Ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pe o tun lọwọ ninu iwọde SARS mi-in ko ni i faraa re lọ l’Ondo-Kọmisanna

 Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.

Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bọlaji Salami, ti ni awọn ko ni i faaye gba iwọde SARS ẹlẹẹkeji nibikibi nipinlẹ naa.

Ọga ọlọpaa ọhun ni awọn oṣiṣẹ oun ti gbaradi, bẹẹ ni wọn ti ṣetan, lati doju ija kọ awọn to ba gbiyanju ati ko ara wọn jọ fun iwọde mi-in nitori pe awọn ko ni i laju silẹ ki awọn janduku kan tun maa da ilu ru gẹgẹ bi eyi ti wọn ṣe kọja.

O ni ki lawọn eeyan ọhun tun n fẹ lẹyin tijọba ti fagi le ọlọpaa SARS ni kete ti iwọde akọkọ ti bẹrẹ, o ni ọpọ awọn oṣiṣẹ to wa lẹka ọhun ni wọn ti gba iṣipo pada nigba tawọn mi-in ninu wọn ṣi wa nibi ti wọn ti n gba itọju.

O ni loootọ lawọn araalu lẹtọọ lati fẹhonu han, ṣugbọn ẹni to ba fẹẹ ṣe bẹẹ gbọdọ kọkọ waa gba aṣẹ lati ọdọ awọn ọlọpaa, ki awọn le mọ bi awọn ṣe maa mojuto wọn ti ko fi ni i yọri si rogbodiyan ati idaluru.

Salami ni ki i ṣe asiko yii ti oun ṣẹṣẹ n gbiyanju ati rọ awọn osiṣẹ abẹ oun ki wọn pada sẹnu iṣẹ lẹyin iriri kikoro ti wọn la kọja lasiko iwọde SARS akọkọ lo yẹ kawọn eeyan kan tun ko ara wọn jọ lati pilẹ wahala mi-in.

Kọmiṣanna ni ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pe o tun lọwọ ninu iwọde ti wọn n gbero rẹ yii ko ni i fi ara rere lọ, o ni awọn ko ni i gba ki awọn janduku kan maa da ilu ru lasiko to yẹ kawọn eeyan maa yọ ayọ ipari ọdun.

 

Leave a Reply