Latigba ti gbajumọ oniṣowo fiimu Yoruba, to tun n ta mọto bayii, Mayegun Oyegoke Ọlaoye, ti bọ sori ikanni ayelujara ẹ, Instagiraamu, to si la ọrọ to ti da bii aṣiri mọlẹ laarin oun ati gbajumọ olorin ẹmi nni, Tọpẹ Alabi, pe oun lobinrin naa bi akọbi ẹ, Ayọmikun, fun ni ni ọrọ yii ti da awuyewuye nla silẹ. Bi ọmọ ti wọn n ja si yii ṣe bọ sita lati sọrọ, ni awọn eeyan ti n gba ọrọ naa bii ẹni gba igba ọti.
Eyi lo fa a ti akọroyin wa fi pinnu lati wa ọkunrin yii kan ko le sọ ti ẹnu rẹ lori iṣẹlẹ naa. Ọkunrin naa ti ba akọroyin wa, KAZEEM ADEROUNMU sọrọ, alaye to ṣe ree:
ALAROYE: Ẹ ku aṣalẹ o, lati ileeṣẹ ALAROYE ni o…
Ọlaoye: Ẹ kaalẹ o…
ALAROYE: Ọrọ nipa awuyewuye to n lọ nipa ọmọ ti Tọpẹ Alabi bi fun yin ni a ṣe pe yin lati le tan imọlẹ sawọn nnkan kan to jẹ yọ ni o…
Ọlaoye: Kin ni ẹ fẹ ki n sọ nipa ẹ?
ALAROYE: Ni kete ti iroyin ọhun ti gbalu, oriṣiriiṣi ọrọ lawọn eeyan ti sọ nipa yin, koda awọn mi-in sọ pe ẹ sa fun ojuṣe yin lori ọmọ naa ni, ati pe lasiko tẹ ẹ jade lati sọ nipa ẹ yii, bii ẹni fẹẹ fi ba nnkan jẹ ni?
Ọlaoye: Ohun to ṣẹlẹ ni pe niṣe ni mo mọ-ọn-mọ fẹẹ dakẹ, mi o fẹẹ sọ ohunkohun. Ati pe aburo mi to mọ nipa ọrọ yii daadaa ti jade sita lati sọ bi ohun gbogbo ṣe jẹ, paapaa lori ohun ti ọmọ yẹn kọ sinu iwe iroyin.
Ko ni i bojumu ki emi ati ọmọ yẹn jọ maa ta ohun sira wa. O maa dara ti ẹ ba le pe Tọpẹ, funra ẹ, ko ṣalaye bi ọrọ ti ̀ọmọ ẹ sọ ṣe jẹ gan-an.
Ni temi, mo ti pinnu pe mi o ni i sọ ohunkohun si ọrọ yẹn, aburo mi ti sọrọ, mo si nigbagbọ pe gbogbo bi ọrọ ṣe jẹ gan-an lo ti sọ ọ yẹn.
ALAROYE: Ṣe ohun ti ẹ n sọ bayii ni pe gbogbo ọrọ ti aburo yin sọ yẹn, bẹẹ naa lo ṣe jẹ?
Ọlaoye: Gbogbo ẹ pata lo ti sọ, ko si ohun kan bayii to ṣẹyin ẹ, o ṣoju ẹ daadaa, ko si eyi to ṣokunkun si i.
ALAROYE: Ni bayii ti ọmọ yẹn ti waa sọ pe kootu lawọn yoo ti yanju ẹ, ti ẹ ba ṣi ni in lọkan pe ẹyin lẹ bi oun nkọ bayii?
Ọlaoye: Ko gba kootu lọ, ko lọọ ṣe ohun to ba fẹ ni kootu… iru ẹjọ wo lo fẹẹ pe ni kootu, ki lo mọ gan-an, ṣe oun lo bi ara ẹ ni?
ALAROYE: Njẹ ẹ tiẹ lanfaani lati ba a sọrọ ri, ṣe ẹ maa n pe e abi oun lo maa n pe yin ki ọrọ too di bayii?
Ọlaoye: Ko mọ nnkan to n ṣe ni, bo ṣe wa yẹn, o mọ ootọ daadaa, gbogbo ọrọ yii pata ni aburo mi ti sọ…
ALAROYE: Gẹgẹ bi awa ṣe gbọ, wọn ni ọmọ yii ni akọbi yin, njẹ o yẹ kiru ọmọ bẹẹ maa jẹ orukọ baba mi-in?
