Dada Ajikanje
Lati le fopin si bi arun Korona ṣe tun bẹrẹ si i ran kaakiri ilẹ wa lẹẹkeji, igbakeji aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Alaaji Atiku Abubakar, ti gba ijọba Buhari nimọran lati ma ṣe gba awọn ọkọ ofurufu to n wa lati orileede Gẹẹsi, United Kingdom, laaye nilẹ wa. O ni lati ibi iwọle awọn eeyan to n ba ọkọ ofurufu ọhun wọle ni arun naa fi tun fẹẹ maa ran ka bii ina alẹ nilẹ Naijiria bayii.
Ninu atẹjade kan to fi sita niluu Abuja lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, eyi to pe akọle rẹ ni ‘‘ Ki a dena nnkan dara ju ka maa nawo repẹtẹ si i lọ’’ lo ti sọrọ naa.
Igbakeji aarẹ tẹlẹ naa ni, awọn orileede ti wọn mọ ohun ti wọn n ṣe ti n gbe igbesẹ lati dena wahala naa nipa titi ẹnubode wọn pa. Pẹlu bi ọkọ ofurufu si ṣe n lọ to n bọ lati ilẹ wa si ilẹ Gẹẹsi, o ti yẹ ki ijọba wa gbe igbesẹ lori rẹ.
O ṣalaye pe o yẹ ki ilẹ wa Naijiria naa ṣe awokọṣẹ awọn ilẹ Yuroopu, eyi ti ko gba ki ọkọ ofurufu lati ilẹ Gẹẹsi wọ ilẹ wọn lati le dẹkun itankalẹ arun Korona to ti tun n pọ si i bayii.
Atiku ni, a ko gbọdọ sa fun otitọ ọrọ to wa nilẹ bayii pe pẹlu bi eto ilera ṣe ri nilẹ wa, ko si ohun ti a fi le koju arun Korona yii bo ba burẹkẹ tan. Ọkunrin naa ni ọpọlọpọ ẹmi la ti sọnu nipasẹ arun aṣekupani yii, ko si tun waa yẹ ka tun sọ ẹmi nu lasiko yii mọ.
O fi kun un pe aitete gbe igbesẹ to yẹ nigba ti arun naa kọkọ bẹrẹ, ti awọn eeyan si n pariwo pe ki ijọba ti awọn ẹnubode wa, ṣugbọn ti wọn ko gbọ lo fa a ti arun naa fi wọle sọdọ wa, to si mu ẹmi opọ eeyan lọ.