Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Latari rogbodiyan to n waye lemọ lemọ lori ọrọ aala ilẹ laarin awọn eeyan ilu Ude ati Isinigbo nijọba ibilẹ Ariwa, Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti kede ofin konilegbele oni wakati mẹrinlelogun.
Akeredolu to gba ẹnu Kọmisanna feto iroyin rẹ, Ọgbẹni Donald Ọjọgo, sọrọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni ijọba ti ṣe ipade pẹlu awọn ẹsọ alaabo lori bi ofin tuntun naa ṣe fẹẹ fẹsẹ mulẹ titi ti alaafia yoo fi pada jọba lawọn ilu mejeeji.
O ni ko si aaye fun ẹnikẹni lati maa rin kiri, bẹẹ ni ko gbọdọ si igbokegbodo ọkọ tabi ti ọkada laarin ọjọ ti iṣede naa ba fi wa nita.
Aketi ni ijọba ti bẹrẹ ẹkunrẹrẹ iwadii lori ohun to ṣokunfa rogbodiyan ọhun ninu eyi ti wọn ti ṣeku pa eeyan meji, ti wọn si tun ba ọpọ dukia jẹ.
O ni o di dandan kọwọ tẹ gbogbo awọn to lọwọ ninu wahala naa ki wọn le waa jiya to tọ labẹ ofin.
Ọjọbọ, Tọsidee ọsẹ to kọja ni Ajagun tilu Ude, Ọba Adewale Bọboye, rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Ondo lati tete wa nnkan ṣe si bawọn eeyan kan ṣe n lepa ẹmi rẹ lẹyin tile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti da a lare lori ọrọ ilẹ ti oun atawọn eeyan Isinigbo n fa mọ ara wọn lọwọ.
O ni awọn tọọgi ọhun ni wọn tun pada waa jo ile oun keji lẹyin aafin ti wọn ti kọkọ jo lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja, o ni apapọ nnkan ti oun sọnu sinu wahala naa le ni miliọnu lọna ọgọfa Naira daadaa.