Ohun ti awọn eeyan kan n sọ, ti wọn si n beere lọwọ mi bayii, ni pe ki la ti ṣe fẹẹ yanju ọrọ to wa nilẹ yii. Ki lọna abayọ? Awọn kan n beere ọrọ yii lọna to daa, wọn n beere nitori loootọ ni wọn fẹ ka rọna abayọ, ka le bọ ninu gbogbo iṣoro yii. Awọn yii ja fun Yoruba, wọn ja fun Naijiria, wọn pariwo titi ka too dibo fun Buhari lẹẹkeji; ṣugbọn a binu, a sọ wọn lorukọ ti i ki ṣe tiwọn. Sibẹ, nigba tọrọ tun ri bo ti ri yii, ọna abayọ ni wọn n wa. Ṣugbọn awọn kan wa ti wọn jẹ ọjẹlu, awọn alaigbọran, ati awọn ti wọn ti fi oṣelu ba laakaye wọn jẹ, boya aigbọn ati iwa omugọ si ni, to jẹ awọn gan-an ni wọn sun wa debi ti a wa yii, awọn naa n beere ọna abayọ. Ki i ṣe pe wọn fẹẹ yi iwa wọn pada o, tabi ọna abayọ yii, wọn fẹẹ lo o fun ọjọ pipẹ, tori ki wọn le bọ ninu rogbodiyan to wa nilẹ yii ni, bi wọn ba si ti bọ ninu ẹ, ki wọn tun pada si ọna ti wọn tọ nijọsi ti ko daa, ọna to gbe wọn debi ti wọn wa yii!
Gbogbo ẹni to ba fẹran Naijiria, gbogbo ẹni to ba fẹran Yoruba, atawọn to ba n wa ọna abayọ loootọ fun ilẹ wa, akọkọ ni ki wọn gba pe ijọba to wa lode yii ko daa! Ijọba buruku ni! Ironu akọkọ niyi, ka kọkọ gba eleyii lọkan wa. Ọrẹ mi kan ja omi loju nigba to n sọrọ kan fun mi lọsẹ to lọ yii. Agbalagba! Orẹ wa kan lo lọ siluu oyinbo lọdun diẹ sẹyin, lo ba ko owo dọla de latọdo awọn ọmọ ẹ. O waa bọ sasiko ti ọrẹ mi yii naa fẹẹ rin irinajo, lo ba ni ki orẹ wa kẹta yii ko owo dọla ti wọn fun un lati ọhun foun, pe nigba to ba nilo ẹ, oun aa fi owo dọla mi-in rọpo fun un. Ẹgbẹrun marun-un ni, lasiko ti wọn n ṣẹ dọla ni Naira to le diẹ ni ọgọrun-un meji. Ni bayii, ara ọrẹ wa kẹta o ya, o fẹẹ lo dọla ẹ! Ọrẹ mi debi to ti fẹẹ ṣẹ dọla, o ti le ni ilọpo meji, bii miliọnu meji ataabọ lo maa fi gbara bayii lori owo to kan le diẹ ni miliọnu kan.
Ijọba yii ko daa! Ki i ṣe nitori mo koriira awọn ti wọn ṣe e, tabi pe n ko fẹran Buahri ni mo ṣe n sọ bẹẹ, ṣugbọn ijọba yii o daa loootọ ni. Bawo nijọba kan ṣe le ṣe ileri oriṣiiriṣii fawọn araalu ti ko si ni i mu ẹyọ kan ori ẹ ṣẹ. Ti owo dọla ni mo sọ yii. Lọjo kin-in-ni ti epo bẹtiroolu di Naira mẹtadinlọgọrun-un (N97) laye Jonathan, gbogbo wa la gbẹnu soke ti a binu, ibinu naa si pọ fun wa. Igba naa lawọn Buhari bẹrẹ ileri pe awọn aa sọ bẹntiroolu di owo pọọku. Ṣugbọn bi a ti n wi yii, gbogbo yin naa lẹ mọ iye ti wọn ni ka maa ra epo mọto bayii. Ijẹrin yii ni wọn ṣẹṣẹ fowo kun un. Owo ina ti mẹkunnu n lo, ounjẹ gbogbo, ilera wa, eto aabo wa (aye Buhari yii lawọn Fulani bẹrẹ iṣẹ ijinigbe, wọn si n ṣe kinni naa lọ, wọn ko ti i dakẹ). Lati ọjọ ti ijọba yii ti waa de, kin ni wọn ṣe yọri gan-an! Ki lẹnikẹni le tọka si!
