Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Ibinu ni Ọnarebu Adegoke Adeyanju Awọṣọ to n ṣoju ẹkun Ayetoro nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun fi ba ALAROYE sọrọ nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejilelogun, oṣu kejila yii, lẹyin iku ojiji ti awọn kọsitọọmu ti wọn tori irẹsi ilẹ okeere wa si agbegbe Kikẹlọmọ, l’Ayetoro, fi pa ọkunrin kan, Ṣọla Ṣọga, to n ṣiṣẹ rẹ jẹẹjẹ, to jẹ niṣe ni ibọn awọn aṣọbode naa ba a laya lojiji, to si ku loju-ẹsẹ, nibi to duro si.
Yatọ si Ṣọla tawọn eeyan mọ si Ishow to ku iku ojiji yii, awọn meji mi-in ni ibọn tun ba laaarọ ọjọ Iṣẹgun naa, to jẹ niṣe ni wọn gbe wọn digbadigba lati yọ ọta ibọn ọhun jade lara wọn. Bẹẹ lawọn mi-in tun fara ṣeṣe nibi ti wọn ti n sa kiri, ọpọ lo si wa lọsibitu ti wọn n gba itọju lọwọ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Awọṣọ sọ pe ‘‘Nigba ti mo n lọ si Igbogila nirọlẹ yii, mo pade mọto awọn ṣọja atawọn kọsitọọmu bii marun-un, wọn n bọ lati Ayetoro ti wọn ti lọọ pẹtu si wahala to ṣẹlẹ.
‘‘Ọrọ yii ṣẹ n kọja afarada, ki lo de? Awọn aṣọbode yii n gbowo lọwọ awọn to n ko irẹsi wọle lati Benin ati Port Novo, ori ilẹ ni wọn n gba, ki i ṣe ori omi, wọn o ni i mu wọn nigba yẹn. O digba ti wọn ba ko awọn irẹsi naa wọle tan ki wọn too maa le wọn kiri adugbo. Iya oniyaa to n ta gure ẹ jẹẹjẹ, ti ko kọja aaye ẹ, pẹlu awọn ẹni ẹlẹni to n kọja wọn lọ aa maa waa kagbako iku ojiji lọwọ kọsitọọmu. O dẹ kere tan, awọn aṣọbode yii maa wa ni bii ọgọta aaye lẹnu ibode, wọn aa maa gbowo lọwọ awọn to n ko irẹsi wọle, ti mo ba ri ọga awọn kọsitọọmu yẹn patapata ma a sọ ọ loju ẹ, awọn ni wọn n gbowo lọwọ awọn to n ko irẹsi wọle, o digba ti wọn ba ko ọja naa debi ti wọn n tọju ẹ si kawọn kọsitọọmu too tun maa daamu wọn.
‘‘Ọsọọsẹ ni wọn n pa wa nibi, mi o dẹ gbọ ọ ri pe kọsitọọmu pa onifayawọ kan nilẹ Hausa. A kan n tanra wa jẹ ni, ko si nnkan to n jẹ ‘wan Naijiria (One Nigeria)
‘‘Wọn ni wọn ti bọda, irọ buruku ni. Gbogbo igba ti wọn ni wọn ti bọda yii naa ni awọn irẹsi yii n wọle. Titi disinyii ti wọn ni ki wọn ṣi i naa, wọn o ṣi i nnkan kan. Oun nibọn ba eeyan mẹta yẹn, ti ẹni kan ku. Eleyii ti kọja afarada o, o ti to gẹẹ.’’
Ṣe laaarọ ọjọ Iṣẹgun naa ni rogbodiyan yii ṣẹlẹ, ti wọn ni awọn aṣọbode ya bo ile ikẹru-si kan ti wọn ja ọpọlọpọ irẹsi ilẹ okeere si.
Wọn ti ko irẹsi naa, wọn si ti fẹẹ maa lọ ki ẹni to ni ile ikẹru-si ọhun too jade lati ba wọn sọrọ boya wọn yoo gbọ. Ṣugbọn awọn aṣọbode naa ko fẹẹ gbọ nnkan kan gẹgẹ ba a ṣe gbọ, bi wọn ṣe bẹrẹ si i yinbọn niyẹn, ti ibọn ọhun si ṣẹ bẹẹ lọọ ba awọn ẹni ẹlẹni ti ko mọwọ-mẹsẹ.
Niṣe lo di rogbodiyan nla, ti awọn araalu di gbogbo ọna abawọle agbegbe Kikẹlọmọ pa, kawọn kọsitọọmu naa ma baa le le sa lọ. Nigba ti apa awọn ẹṣọ naa ko fẹẹ ka ohun to n ṣẹlẹ mọ ni wọn ranṣẹ pe awọn eeyan wọn n’Idiroko pe ki wọn waa kun awọn lọwọ. Gbogbo agbegbe yii ko si fara rọ fungba pipẹ, afigba tawọn ẹṣọ atawọn ṣọja to waa kun wọn lọwọ de.
Ohun ti yoo ṣẹlẹ lẹyin rogbodiyan yii ko ti i ṣe e foju sun, nitori ALAROYE gbọ pe ara n kan awọn eeyan agbegbe bọda yii pupọ, o si ṣee ṣe ki wọn ṣigun sawọn kọsitọọmu lori ọrọ irẹsi ilẹ okeere to n fa iku alaiṣẹ lọpọ igba yii.