Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ko ti i sinmi lorí iwadii wọn lati mọ awọn to yinbọn pa Onimọ-ẹrọ Mufutau Ọlayẹmi, ọkan lara awọn tiṣa nileewe gbogboniṣe D.S Adegbenro to wa n’Itori, nipinlẹ Ogun, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtaadinlogun, oṣu kọkanla, ọdun yii.
Ibi ipade kan ni Ọlayẹmi ti n bọ ti awọn kan fi dọdẹ rẹ de Itori, ti wọn si da ibọn bo o ninu mọto ayọkẹlẹ rẹ to n wa bọ.
Bi wọn ṣe rọjo ibọn fun un naa lo sọ’ri nu sinu ọkọ nibẹ, ọkunrin olori ẹka ẹkọ nipa iṣẹ mọnamọna nileewe Adegbenro naa gba ọrun lọ.
Awọn to pa a ko mu nnkan kan ninu mọto rẹ, bẹẹ ni wọn ko gbe mọto naa lọ.
Latigba ti Ọlayẹmi ti ku yii ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti bẹrẹ itọpinpin lati mọ awọn to yinbọn pa a. Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ pe awọn ti da awọn ọlọpaa lati ẹka to n ri si ipaniyan si agbegbe tiṣẹlẹ yii ti waye.