Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
TRACE, iyẹn ajọ to n ri si titele ofin irinna to si n fọwọ ofin mu awọn arufin nipinlẹ Ogun, ti sọ ọ di mimọ pe eeyan mejilelọgọjọ (162) lo padanu ẹmi wọn ninu ijamba oju popo nipinlẹ Ogun laarin oṣu kin-in-ni ọdun yii si oṣu kọkanla to kọja.
Ọjọ Aje ọsẹ yii ni Kọmandanti Ṣeni Ogunyẹmi, ọga TRACE, sọrọ naa nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, lasiko to n ṣepade pẹlu igbimọ to n ri si inawo ati iṣuna nile naa.
Ogunyẹmi ṣalaye pe aisi imọ to peye nipa ọkọ wiwa loju popo lo n fa ijamba fawọn awakọ, o ni TRACE ti la awọn ilana kan kalẹ lati kọ awọn awakọ to le ni irinwo lawọn ọna ti ijamba yoo fi dinku jọjọ.
O fi kun un pe asidẹnti to din diẹ lẹgbẹrin (774) lo ṣẹlẹ kaakiri ipinlẹ Ogun lati oṣu akọkọ ọdun yii titi de oṣu kọkanla, awọn to farapa sile ni ẹẹdẹgbẹrun kan(927).
Lati le pa miliọnu ogun le ni irinwo to ni ajọ yii gbero lati mu wọle lọdun 2021, Ọga TRACE lawọn nilo awọn eeyan si i lẹnu iṣẹ àwọn.