Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọba Yisa Ọlaniyan, Onipokia ti Ipokia nipinlẹ Ogun, ti kilọ fawọn aṣọbode ti wọn yi agbegbe rẹ ka lati dawọ ipaniyan to n waye nigba gbogbo duro. Ọba ni ẹgbẹrun kan apo irẹsi ti wọn n tori ẹ yinbọn paayan ko to ẹmi eeyan kan ṣoṣo.
Ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii ni Onipokia ṣe ikilọ naa fun alakooso ẹkun kin-in-ni kọstọọmu nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Peter Kolo, nigba ti ọkunrin naa ṣabẹwo si i niluu Ipokia.
‘Sọ fawọn eeyan rẹ ki wọn yee pa awọn araalu mi nitori irẹsi, ẹgbẹrun kan apo irẹsi ko to ẹmi eeyan kan ṣoṣo. Ki i ṣe pe mo faramọ fayawọ ṣiṣe, ṣugbọn mi o le gba ki ẹmi awọn eeyan mi maa bọ laiṣẹ nitori apo irẹsi lasan.’ Bẹẹ ni Onipokia wi.
Nigba to n dahun si ọrọ Kabiyesi, ọga kọsitọọmu naa sọ pe oun naa ko fẹran ipaniyan, bẹẹ lawọn eeyan oun ki i deede lo nnkan ija, afi ti ọrọ ba fẹẹ ba eyin yọ.
Kolo fi Kabiyesi lọkan balẹ, o loun ko ni i gba ki ẹmi alaiṣẹ sọnu mọ nitori irẹsi bo ṣe maa n waye.
Ṣe lọpọ igba lẹmi awọn ti ko tiẹ mọ nnkan kan nipa fayawọ maa n sọnu n’Ipokia, lasiko tawọn kọstọọmu atawọn onifayawọ ba wọya ija. Aimọye awọn ti ko mọwọ-mẹsẹ ni wọn ti ba ogun irẹsi lọ.