Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Awọn agbebọn kan ti wọn fura si gẹgẹ bii ajinigbe ti yinbọn pa Rẹfurẹndi Johnson Ọladimeji to jẹ alufaa ijọ Solution Baptist Church, to wa niluu Ikẹrẹ-Ekiti.
Ọjọbọ, Tọsidee, niṣẹlẹ ọhun waye loju ọna Igbara-Odo si Ikẹrẹ-Ekiti, lasiko ti oluṣọ-aguntan ọhun n bọ lati ipinlẹ Ọṣun, ṣugbọn ọjọ keji ti i ṣe Furaidee, lawọn mọlẹbi ẹ too mọ.
Gẹgẹ bi ẹnikan to mọ nipa iṣẹlẹ naa ṣe sọ fun ALAROYE, ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ lawọn agbebọn yii da emi oloogbe legbodo, nigba tawọn mọlẹbi ẹ ko si ri i ni wọn bẹrẹ si i waa kaakiri, ki wọn too ba a ninu mọto ẹ ti wọn yinbọn pa a si loju titi.
Lẹyin eyi ni wọn lọọ sọrọ naa fawọn ọlọpaa Igbara-Odo, wọn si gbe oku rẹfurẹndi yii lọ si mọṣuari.
Ninu alaye to ṣe, adari ijọ Baptist nipinlẹ Ekiti, Rẹfurẹndi Adeyinka Aribasoye, fidi ẹ mulẹ pe oloogbe naa lọọ ki iya ẹ niluu Ipetu Ijẹṣa, nipinlẹ Ọṣun ni, nigba to si n bọ niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si i.
O ni, ‘Iṣẹlẹ yii jọ ijinigbe to ja si iku. O ṣee ṣe ko jẹ nigba ti wọn da a duro ti ko fẹẹ duro ni wọn yinbọn pa a.
‘Awọn mọlẹbi ẹ bẹrẹ si i wa a nigba ti wọn ko gburoo ẹ, eyi lo jẹ ki wọn maa pe gbogbo awọn to mọ nipa irin-ajo ẹ, ki wọn too pada ri i nibi ti wọn pa a si.’
Lasiko ta a pari akojọpọ iroyin yii, ASP Sunday Abutu to jẹ Alukoro ọlọpaa Ekiti sọ pe oun ko ti i gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn o daju pe awọn yoo wa awọn oniṣẹ laabi ọhun ri tawọn ba gbọ nipa ẹ.