Ijọba yii ko daa ni! Ariwo ti ọpọ awọn ti ko mọkan n pa ni pe Buhari fẹẹ waa gbogun tiwa ibajẹ ni; o fẹẹ waa mu awọn ti wọn n kowo jẹ ni; o fẹẹ waa fopin si riba ni Naijiria ni. Ni ọdun 2023, nigba ti ijọba yii ba kogba wọle, ọmọ Naijiria yoo lanu silẹ, wọn ko ni i le pa a de, nigba ti wọn ba n gbọ iye owo tawọn kan ko jẹ laye Buhari yii, ti wọn si n ko o jẹ lojoojumọ bi a ti n sọ yii, ti wọn ko ṣiwọ nibẹ, to jẹ niṣe ni kinni naa n le si i. Ẹni ba gbọ iye ti wọn ni awọn fi ra ounjẹ fun awọn araalu lasiko korona, to ba gbọ iye ti awọn minisita fi n rin irina-ajo lasiko ti wọn ni ki kaluku gbele ẹ, ti ko si orilẹ-ede to ṣilẹkun ẹ fẹnikan, to ba gbọ iye ti wọn fi n ṣe ọna reluwee, atawọn ọna marosẹ wa, tọhun yo mọ pe kekere lowo ti wọn ji laye Joathan ti a n pariwo, awọn aṣiri to maa jade sita laye ti Buhari yii, Ọlọrun jẹ ki ẹmi Naijiria gbe e ni.
Ijọba yii ko daa! Ki lo de ti mo fi n pariwo bẹẹ. Ko sohun to fa a ti mo fi n pariwo yii ju pe ko daa loootọ ni. Ohun gbogbo lo dorikodo, nnkan ko buru to bayii fun Naijiria yii ri. Eyi to buru ju ninu gbogbo ẹ ni ti ija ẹlẹyamẹya to ti wọ aarin wa bayii, ikoriira ti a ni fun ara wa, ti Yoruba koriira Fulani ati Hausa, ti awọn Ibo naa koriira wọn, ti awọn Hausa paapaa koriira Yoruba ati Ibo, to jẹ ko si ajọṣe gidi laarin wa. Lori ọgẹgẹrẹ la wa, lọjọkọjọ ni ikoriira to wa laarin wa yii le di ogun. Ijọba Buhari yii lo fa a, tabi ki n ni Buhari gan-an lo fa a fun wa, nnkan wa o ri bayii tẹlẹ. Ṣebi Hausa n bẹ, Yoruba wa, Ibo naa n bẹ, bi a ti jọ n gbe lati ọjọ pipẹ wa ree, ti ko si ẹni kan to koriira ẹni kan. Buhari lo la awọn Fulani loju sodi, ti wọn waa ri ara wọn bii ẹni to ni Naijiria, ti wọn si ṣetan lati fi ẹmi ara wọn di i ki wọn le sọ Naijiria di tiwọn pata.
Ijọba yii ko daa! Buhari ti da gbogbo eyi silẹ tan ki aiyaara too ba a. O ti fi awọn iran rẹ sipo titi, o ti gbe awọn Fulani ati Hausa gori awọn ẹya to ku, o si fa ọrọ aje ilẹ yii le ọwọ awọn alaimọkan ti ko yẹ ko de rara. Nigba to n ṣe gbogbo eleyii, ara rẹ ya daadaa, ṣugbọn nigba ti atubọtan awọn iwa to hu yii de, to di wahala, to si yẹ ko fopin si wọn, ko si nipo lati le ṣe bẹẹ mọ, nitori aiyaara rẹ ti le kọja ohun to le da si nnkan kan, tabi to le paṣẹ to maa mulẹ laarin awọn to ko jọ. Bi ara ọkunrin yii ba ya, o ṣee ṣe ko ti mu ayipada ba awọn nnkan to ti ṣe tẹlẹ, ṣe oun naa kuku ti ri i pe kini naa ko daa, iparun ati ogun lawọn iwa naa fẹẹ da si Naijiria. Ṣugbọn ko lagbara lati ṣe bẹẹ mọ, awọn to ti fi sipo ko si ṣetan lati gbe ipo silẹ, kaka bẹẹ, wọn tubọ n gbilẹ si i ni, wọn n fi ara wọn si ipo nla nla kaakiri. Bi wọn ba si ṣe kinni kan, wọn aa ni Buhari lo ni ki awọn ṣe e. Bi ẹ ba si fẹẹ beere bi ọro ti jẹ lọwọ Buhari funra ẹ, ẹ ko ni i ri i!
