Aderohunmu Kazeem
Bo o lọ o yago lọrọ da ni kutukutu ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọsẹ yii, nigba ti wahala buruku bẹ silẹ laarin awọn ẹṣọ agbofinro atawọn ọlọkada lagbegbe Second Rainbow, lojuna Apapa-Oshodi, l’Ekoo.
Ohun ti wọn lo fa a ni bi awọn ọlọkada yii ṣe yari mọ awọn ẹṣọ agbofinro lọwọ, nigba ti awọn yẹn kọ lu wọn nibi ti wọn ti n gbero lawọn ibi ti ko yẹ lojupopo.
ALAROYE gbọ pe bi awọn ẹṣọ agbofinro ti wọn n ko awọn ọlọkada kiri ṣe ya bo awọn ọlọkada ọhun lo da wahala silẹ. Wọn ni bi wọn ṣe de agbegbe naa ti wọn fẹẹ maa ko ọkada wọn sinu ọkọ ti wọn gbe wa ni wahala bẹ silẹ, ti ija si di ranto.
Bi wọn ṣe n dana sun taya, bẹẹ lọpọ mọto atawọn ero irinna paapaa ko le gba agbegbe ọhun kọja nigba ti wahala ọhun fẹju gan-an.
Bi iṣẹlẹ yii ṣe n lọ lọwọ ni ọga ọlọpaa, Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi, ti gba ori redio kan lọ l’Ekoo, nibi to ti sọ pe awọn ti pana wahala ọhun.
Ninu ọrọ ẹ lo ti sọ pe oun atawọn ikọ oun lawọn jọ lọọ ko awọn ọlọkada ti wọn n ṣiṣẹ loju popo, eyi to lodi si ofin irinna nipinlẹ Eko. O ni nibi tawọn ti fẹẹ ko ọkada wọn lawọn eeyan ọhun ti sọ ọ di wahala mọ awọn lọwọ, tọrọ ọhun si di ranto.
Ẹgbẹyẹmi ti sọ pe ki awọn eeyan Eko fọkan balẹ, ko si wahala kankan, nitori pe alaafia ti pada sagbegbe ọhun bayii.
Afewala mo ki awon olopa sejeje