Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Nitori bo ṣe jẹ pe ẹnu ọna abawọle si ọpọlọpọ ipinlẹ ni Naijiria ni ipinlẹ Ogun, ti ọpọlọpọ okoowo si n ti ibẹ waye lojoojumọ, Gomina ipinlẹ yii, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti rawọ ẹbẹ sijọba apapọ lati jọwọ, ṣe iranwọ to yẹ fawọn ọna ipinlẹ yii ti wọn nilo atunṣe gidi latọdọ ijọba.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kọkanla yii, ni gomina ṣipẹ ọhun nibi ipade awọn alẹnulọrọ to waye l’Ogere, loju ọna marosẹ-Eko s’Ibadan. Minisita fun ọrọ iṣẹ ode, Ọgbẹni Babatunde Raji Fashọla, wa nibẹ lọjọ naa, oun si ni gomina fiṣẹ ran sijọba apapọ lati ṣatunṣe sawọn ọna pataki bii marosẹ yii, eyi to kan ipinlẹ Ogun gbọngbọn.
Nigba to n fesi, Fashọla paṣẹ pe kawọn onitanka ati tirela loju ọna yii ko wọn kuro ni titi, nitori epo bẹntiroolu ti wọn n da si titi naa n ba oju ọna jẹ ni.
O waa rọ awọn FRSC pe ki wọn ṣiṣẹ wọn daadaa pẹlu lilo ofin fawọn to n ba oju ọna jẹ, nitori ijọba ko ni i gba kawọn eeyan ti wọn n pawo sapo ara wọn maa ba nnkan ijọba jẹ.
O ni ijọba apapọ yoo ran ipinlẹ Ogun lọwọ lori awọn ọna rẹ, paapaa lawọn ibi tiṣẹ ti n lọ lọwọ.