Ọlaoye: Wahala oun ati iya ẹ niyẹn, iya ẹ lo mọ idi to fi ṣeru ẹ, ohun lo mọ ohun to wa lọkan ẹ to fi fun un lorukọ baba mi-in. Ti iya ẹ ba dara ẹ loju, ko jade sita lati sọ ọ pe emi kọ lo bi i fun.
Emi ati ọmọ yẹn ko lẹjọ rara, Tọpẹ Alabi gan-an ni ko bọ sita gbangba ko waa jiyan pe emi kọ ni mo lọmọ, diẹ ni tọmọ yẹn nitori oun kọ lo bi ara ẹ….
ALAROYE: Awa tiẹ gbọ pe ẹyin ati Tọpẹ Alabi ti jọ pade pẹlu awọn eeyan ti wọn mọ sọrọ yii lati wa alaafia saarin ẹyin mejeeji…
Ọlaoye: Ohun naa ni mo ti sọ yẹn, gbogbo ẹ pata ni aburo mi ti tan imọlẹ si, ko si ohun ti aburo mi sọ lori ọrọ yii ti ki i ṣe ootọ, nitori gbogbo ẹ pata lo ṣoju ẹ.
ALAROYE: A jẹ pe loootọ ni Sọji Alabi ti maa n waa ka Tọpẹ Alabi mọle yin tẹ ẹ jọ n gbe gẹgẹ bi aburo yin ṣe sọ?
Ọlaoye: Mo ti sọ fun un yin pe gbogbo ohun to ba ti sọ pata, bo ṣe ri gan-an niyẹn, ẹ ma wulẹ tun ṣeyọnu lati gbọ ohunkohun mọ lọdọ temi. Gbogbo ẹ pata lo mọ, to ṣoju ẹ daadaa. Emi kan pinnu lati ma sọrọ ni, gbogbo ohun to ba si sọ, ododo ni.
Tẹ o ba gbagbe, wẹrẹ bayii ni wahala ọhun bẹrẹ, Ọlaoye lo kọkọ sọrọ, bẹẹ ni ọmọ Tọpẹ Alabi, ti wọn n ja si yii naa si jade, to sọ pe oun ko mọ baba meji o, Sọji Alabi ti i ṣe ọkọ iya oun, ti oun ti mọ lati kekere gan-an loun gba ni baba oun.
Ko si pẹ naa ti aburo Ọlaoye naa bọ sita, ọkunrin naa lo kọ awọn ọrọ aṣiri kan si ori ikanni ayelujara rẹ lọsẹ to kọja. O ni ki i ṣe pe oun gbe igbesẹ yii lati ba Tọpẹ lorukọ jẹ, tabi lati ba iṣẹ iranṣẹ rẹ jẹ, o ni oun ṣe bẹẹ lati tan imọlẹ si ọrọ naa, nitori ọpọ awọn ti wọn n sọ ohun ti wọn ko mọ nipa ajọṣepọ to wa laarin ẹgbọn oun ati Tọpẹ.
Bẹẹ lo ni igbesẹ yii di dandan nitori bi awọn kan ṣe n tabuku ẹgbọn oun, ti wọn si n sọ pe nitori pe ọmọ naa ti dagba bayii to fẹẹ gba ọmọ naa lo ṣe pariwo sita. O ni ọrọ ko ri bẹẹ rara.
Ọkunrin yii ni nitori akọroyin ori ẹrọ ayelujara to gbe ọrọ naa jade, to si sọ ọ bii pe ọmọ ale ni ọmọ naa lo jẹ ki oun fẹẹ sọrọ, nitori ọdọ ẹgbọn oun yii loun gbe, ọpọlọpọ ohun to si ṣẹlẹ lo ṣoju oun, ti oun si ni ẹri lọwọ lati gbe e lẹyin paapaa.
Eyi ni alaye ti ọkunrin naa ṣe sori ikanni ayelujara rẹ.
‘‘Emi ni aburo si Baba Ayọmikun, (ọmọ Tọpẹ Alabi), a ko le maa dahun si gbogbo ohun ti awọn eeyan n sọ lori ọrọ yii nitori niṣe lo maa di ariwo, to si maa da bii pe niṣe ni a n wọna lati ba iṣẹ orin ti Tọpẹ Alabi n ṣe jẹ.
‘‘Ṣugbọn imọran to fun Ayọ lati lọ sori ẹrọ agbọrọkaye lati sọrọ lai beere bi akọroyin ori ẹrọ ayelujara to gbe iroyin naa ṣe ri i maa ṣi oju ọgbẹ to ti n san tẹlẹ silẹ fun awọn obi ọmọ yii mejeeji, ti onikaluku ti gbagbe ohun to ti ṣẹlẹ tẹlẹ.
