Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii n lọọ gbẹsan iku ọkan lara wọn lọwọ tẹ wọn l’Ọta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Bi awo ba ku awo ni i sinku awo ni wọn fẹẹ fọrọ ṣe ko too bu wọn lọwọ o, iyẹn awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun marun-un ti mọto pa ọkan lara wọn ti wọn si fẹẹ lọọ gbẹsan iku naa, ti wọn waa n gbe oku kiri ninu kẹkẹ Marwa, lagbegbe Ọta, nipinlẹ Ogun, lọjọ Mọnde, ọjọ kẹrinla oṣu kejila ọdun 2020.

Awọn ti wọn n gbe oku kiri naa ni: Babatunde Shittu; ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn(25), Ayọbami Morẹnikeji; ọmọ ọdun mẹẹẹdogun,(15) Fidelis John; ẹni ọdun mẹtalelogun(23) Abdullah Adegbenro; ọmọ ọdun mẹtadinlogun (17) ati Oyeyẹmi Bakare ti oun jẹ ọmọ ogun ọdún(20)

 

DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ṣalaye pe awọn eeyan ni wọn ta awọn ọlọpaa lolobo pe awọn kan n gbe oku èèyàn kiri ninu kẹkẹ Maruwa, wọn mu ori le ọna Ọta, ṣugbọn pẹlu nnkan ija bii ada ati kumọ ni wọn n lọ.

Eyi lo mu ACP Monday Agbonika ti i ṣe ọga ọlọpaa agbegbe Sango ko awọn eeyan rẹ lẹyin, ni wọn ba ri awọn to n gbe oku kiri naa loju ọna Ilo Awẹla, nibi ti wọn ti n ba dukia awọn eeyan jẹ, ti wọn n ja awọn ẹni ẹlẹni to n kọja lọ lole pelu awọn nnkan ija ti wọn ni lọwọ.

Awọn marun-un lọwọ ba ninu wọn, wọn ṣalaye pe pati lawọn lọ ni Muṣin, l’Ekoo, bi ija ṣe ṣẹlẹ nigba tawọn n pada bọ niyẹn, to di pe àwọn alatako awọn fi mọto pa ọmọkunrin tawọn n gbe oku ẹ kiri yii. Wọn ni ile ẹbi awọn to pa a lawọn n gbe oku naa lọ lati gbẹsan iku rẹ. Orukọ awọn to pa a naa gẹgẹ bi wọn ṣe da a ni: Ọmọ ẹkùn, Lampard àti Anko.

Alukoro ọlọpaa sọ pe kawọn eeyan oun too de ibi ti wọn ti mu awọn ọmọ yii, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti ba mọto jiipu Highlander kan jẹ. Emmanuel Adekọya lorukọ ẹni to ni mọto naa, KJA 275GD si ni nọmba rẹ bi Oyeyẹmi ṣe wi. O ni wọn ti ja foonu Infinix gba lọwọ Falọla Olushọla, wọn si ti gba ẹgbẹrun lọ́na àádọ́ta naira lọwọ ẹnikan to n jẹ Emmanuel Agbaje.

Àwọn ọlọpaa ti gba oku naa lọwọ wọn, wọn ti gbe e lọ si mọṣuari Ifọ, wọn si ko awọn agbokuukiri naa lọ sẹka itọpinpin gẹgẹ bii aṣẹ CP Edward Ajogun.

Leave a Reply