Iya mi ti kọ mi pe gbogbo bo ṣe wu ko ri, mi o gbọdọ kọ ọkọ mi silẹ – Abilekọ Ẹniitan

Ọdun kẹrindinlọgọta (56) ree ti Oloye Abiọdun Dominic Ẹniitan ti fẹ iyawo wọn, Abilekọ Cecilia Abikẹ Ẹniitan. Ọdun 1964 ni wọn ti ṣegbeyawo niluu Eko, awọn mejeeji ti di arugbo kujẹkujẹ bayii, ṣugbọn bi igbin ba fa, ikarahun rẹ yoo tẹle e ni wọn jọ n ṣe.

Akọroyin ALAROYE nipinlẹ Ogun, ADEFUNKẸ ADEBIYI, ṣabẹwo sile awọn tọkọ-taya ọlọdun gbọọrọ naa n’Ilewo-Orile, nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta, eyi lohun ti wọn sọ pe o gbe igbeyawo awọn duro titi di asiko yii.

BABA: Emi ni Oloye Abiọdun Ayinde Dominic Ẹniitan, ẹni ọdun mejidinlaaadọrun(88) ni mi, emi ni Seriki Ilewo-Orile nibi, ilu yii naa ni wọn ti bi mi. Orukọ iyawo mi ni Cecilia Ọlabisi ọmọ Ogunfọlaji, aya Ẹniitan.

Mo pade iyawo mi nipasẹ ọrẹ mi, Oloogbe Benjamin Fọla Akiyọde, to n fẹ ọmọ kan n’Igbeyin. Ọmọ ti ọrẹ mi n fẹ yẹn ni baba ẹ ku ti a lọọ ba wọn ṣe oku, nibẹ ni mo ti ri iyawo mi to dẹ wu mi. Aṣọ to wọ lọjọ yẹn ba a mu pupọ, niṣe lo ṣe rẹgi lara ẹ. Bo ṣe ri lọjọ yẹn lo ko si mi lọkan ti mo fi pinnu pe mo maa fẹ ẹ.

Iru aṣọ to wọ lọjọ naa

Aṣọ kekere bii bonfo bayii ni, ọpa meji ni wọn fi n ran an, wọn aa ṣẹṣẹ waa wọ omi-in le e lori, aṣọ yẹn fain pupọ lara Ọlabisi, bi mo ṣe sọ fun ẹgbọn ẹ obinrin niyẹn ti wọn ba mi sọ fun un. Ko gba o, ko kọkọ da mi lohun, a tun pinya nigba to ya paapaa, ṣugbọn nigba ti Ọlọrun sọ pe a maa fẹra wa, o wa si imuṣẹ.

Nigba ti a pinya

1958 la kọkọ pade ti mo ni ki wọn ba mi ba a sọrọ. Nigba ti ọrọ wa ti n wọ daadaa, mo wa a lọ sile wọn lọjọ kan, aṣe baba wọn wa nile. Bi baba ṣe yọju latoke ti wọn ri mi ni wọn fi ede Ẹgba beere pe, ‘‘Lee wa o, lee o n bebi ( Ta niyẹn o, ta lo n beere). Ọlọrun dẹ fun mi nigboya, mo dahun pe emi ni o, Labisi ni mo n beere. Baba tun ni ki lo de, mo ni ọrẹ mi ni, a jọ n ṣọrọ ni. Labisi funra ẹ ti fẹrẹ gan sinu ile, ibẹru ko jẹ ko le jade bo ṣe n gbọ ohun ti emi ati baba n sọ.

A rira lalẹ ọjọ yẹn o, ṣugbọn arimọ niyẹn lọdun naa. Niṣe ni baba mu un lọ s’Ekoo nitori temi, Eko ni baba n gbe, ṣugbọn wọn nile l’Abẹokuta naa. Bi wọn ṣe mu iyawo mi lọ niyẹn, mi o dẹ ri i mọ lati ọdun naa titi di ọdun 1963 ti iṣẹ tiṣa ti mo n ṣe gbe mi lọ s’Ekoo.

Wọn tiẹ ti gbe mi kiri titi ki wọn too gbe mi lọ s’Ekoo yẹn, ibinu ni ọga to gbe mi lọ s’Ekoo fi gbe mi, ko mọ pe Ọlọrun fẹẹ lo oun lati mu mi ri iyawo mi pada ni. Ita ile wọn bayii ni mo maa n gba kọja ni Yaba ti iṣẹ gbe mi lọ, ṣugbọn mi o mọ pe ile wọn ni. Nigba ti asiko to ṣaa, a rira wa pada, baba rẹ naa tun ri mi, wọn o binu mọ, iyẹn lọdun 1963, niṣe ni wọn ni ki n lọọ pe baba mi wa, wọn dẹ sọ fun Labisi naa pe awọn ko fẹẹ ri ẹlomi-in pẹlu ẹ ju emi lọ. Ba a ṣe to gbogbo ẹ bo ṣe yẹ niyẹn, ta a ṣegbeyawo ninu oṣu kẹsan-an, ọdun 1964.