‘‘Ohun to hu ọrọ yii jade ni bi wọn ṣe fẹsun kan Ayọmikun pe ọmọ ale ni, eyi lo mu ki ẹgbọn mi jade pe oun ni baba rẹ, oun ko si le sẹ́ pe oun kọ loun bi i.
‘‘Ti akọroyin ori ẹrọ ayelujaara kan ba waa fẹ ẹ loju lati fi han gbogbo aye, nibo lo ti waa kan bọọda mi, nibo lo ti jẹ ẹjọ rẹ?
‘‘Yara kan naa ni mo n gbe pẹlu ẹgbọn mi yii ni ile ta a gbe ni Oguntolu, ni Onipaanu, lọdun naa lọhun-un. Mo le ṣalaye ti ko ruju nipa bi awọn mejeeji ṣe pade, ati bi Tọpẹ ṣe gbakoso ohun gbogbo, ti wọn si jọ n gbe bii tọkọ-taya.
‘‘Ẹgbọn mi ṣetọju Tọpẹ daadaa ni gbogbo igba to fi wa ninu oyun, titi to fi bimọ. Koda, niṣe ni wọn ṣekomọ ọmọ naa rẹpẹtẹ, nitori wọn pe olorin to waa kọrin nibi ikomọ Ayọmikun, gbogbo awọn to si lorukọ daadaa ti wọn n ta fiimu, ti wọn si n gbe awọn oṣere jade ti wọn wa ni Idumọta nigba naa lo wa nibi ayẹyẹ ikomọ yii. Ẹ lọọ beere daadaa, ko sẹni ti ko mọ itan Ọlaoye ati Tọpẹ laarin awọn makẹta to n ta fiimu yii.
‘‘Njẹ eyin mọ bi Sọji Alabi ṣe jẹ si Tọpẹ nigba to ṣi wa lọọdẹ bọọda mi? Njẹ ẹyin mọ iye igba ti mo maa wa si Eko lati ileewe, ti mo maa ba Sọji ninu ile ẹgbọn mi pẹlu Tọpẹ nikan? Ohun ti ẹgbọn mi si maa n ṣe nigba naa ni lati fun mi ni igbati olooyi, ti yoo si lu mi gidigidi pe mo n sọ isọkusọ nipa iyawo oun ti mo ba sọ ipo ti mo ba Sọji ati Tọpẹ fun wọn. Ohun ti wọn maa n sọ fun mi nigba naa ni pe ko si ohun to pa Tọpẹ ati Sọji pọ, pe produsa Tọpẹ ati amoju ẹrọ rẹ ni.
‘‘Hummmm, afigba ti Tọpẹ ko jade nile pẹlu ọmọ kekere naa nigba ti ọmọ naa ko ti i pe ọdun kan, igba yii ni oye gbogbo ọrọ naa too ye ẹgbọn mi. Njẹ ẹ mọ pe niṣe ni Tọpẹ sọ ẹgbọn mi di onigbese nigba to lọ pẹlu bo ṣe ko fiimu ati orin rẹ ti ẹgbọn mi ṣonigbọwọ lọ?
‘‘Ẹ jẹ ki n sọ eleyii fun yin, mo si pe Tọpẹ Alabi nija lati jade sita ko waa sọ pe ko ri bẹẹ, ma a waa pe awọn mejeeji tọrọ kan sita pe ki wọn waa koju ara wọn, nigba yii ni ma a waa tu awọn aṣiri kan. Ọdun 1998 ni wọn bi ọmọ yii, ọdun 1999 ni Tọpẹ kuro nile ẹgbọn mi, o si gbe ọmọ naa lọ sọdọ awọn obi rẹ ni Mafoluku, Oshodi, ti wọn n gbe nigba naa.
‘‘Mi o le ka iye igba ti mo lọọ ṣe abẹwo sọmọ naa nigba to wa nileewe jẹle-o-sinmi. Koda, aburo mi to n jẹ Fẹmi toun naa n gbe lọdọ ẹgbọn mi paapaa maa n lọọ bẹ ọmọ yii wo pẹlu aṣọ ọdun Keresi, awọn ẹbun loriṣiiriṣii atawọn nnkan mi-in ti ọmọ yii nilo la maa n ko lọ sọdọ mama Tọpẹ ti wọn n tọju ọmọ naa daadaa nigba ti mo n sọ yii.
