Faith Adebọla, Eko
Ahamọ ọgba ẹwọn Kirikiri, l’Ekoo, ni ile-ẹjọ Majisreeti to wa ni Surulere paṣẹ pe ki wọn sọ afurasi ọdaran to pera ẹ ni oluṣọ-aguntan ijọ Ọlọrun, Pasitọ Ifeanyi Ndieze, si, latari ẹsun pe ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogoji naa pe o fipa ṣe ọmọ ọdun mẹta kan baṣubaṣu ninu ṣọọṣi rẹ.
Ọsan Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni igbẹjọ bẹrẹ ni kootu naa lori ẹsun ti won fi kan Pasitọ Ifeanyi, ti wọn lo n gbe ni Opopona Karimu, lagbegbe Surulere, nipinlẹ Eko.
Agbefọba, Sajẹnti Courage Ekhueorohan, sọ pe ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii lo huwa buuku naa.
Wọn ni iwadii tawọn ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa ṣe lori iṣẹlẹ naa fihan pe loootọ ni Pasitọ Ifeanyi bọ pata nidii ọmọ ọdun mẹta kan ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ naa, wọn lo bẹrẹ si i fi ika ro ọmọ naa labẹ ni ṣọọṣi r5ẹ to wa ni Ojule kejidinlogun, Opopona Salau, lagbegbe Surulere.
Ẹnikan ti wọn forukọ bo laṣiiri lo ka afurasi ọdaran naa mọ ibi to ti n huwa palapala ọhun, lo ba pariwo le e lori, ṣugbọn wọn lọkunrin naa loun n ba ọmọbinrin yii ṣere lasan ni, lọrọ ba di tọlọpaa.
Wọn ni ayẹwo ti wọn ṣe fọmọbinrin naa lọsibitu fihan pe erekere ti pasitọ yii ba a ṣe ti dọgbẹ si i loju ara.
Adajọ M. I. Dan-Oni to gbọ ẹsun ọhun ni oun ko ti i fẹẹ gbọ alaye olujẹjọ titi ti ajọ to n gba adajọ nimọran yoo fi fesi si ibeere wọn lori ọrọ ọhun.
O ni ki pasitọ naa maa gbatẹgun lọgba ẹwọn titi di ọjọ keji, oṣu to n bọ, ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.