Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Damilare Oyeniyi, ẹni ọgbọn ọdun, ati Emmanuel Okori, toun jẹ ẹni ogun ọdun, ko le ṣe Keresi ati ọdun tuntun nile wọn, idi ni pe wọn fipa ba ọmọ ọdun mọkandinlogun lo pọ, l’Ọta, ọwọ palaba wọn si ti segi.
Ọjọ kejila, oṣu kejila yii, ni wọn huwa naa, ṣugbọn ọjọ kẹrindinlogun, lọwọ awọn ọlọpaa ba awọn mejeeji. Ọmọ ti wọn ṣe kinni fun lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Sango.
Ọmọbinrin naa ṣalaye pe ile kan naa loun atawọn gende yii n gbe, niṣe ni wọn si fi agbara fa oun wọ yara ọkan ninu wọn, wọn ja oun sihooho, wọn si fidio ihooho oun ki wọn too ba oun lo pọ nikọọkan.
Nigba ti DPO teṣan naa, CSP Godwin Idehai atawọn eeyan yoo fi de ile tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, awọn afurasi mejeeji ti sa lọ.
Ṣugbọn l’Ọjọruu to kọja yii, awọn ọlọpaa wa wọn ri, wọn si mu awọn mejeeji ṣinkun.
Awọn gende meji yii jẹwọ pe loootọ lawọn ba ọmọdebinrin ọhun lo pọ, awọn si fidio ihooho ẹ loootọ. Wọn ni ko ma baa loun yoo sọ feeyan lawọn ṣe ya aworan ihooho ẹ, awọn fi dẹru ba a ko ma baa sọ ni, awọn ko mọ pe yoo pada gbe ọrọ naa de teṣan.
DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, sọ pe ọga awọn, CP Edward Ajogun, ti paṣẹ pe ki wọn ko awọn atilaawi mejeeji lọ sẹka to n ri si ṣiṣe ọmọ niṣekuṣẹ,wọn si ti wa nibẹ, wọn n gba atẹgun olooru.