‘‘Mo ranti asiko kan ti mo lọọ ṣe abẹwo si ọmọ naa ti Iya Tọpẹ fi esi idanwo ọmọ naa han mi pe o mọwe daadaa, o si n ṣe daadaa nileewe.
‘‘Bẹẹ ni Tọpẹ maa n wa si Idumọta lasiko naa lati waa gbowo lọwọ ẹgbọn mi fun itọju ọmọ yii. Afi nigba ti kasẹẹti rẹ to ṣe, boya ẹlẹẹkeji tabi ikẹta to pe ni ‘Oore ti o Common’ ta daadaa, to si rowo nibẹ ni ko wa mọ.
‘‘Lẹyin ti aye rẹ yipada, to bẹrẹ si i rowo, ti okiki naa si tẹle e, o gba ọmọ naa kuro lọwọ iya rẹ, o gbe e lọ sile ọkọ to ṣẹṣẹ fẹ, nigba yẹn la si dẹkun wiwa ọmọ naa lọ.
‘‘Ọpọ igba ni ẹgbọn mi maa n pe e pe awọn feẹ ri ọmọ naa, o le ni ọwọ oun di, tabi ko ni oun ki i gbele, oun ko si ni Naijiria. Bi Tọpẹ yoo ṣe maa fonii donii, fọla dọla, fun wa niyi ta a ba ni ko gbe ọmọ naa wa, ti ko ni i gbe e wa.
‘‘Ẹgbọn mi naa ti fẹyawo o, o si ti bi awọn ọmọ, bẹẹ lo ti gbagbe iṣẹlẹ to ti ṣẹlẹ sẹyin. Ṣugbọn mi o ro pe ẹni ti ori rẹ pe kan yoo gba ọkunrin kan nimọran pe ko maa lọ sile ọkọ obinrin to kọ ọ silẹ nitori pe o fẹẹ ri ọmọ rẹ to wa nibẹ.
‘‘Ka waa lọ si ọdun 2018, nigba ti Tọpẹ ṣe ọjọọbi to ṣe ifọrọwerọ pẹlu iweeroyin ‘The Punch’, nibi ti Tọpẹ ti sọ pe wundia loun, oun ko mọ ọkunrin kankan titi ti oun fi fẹ Sọji Alabi, nibi ti wahala ti n bẹrẹ diẹdiẹ niyi, ti ọrọ ta lo lọmọ si fi waye nigba ti awọn eeyan bẹrẹ si i gbe e kiri pe Sọji Alabi lo ni ọmọ ti Topẹ Alabi, eyi ni awọn to mọ nipa ọrọ wọn fi n sọ pe ọmọ ale ni Ayọmikun. Eyi lo mu ki ẹgbọn mi kọ awọn ọrọ kan sori ikanni Instagraamu rẹ lati fidi otitọ mulẹ nigba ti ọmọ naa ṣe ọjọọbi ogun ọdun to dele aye. O fi ọrọ yii kan naa ranṣẹ si Tọpẹ, o si fi ranṣẹ si Ayọmikun paapaa.
‘‘Ki i ṣe pe ẹgbọn mi sọ pe oun fẹẹ gba ọmọ naa lati maa tọju bayii, tabi pe o ṣe eleyii lati le waa jokoo gẹgẹ bii baba lasiko ti ọmọ naa ba ṣe igbeyawo, gẹgẹ bi awọn akọroyin ori ẹrọ ayelujara kan ṣe n gbe e kiri.
‘‘Lẹyin ti ọmọ yii ṣe ọjọọbi ogun ọdun laye, lara igbesẹ ti ẹgbọn mi gbe lati fopin si awuyewuye yii ni bo ṣe pe Tọpẹ Alabi, to si beere lọwọ rẹ pe ki ni idi ti o fi yi orukọ ọmọ naa pada si ti ọkọ rẹ. Ṣe o ṣe eyi lati ma jẹ ki awọn eeyan mọ iru eeyan to jẹ tẹlẹ ni abi bawo? Ipade ti mo n sọ yii, awọn eeyan nla nla to n gbe fiimu jade ati awọn makẹta lo ṣeto ipade naa labẹ idari Alaaji Wasiu ti wọn n pe ni Wastayos Films ati Alaaji Iṣọla Saheed ti wọn n pe ni Isolak Films ni Arena, ni Oshodi. Emi naa wa nikalẹ lọjọ naa, mo si gba ohùn gbogbo ọrọ ta a sọ nibẹ silẹ. Koda, Tọpẹ Alabi gan-an sọ lọjọ naa pe a le gba ohun silẹ lori gbogbo ohun ta a sọ. Tọpẹ ni ohun kan toun mọ ni pe Ọlaoye ko ṣe aidaa kankan si ohun, bẹẹ ni ko si ro ibi si oun, pe oun ko si sọ ohun ti ko dara nipa rẹ fun Ayọmikun. O ni ti ohunkohun ba tilẹ wa, oun Tọpẹ loun ṣẹ Ọlaoye, oun si ṣetan lati tọrọ aforiji lọwọ rẹ.
