Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ẹnjinnia Gabriel Taiwo Ogunniran ni adajọ ile-ẹjọ giga ijọba apapọ tilu Oṣogbo ti sọ pe ki awọn ọlọpaa lọọ fi sọgba ẹwọn ilu Ileefẹ lori ẹsun pe o lu Alọwa Ọwariṣa tilu Ilọwa-Ijẹṣa, Ọba Adebukọla Alli ni jibiti owo.
Agbẹjọro to n ṣoju ijọba ninu ẹjọ naa, Muyiwa Ogunlẹyẹ, ṣalaye pe lọdun 2016 ni Ogunniran gba miliọnu lọna ogun naira (#2m) lọwọ ọba naa pẹlu ileri pe oun yoo ta ile kan to wa ni Block 19, Plot 3, GRA, loju ọna Ilobu, niluu Oṣogbo fun un.
Ogunlẹyẹ ṣalaye pe miliọnu lọna marundinlogoji naira (#35m) ni Ogunniran sọ pe oun fẹẹ ta ile naa fun Alọwa, o si gba miliọnu lọna ogun naira gẹgẹ bii owo asansilẹ.
Nigba to tun di ọdun 2019, o tun gba miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna aadọrun-un naira (#1.3m), ṣugbọn to tun lọọ ta ile naa fun ẹlomi-in.
Ẹsun meji ni wọn ka si Ogunniran lọrun, wọn si sọ pe o nijiya labẹ ipin kin-in-ni, abala kin-in-ni, ofin to lodi si jibiti lilu ti wọn ṣagbekalẹ lọdun 2006.
Lẹyin ti Ogunniran sọ pe oun ko jẹbi ẹsun mejeeji ni agbẹjọro rẹ, D. E. Ẹniọlapọ, rọ ile-ẹjọ lati fun oun laaye lọọ yẹ iwe ipẹjọ wo, nitori ninu kootu ni wọn ti fun oun ati onibaara rẹ.
Onidaajọ Peter Lifu paṣẹ pe ki wọn lọọ fi olujẹjọ pamọ sọgba ẹwọn ilu Ileefẹ titi ọjọ kin-in-ni, oṣu kejila, ọdun yii, ṣugbọn anfaani wa fun agbẹjọro rẹ lati mu iwe wa fun beeli rẹ.