Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ
Awọn Fulani darandaran kan la gbọ pe wọn ya bo oko Oloye Olu Falae lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii, nibi ti wọn ti ba ọpọlọpọ ire oko jẹ, ti wọn si tun ji awọn nnkan mi-in ko sa lọ.
Nigba to n fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ funra rẹ, Oloye Ondo ọhun ni lati bii ọsẹ diẹ sẹyin lawọn darandaran naa ti n soro bii agbọn ninu oko oun.
O ni awọn ọlọpaa lo ba oun le awọn Fulani ọhun kuro ninu oko lọjọ ti wọn kọkọ wa, lẹyin naa loun tun lọọ fẹjọ wọn sun alaga ẹgbẹ Miyẹti Allah nipinlẹ Ondo, boya o le ba wọn sọrọ ki wọn si gbọ si i lẹnu.
Tijatija lo ni wọn tun pada wa lẹyin tawọn ọlọpaa waa le wọn, o ni ṣe ni wọn mọ-ọn-mọ fi ẹran ọṣin wọn ba gbogbo oko naa jẹ patapata, ti wọn si tun ji owo ati ẹru awọn oṣiṣẹ ibẹ ko sa lọ.
Oloye Falae ni oun ti kọ lẹta ẹbẹ si alakooso ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, fun iranlọwọ.
Baba yii ni ki wọn jọwọ, tete waa gba oun lọwọ awọn akọlu igba gbogbo tawọn Fulani n ṣe si oun atawọn to n ba oun ṣiṣẹ oko.