‘‘O ni idi ti oun fi ni lati yi orukọ ọmọ naa pada si ti ọkọ ti oun ṣẹṣẹ fẹ ni pe lọpọ igba nigba yẹn, oun maa n rin irinajo lati lọọ kọrin loke okun, oun si maa n ni wahala ti oun ba fẹẹ mu ọmọ naa lọ nitori wọn maa ni ki oun lọọ gba iwe iyọnda wa lati ọdọ baba ọmọ naa, ṣugbọn ko le baa rọrun fun oun lati lọ si irinajo pẹlu rẹ ati lati gba iwe irinna fun un loun ṣe yi orukọ rẹ pada. O ni oun ko ṣe eleyii lati ma jẹ ki ọmọ naa mọ itan baba to bi i.
‘‘Nibi ta a wa lọjọ naa ta a ti n sọrọ lo ti fun wa ni nọmba ọmọ naa, emi ati ẹgbọn mi si ba a sọrọ lọpọ igba, ṣugbọn ko jọ pe aarin awọn mejeeji lọ gaara.
‘‘Awa la sọ fun ẹgbọn wa pe ki wọn tẹ ọrọ naa jẹẹjẹ, ki wọn si ma sọ pe awọn maa sun mọ ọmọ naa lasiko yii nitori awọn eeyan le sọ pe o fẹẹ lo ọrọ naa lati tu aṣiri awọn ohun to ti ṣẹlẹ laarin oun ati iya ọmọ naa ti ko han si ọpọ eeyan ni. O waa jẹ ohun iyalẹnu fun mi nigba ti mo bẹrẹ si i ri ọrọ oriṣiiriṣii ti awọn ti ko mọdi ọrọ, ti wọn ko mọ bi ọrọ ṣe jẹ, n sọ kaakiri.
‘‘Awa ko gba a lero lati wa iṣubu ẹnikẹni, gbogbo wa la ni awọn ohun ta a ti ṣe sẹyin. Ohun to ba si ti waye sẹyin, ẹyin naa lo yẹ ko wa, ko si sẹni to n gbero lati gba ọmọ kan tabi ṣe ohunkohun. Ohun ti ẹgbọn mi ṣe ni lati ṣalaye, ko si jẹ ki akọroyin ori ẹrọ ayelujara naa mọ pe ọmọ oun ki i ṣe ọmọ ale pẹlu bo ṣe n jẹ orukọ ọkunrin mi-in, ti wọn ko jẹ ko maa jẹ orukọ baba to bi i gan-an.
‘‘Awa ti sọ ohun to kan wa, iyẹn naa ni ẹni to bi ọmọ yii ati ẹni to ni in, ẹni to ba si wu ọmọ naa lo le pe ni baba rẹ, ko si ẹni ti eleyii maa bi ninu, nitori a mọ ẹjẹ to wa lara rẹ.
‘‘Idile to ti wa jẹ idile lati ilu Ọwọ, nipinlẹ Ondo, nigba to si jẹ pe ipinlẹ Kogi ni Sọji Alabi ti wa ni tirẹ, ohun to si daju ni pe ‘Funtọ’ ni ọmọ to n tọju yii, ti ohunkohun ko si gbọdọ ṣẹlẹ si i.
‘‘Ootọ ti ko ṣee yipada ni eleyii, bi gbogbo ọrọ si ṣe jẹ yoo tun ye onikaluku si i nigba to ba ya.’’
Ohun ti ọkunrin yii kọ niyi, eyi si jẹ ki awọn oloye sọ pe ko jọ pe ọrọ yii yoo tan nile bọrọ pẹlu awọn aṣiri to n tu jade yii.
ALAROYE tun pe ọkunrin to fẹsun kan Tọpẹ Alabi lati gbọ ọrọ lẹnu rẹ, ṣugbọn pipa ni foonu re wa titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii, Bakannaa si lọro ri pẹlu foonu Tọpe, oun naa pa foonu re ni.