Mo gbadun iyawo mi daadaa nitori idaṣẹsilẹ wa kaakiri Naijiria nigba yẹn, awọn oṣiṣẹ ijọba daṣẹ silẹ loṣu ti mo ṣegbeyawo yẹn, o dẹ to oṣu kan ko too pari, bi a ṣe n ṣe faaji wa lọ niyẹn.

Owo ti mo n gba loṣu nigba ta a ṣegbeyawo ko ju ọgbọn naira lọ

Oṣu kin-in-ni, ọdun 1960, ni mo bẹrẹ iṣẹ tiṣa, naira mejidinlogun ati aadọta kọbọ (18,50k) ni mo n gba loṣu. Nigba ti mo ṣegbeyawo, mo n gba ọgbọn naira, a n maneeji ara wa pẹlu ẹ. Iyawo mi naa n ta awọn nnkan eelo telọ, o dẹ n  cvranṣọ, ba a ṣe n fọwọ wẹwọ niyẹn titi ta a fi tọ gbogbo awọn ọmọ wa. Ọkunrin marun-un, obinrin mẹta la bi.

Ba a ṣe n nawo yẹn

Ti mo ba ti gba salari, mo maa ra awọn nnkan ta a niidi nile, ounjẹ ọmọ ta a ba n tọ lọwọ, agolo bii mẹrin ẹ ni ma a ra silẹ. A maa ra miliiki ọlọpẹ atawọn ounjẹ ti awa yooku naa maa jẹ. Nigba ti yoo ba fi tan, owo oṣu mi-in aa ti de. Ba a ṣe yi i mọra wọn titi ti Ọlọrun dẹ ṣaanu wa niyẹn. Mo kọle s’Owode, mo tun kọ s’Ilewo nibi. Mo si fi ọdun marundinlogoji ṣiṣẹ tiṣa ki n too fẹyinti.

A maa n ja, ṣugbọn funra wa la n pari ẹ

Ahọn atẹnu n ja, wọn n pari ẹ naa ni. Bi ọrọ ba dẹ fẹẹ le ju, mo maa mẹwu ni, mo n jade lọ niyẹn. Nigba ti mo ba maa fi de, inu kaluku maa ti yọ.

Awọn nnkan to maa n faja

Awọn nnkan keekeeke lo maa n faja, bii ki n lọ sibi iṣẹ kounjẹ ma ti i delẹ. Bii ki n ni ki wọn ma ṣe nnkan ki wọn ṣe e, ohun to maa n faja naa niyẹn. Ṣugbọn suuru la fi n ṣọkọ obinrin, teeyan ba ti ni suuru, to dẹ n gbadura, Ọlọrun maa ba a mu igbeyawo ẹ duro.

Idi to fi jẹ iyawo kan ni mo fẹ

Mo ti pe ẹni ọgbọn ọdun ki n too ṣegbeyawo, mi o tiẹ ki n le ba obinrin sọrọ, niṣẹ lawọn eeyan maa n sọ pe ṣe kawọn ba mi ba obinrin sọrọ, bi mo ṣe ri niyẹn. Idi keji ni pe mo kẹkọọ lati ara baba mi. Obinrin mẹta lo bimọ fun baba mi, mo mọ ohun ti wọn fi mi ṣe. Wọn o fẹ ki n kawe, bẹẹ, mo mọ irawọ ti Ọlọrun fun mi, mo si mọ ibi ti aye ba ara wọn de.

Asiko to ba yẹ ki n lọ sileewe, abẹ igi ọdan ti eegun ti n jo ni mo maa lọọ jokoo si, ibẹ ni mo maa wa titi tawọn to lọ sileewe yoo fi de. Ṣugbọn igba ti Ọlọrun sọ pe ma a kawe, mo ka a. Mo lọ si Ikereku United, mo ka sitandaadi tiri ( Standarad 3) nibẹ, mo lọ si St.Augustine, l’Abẹokuta, ibẹ ni mo ti ka a de Standard 6. Mo lọ si St Leo’s Teachers’ College. 1995 ni mo fẹyinti ti mo ko wa sile.

Ṣiṣẹ lọkọ-laya

Ko si iyẹn mọ bayii o, ko si agbara biba obinrin lo pọ mọ nitori agba ti de. Ṣugbọn ifẹ aiṣẹtan ta a fi bẹrẹ ṣi wa nibẹ, iyawo igba ewe mi naa la ṣi jọ wa, a o si jọ wa pẹ si i lagbara Oluwa.

