Dada Ajikanje
Ohun ti ọkan ninu awọn oluṣọagutan ijọ Anglican, The Retd Revd Biṣọọbu Ajilẹyẹ Adepọju, ko ro lo ba pade pẹlu bi awọn adari ijọ naa ṣe jawee gbele-ẹ fun un nitori ẹsun agbere ti wọn fi ka an.
Biṣọọbu yii ni adari gbogbo ijọ naa ni Iwọ Oorun Ekiti, ẹsun ti wọn si fi kan an ni pe o n ba iyawo ọkan ninu awọn alufaa to wa labẹ rẹ lo pọ. Ọkunrin naa si ti jẹwọ nigba ti wọn pe e siwaju awọn igbimọ oluwadii kan lọjọ kẹwaa, oṣu kejila yii, pe loootọ loun huwa buruku naa.
Ninu iwe ti wọn kọ si ọkunrin naa lati da a duro fungba diẹ, eyi ti Oluṣọagutan Henry C. Ndukaba fọwọ si lo ti kọ pe ‘‘ Pẹlu ọkan wuwo la fi kọwe ‘gbele ẹ’ fun ọ gẹgẹ bii Biṣọọbu Diocesan Anglican Ekiti West.
‘‘Igbesẹ yii ko sẹyin iwa idojutini ti o hu pẹlu bi o ṣe n ba ọkan ninu awọn iyawo alufaa to wa labẹ rẹ ni ajọṣepọ, to o si fidi ọrọ yii mulẹ ninu ipade ti a ṣe pẹlu rẹ ni ọọfiisi wa ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu kejila yii.
‘‘Pẹlu igbesẹ yii, o ko gbọdọ kopa ninu ohunkohun gẹgẹ bii biṣọọbu agbegbe naa fun odidi ọdun kan gbako latọjọ ti o ba ti gba iwe yii.
‘‘Ki o si yọju si biṣọọbu agba fun itọni ti ẹmi siwaju si i.’’