Ijoba yii o daa! Ẹ wo ohun to ṣẹlẹ nijọsi l’Ekoo yii, nigba tawọn ọmọ wa n ṣe iwọde SARS. Alaye to jade lati ọdọ awọn ologun bayii fihan pe ki nnkan too yiwọ, Babajide to jẹ gomina Eko gbiyanju titi lati ri Buhari ba sọrọ. Awọn ṣọja funra wọn lo sọ bẹẹ. Ohun ti wọn si ṣe n ṣalaye bẹẹ ni pe ko si ninu ofin Naijiria ko jẹ gomina kan lo maa paṣẹ fawọn ṣọja ki wọn jade lọ sibikibi. Ẹni kan ṣoṣo naa lo le paṣẹ, iyẹn naa si ni olori ijọba Naijiria funra ẹ, iyẹn Buhari. Koda, olori awọn ṣọja funra ẹ ko gbọdọ paṣẹ, ibi yoowu ti wọn ba fẹẹ lọ, to ba ti di pe wọn n ko ọmọ ogun lọ, wọn le yinbọn ẹyọ kan nibẹ, Aarẹ nikan lo ni aṣẹ bẹẹ lati pa. Ṣugbọn Babajide wa Buhari, ko ri i, n lo ba bẹrẹ si i pe awọn mi-in. Awọn mi-in to n pe kiri lo pada da wahala buruku to ṣẹlẹ ni Lẹkki yẹn silẹ, bi kinni naa ba si maa buru ju bẹẹ lọ, bi yoo ti ṣẹlẹ naa niyẹn.
Ijọba yii ko daa! O yẹ ki ẹyin naa le fi ọkan ronu lori ọrọ Eko yii, nigba ti ilu ba n daru bẹẹ, ti wọn wa odidi Aarẹ to jẹ olori ilu, ti wọn ko ri i ba sọrọ. Ni gbogbo Naijiria, Eko lo lokiki ju lọ loju aye, Eko ni gbogbo agbaye mọ, nitori nibẹ ni ile ọrọ-aje wa. Ki nnkan iru iyẹn waa maa ṣẹlẹ, ki gomina fi wakati mẹrinlelogun wa Aarẹ lati ba sọrọ ko ma ri i. Ṣe oju aye ni Buhari wa nigba naa ni abi oju oorun! Ṣe Naijiria yii naa lo wa ṣaa! Awọn ti wọn ki i ṣe ara Naijiria n sọrọ, wọn n ri gbogbo ohun to n lọ, ṣugbọn Aarẹ tiwa ko ri i, ko si gbọ nnkan kan to n lọ. Ko le ri i, ko si le gbọ, nitori ko gbadun! ko mọ ọpọ ohun to n lọ ni ayika ẹ rara. Kaluku awọn ti wọn yi i ka kan n paṣẹ tiwọn ni, ṣugbọn wọn ti ko awọn kan sibẹ ti wọn aa maa purọ tan gbogbo aaye jẹ, ti wọn aa maa sọrọ funra wọn, ti wọn aa si sọ pe Buhari lo sọ ọ, ni ẹni ti ẹlomi-in ninu wọn ki i ri laarin oṣu kan.
Ijọba yii ko daa. Ko daa loootọ. Ohun ti gbogbo wa kọkọ gbọdọ gba ree, lẹyin naa ni a o ṣẹṣẹ waa jọ wa ọna abayọ! Ṣugbọn bi ẹni kan ba jade, to n tan yin, to ko ṣuga sẹnu, to n sọrọ wọyọwọyọ, to ni ko si iru Buhari ni gbogbo agbaye. Ẹ woju ẹ, kẹ ẹ sọ fun un pe were ni! Nitori loootọ loootọ ni mo wi fun yin, ijọba yii o daa!