Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọbaladi ti Afọn, nijọba ibilẹ Imẹkọ-Afọn, nipinlẹ Ogun, Ọba Busari Adetọna, naa ti waja.
Ọjọ keji ti Olu Imaṣayi, Ọba Gbadebọ Oluṣọla Oni, waja ni Ọbaladi Afọn naa tun papoda yii, tẹle-n-tẹle niku ọhun tun jẹ.
Ọkan ninu awọn ọmọ Ọbaladi, Ọmọọba Adewale Adetọna, lo kede ipapoda baba rẹ soju ikanni ẹ lori Fesibuuku, nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe Ọba Busari Adetọna, Ọbaladi Afọn, ti jade laye lẹni ọdun mejilelọgọta(62). O ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ni iku pa oju Kabiyesi de.
Ọbaladi Afọn to tun ṣipopada yii ni ọba kẹrin to waja ninu ọsẹ yii nikan nipinlẹ Ogun.