Faith Adebọla, Eko
Ahamọ ọlọpaa lawọn mẹwaa tọwọ ba pe wọn lọọ doju ija kọ awọn oṣiṣẹ ijọba ikọ amunifọba to n ri si imọtoto ayika (Lagos State Enviromental Sanitation Enforcement Agency Taskforce), latari awọn ọkada ti ikọ naa gba lọwọ wọn.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, agbegbe Ojodu ati Ọbanikoro, nipinlẹ Eko, ni yanpọnyanrin naa ti waye, nigba tawọn oṣiṣẹ ijọba naa mu awọn ọkada mẹrindinlọgọrun-un lapapọ, ti wọn si gbẹsẹ le wọn, wọn ni ọna tijọba ti ka leewọ fawọn ọlọkada naa ni wọn gba.
Yatọ si tawọn ọlọkada, eeyan mẹrin mi-in lawọn agbofinro naa tun mu, ti wọn gba mọto tiwọn naa, wọn lawọn yẹn wa mọto gba ọna ọlọna.
Ninu alaye ti Alaga ikọ amuṣẹṣẹ naa, SP Shọla Jẹjẹloye, ṣe, o ni nibi tawọn agbofinro ti n gbe ọkada ti wọn gba lagbegbe Ojodu sinu mọto lawọn afurasi ọdaran yii ti ya bo wọn pẹlu igi, irin gbọọrọ, okuta, atawọn nnkan ija mi-in, ti wọn si fẹẹ bori awọn oṣiṣẹ ijọba.
O lo ṣoro fawọn ọlọpaa lati yinbọn, tori awọn araalu rẹpẹtẹ ti dapọ mọ awọn to waa kọju ija si wọn yii, igba ti wahala naa rọlẹ diẹ ni wọn ri awọn wọnyi mu.
Ọrọ naa ko yatọ lagbegbe Ọbanikoro, niṣe lawọn afurasi yii n sọ okuta lu awọn agbofinro, wọn o ṣaa fẹ ki wọn ko ọkada wọn lọ. Ọpọ wakati lo ni wahala naa fi waye ki wọn too le ṣiṣẹ wọn.
Shọla ni awọn ti fa awọn tọwọ ba yii le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ lati wadii, ki wọn si fẹsẹ ofin to ọrọ wọn.
Sibẹ, o ni awọn yoo maa ba iṣẹ awọn niṣo lati mu aṣẹ ijọba ṣẹ lori ofin irinna, paapaa lasiko pọpọṣinṣin ọdun yii, o si kilọ fawọn ọlọkada ati onimọto lati ma ṣe tapa sofin, tori wọn yoo foju wina ofin ti wọn ba ṣe bẹẹ.