Jide Alabi
Bo tilẹ jẹ pe ariwo ti Aarẹ Donald Trump, olori ilẹ Amẹrika lọwọlọwọ n pa bayii ni pe oun yoo lọ sile-ẹjọ dandan lati ta ko bi wọn ṣe kede pe Joe Biden lo wọle ibo ti wọn di lọjọ kẹta, oṣu yii, ṣugbọn aṣiri ohun to ko ba a gan-an ninu ibo ọhun ti n foju han bayii.
ALAROYE gbọ pe lara ohun to n bi awọn eeyan Amẹrika ninu ni ọwọ yẹpẹrẹ to fi mu arun koronafairọọsi to gbaye kan.
Wọn ni niṣe ni Trump kọkọ sọ pe ko si ohun to n jẹ bẹẹ. Bẹẹ ni ko ka wiwọ ibomu atawọn ohun mi-in ti eeyan le fi daabo bo ara ẹni kun rara.Ọwọ to fi mu kinni naa bi awọn eeyan orilẹ-ede rẹ ninu, bẹẹ ni wọn pada gbẹsan ẹ lara ẹ nigba ti asiko ibo to, nitori ọpọ ẹmi lo ṣofo danu, arun koronafairọọsi yii naa lo si pa wọn.
A gbọ pe nibi ti ko gba ọrọ koronafairọọsi yii gbọ de, niṣe lo n fi Joe Biden, alatako ẹ ṣe yẹyẹ lọjọ ti wọn pade ti iyẹn lo ibomu, ko si ju ọjọ kẹta ti arun buruku naa fi kọ lu oun paapaa.
Ohun mi-in ti wọn tun sọ nipa ẹ ni bo ṣe koriira eeyan dudu pupọ. Apẹẹrẹ eyi ni ti iku ọmọkunrin kan, George Floyd, ọmọ Afrika ati America ti ọlọpaa alawọ funfun kan ṣeku pa. Wọn ní kó rí iṣẹlẹ ohun bii ohun ti ko yẹ, ati pe niṣe lo tun n halẹ mọ awọn to ṣewọde ta ko bi wọn ṣe pa ọkunrin naa.
Ti wọn ba n sọ nipa Aarẹ orilẹ ede ti ẹnu maa n fojoojumọ kun, to jẹ pe oni ẹjọ, ọla aroye ni, Aarẹ Donald Trump yii ko l’ẹgbẹ.
Bẹẹ ni inu awọn eeyan ti wọn jẹ ọjọgbọn nilẹ Amẹrika ko dun si awọn ọrọ kobakungbe to máa n sọ lori ikanni abẹyẹfo rẹ.
Wọn ni ilana iṣelu ẹ gan-an ko dun mọ ọpọ ninu, iyẹn gan-an lo mu ọpọ eeyan Amẹrika dẹyẹ si i.
Yatọ si eyi, pupọ ninu awọn eeyan nla nla l’Amẹrika ni Trump n ba ja, o si pẹlu ohun to ba nnkan jẹ fun un.
Bakan naa laarin oun atawọn oniroyin paapaa ko gun.
Orilẹ ede China naa si wa ninu ilu ti ko ba a ṣe rara.
Ajọ agbaye (WHO), naa ko ṣai fara gba lara awọn ti Donald Trump mu ni ọta, ẹsun to si fi kan wọn ni pe wọn n gbe lẹyin China lori ọrọ koronafairọọsi.