Jide Alabi
Pẹlu igbesẹ ti ijọba apapọ fẹẹ gbe lati fopin si ohun ti awọn eeyan yoo maa pin kiri lori ẹrọ ayelujara, o ṣee ṣe ki ariwo mi-in tun ṣelẹ, ti awọn ọmọ Naijiria ba ri i gẹgẹ bii ọna lati pa wọn lẹnu mọ ni.
Minisita fun eto iroyin, Alhaji Lai Muhammed, sọ pe ko sigba ti ijọba ko ni i fi gbedeke si bi awọn eeyan ṣe n lo ẹrọ ayelujara nilokulo, paapaa lori bo ṣe le da wahala silẹ laarin ilu.
O ni igbesẹ ọhun ti ṣe pataki bayii, nitori ọpọlọpọ wahala to ṣẹlẹ lasiko iwọde ta ko SARS, iroyin ẹlẹjẹ ti wọn n pin kiri lo fa a.
Ọdun 2018 ni minisita yii sọ pe oun ti kọkọ keboosi pe o ṣe pataki ki ofin ati ijanu wa lori bi awọn eeyan yoo ṣe maa lo ẹrọ ayelujara.
Minisita naa ni bayii, ko si ṣiṣe, ko si aiṣe, o ti di dandan fun ijọba lati wa ojuutu si bi ijanu ṣe maa wa, ki awọn alayederu iroyin ma lọọ fi igbekugbee wọn da Naijiria ru.
O ni aimọye iroyin ti ko jẹ ootọ lawọn kan n pin kiri, paapaa lasiko igba ti ọrọ iwọde ta ko SARS gbọna mi-in yọ, tawọn kan ti n tufọ awọn oṣere kan pẹlu fọto wọn, ṣugbọn ti ọrọ ko pada ri bẹẹ rara.
Muhammed ni, ‘‘A o ṣiṣẹ lori ẹ, bẹẹ ni ko ni i jẹ lorilẹ-ede yii nikan. A o ri i daju pe ko ni i saaye lilo ẹrọ ayelujara bi eeyan ba ṣe fẹ lai bikita wahala to le ṣẹlẹ.
K’ijoba fi gbedeke si kiakia lodara ju!
Baba lai Muhammad opolo yin otilo,ohun temaje koje ke gbon mo ewadi eru Fulani Omo Eran otita funyi,
Were tutu