Latọdun to n bọ lọ, gbogbo ẹni to ba fẹẹ gba nọmba ati lansẹnsi gbọdọ ni kaadi idanimọ ilẹ wa –FRSC

Ọga agba ajọ ẹṣọ oju popo nilẹ wa, (FRSC), Ọgbẹni Boboye Oyeyẹmi, ti kede pe bẹrẹ lati oṣu kin-in-in, ọdun to n bọ, ẹnikẹni to ba fẹẹ gba lansẹnsi (license) iwakọ tabi to fẹẹ gba nọmba tuntun fun ọkọ rẹ gbọdọ ti ni kaadi idanimọ to fi i han pe ọmọ Naijiria ni, aijẹ bẹẹ, onitọhun ko ni i ri ohun to fẹ gba.

Ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii lo sọrọ yii lasiko ifọrọwerọ to ṣe pẹlu Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa, NAN. Ọkunrin naa sọ pe ibaa jẹ iwe aṣẹ iwakọ leeyan fẹẹ gba, ibaa si jẹ nọmba (plate number), tabi nnkan mi-in, o ti di dandan lati kọkọ ri kaadi idanimọ orileede ẹni naa, iyẹn National Identity Number.

O ni idi pataki ti ajọ naa fi ṣe ofin tuntun yii ni pe kaadi idanimọ yii maa jẹ ki awọn le tọpasẹ ẹni ti wọn fun ni lansẹnsi ati nọmba ọkọ, ko si ni i jẹ kawọn eeyan le maa lo oriṣiiriṣii orukọ lati gba ọpọ lansẹnsi ati nọmba ọkọ, gẹgẹ bawọn kan ti ṣe sẹyin.

O ni aye ti di aye imọ ẹrọ, imọ ẹrọ si ti jẹ ko ṣee ṣe lati ṣakọsilẹ, ki awọn si tọju ẹkunrẹrẹ ohunkohun nipa awọn eeyan. Aisi iru akojọpọ bẹẹ latẹyinwa lo ni o fa a ti awọn mi-in fi n ṣe ohun to lodi sofin.

O fikun un pe bawọn orileede bii Ṣaina, India ati Amẹrika, ti wọn ti goke agba lagbaaye, ti wọn si lero to pọ ṣe n ṣe niyẹn, eyi si mu ko ṣee ṣe fun wọn lati fi imọ ẹrọ gbogun ti iwa ọdaran.

Boboye tun ni ẹgbẹrun mẹfa ati ọgọrun mẹta ati aadọta naira (N6,350), tawọn n gba lati fun ẹnikan ni lansẹnsi iwakọ ko ti i yipada, o ni tẹnikẹni ba beere ju bẹẹ lọ, jibiti lonitọhun fẹẹ lu.

 

One thought on “Latọdun to n bọ lọ, gbogbo ẹni to ba fẹẹ gba nọmba ati lansẹnsi gbọdọ ni kaadi idanimọ ilẹ wa –FRSC

  1. Lisensi iwako kii se #6,350 bi oga yi sewi. Fun eniti tie bati expired nkan bi #12,000 si #15,000 ni won ngba. Naijiria ti di nkan miran bayi o. Afi ki oluwa kowa yo

Leave a Reply