Mama

Orukọ mi ni Cecilia Ọlabisi Abikẹ Ẹniitan, ọmọ Ogunfọlaji.  Ẹni ọdun mejidinlọgọrin(78) ni mi bayii. Ọmọ Igbeyin ni mi, l’Abẹokuta. Mo lọ sileewe St Peters, l’Ake. Mo tun lọ si St John Primary School, ni Kutọ. Mo lọ si Imo Methodist Girls High School.

Mi o fi bẹẹ da ọkọ mi laamu ki n too gba lati fẹ wọn

Loootọ ni ki i ṣe pe ọjọ ti wọn lawọn maa fẹ mi naa ni mo gba fun wọn, ṣugbọn mi o da wọn laamu pupọ. Irun kan ti wọn da si ni gbogbo ẹnu nikan ni mo ni emi o fẹ o.

Mo sọ fun aunti mi ti wọn ran si mi pe emi o le fẹ ẹ pẹlu gbogbo irun to da si yii o. Ti irun tun kun gbogbo ori ẹ, mo ni to ba le lọọ ge irun yẹn kuro, ka maa wo o na boya yoo ṣe e ṣe. Nigba to dẹ maa fi pada wa loootọ, o ti gẹ gbogbo irun yẹn kuro, ba a ṣe bẹrẹ si i sọrọ niyẹn. Latigba naa lo ti wa bayii, ti ko da irun kankan si mọ.

Lọjọ to wa mi wa ti ibẹru baba ko jẹ ki n le sọrọ

Mo ti pari nileewe nigba yẹn o, ṣugbọn ibẹru baba mi wa lọkan mi. Wọn ti mọ pe o fẹẹ fẹ mi ni. Nigba ti wọn waa n bi mi pe ki lo n wa lọdọ mi, mi o le sọ nnkan kan fun wọn nitori ẹru n ba mi. Nigba ti baba waa mu mi lọ s’Ekoo, ta a tun pada rira, wọn fọwọ si i, inu wọn tiẹ dun nigba ti wọn gbọ pe Katoliiki loun naa.

Ṣọọṣi Regina Mundi la ti ṣegbeyawo

Muṣin, l’Ekoo, ni ṣọọṣi Regina Mundi, la ti ṣegbeyawo, ṣọọṣi Katoliiki ni. Katoliiki ni mi, oun naa dẹ lokọ mi. Oṣu kẹsan-an, ọdun 1964 la ṣe e, ṣugbọn mi o ranti ọjọ to jẹ gan-an mọ.

Ọkunrin ko le ṣe ko ma ṣe iṣẹ ọkunrin, suuru la fi n gbe

Aimọye nnkan lo maa n fa ija, nitori ọkunrin ko le ma ṣe iṣe ọkunrin. Ba a ṣe dagba to yii naa, a si maa n ja. Ṣugbọn gẹgẹ bii Katoliiki, ti mo ba ti ranti pe oorun ko gbọdọ wọ ba ibinu wa, mo maa bẹ wọn, mo maa ri i pe o pari. Funra wa naa la n pari ija wa. Suuru la fi n gbe ọpọlọpo ninu ẹ, suuru gidi paapaa.

A ki i ni ibalopọ mọ, ara ko tiẹ beere fun un mọ

Bẹ ẹ ṣe ri wa ta a duro deede yii, nitori a ki i ba ara wa sun mọ tipẹtipẹ ni. Ọdun 1985 ni mo ti bi abigbẹyin, Fada lọmọ naa paapaa, o ti n sin Oluwa, ko ni i fẹyawo, ko dẹ ni i bimọ.

Ki waa ni iru awa ta a ti di arugbo bayii aa maa ṣe iru ẹ fun.

To ba jẹ pe a n ṣe e ni, ara maa ṣe dẹgẹdẹgẹ ni, a o ni i ṣara giri bayii. Ọkọ mi ni yara tiẹ, emi naa ni temi, ifẹ wa laarin wa daadaa, ṣugbọn ko si aaye a n ba ara ẹni sun mọ.

Ohun to gbe ile wa duro di bayii

Iya mi maa n sọ pe ti wọn ba ni mo gọ, ki n sọ fun wọn pe loootọ ni, mo fẹnu họra paapaa, ṣugbon ki n ṣaa jokoo ti ọkọ mi, mi o gbọdọ kọ ọ.

Wọn ni gbogbo bo ba ṣe ri, mi o gbọdọ kọ ọkọ mi silẹ, ki n ṣaa maa ba a fọwọ wẹwọ ni gbogbo ọna, ki n dẹ maa ni suuru. Ohun ti mo n ṣe naa niyẹn titi dasiko yii.

Ọmọ wa to jẹ Fada dun mọ wa pupọ, adura iya ọkọ mi lo gba

Ki iya ọkọ mi too ku rara lo ti maa n sọ pe oun fẹ Fada ninu awọn ọmọ mi, o maa maa fi si adura pẹlu aawẹ ni. Mi o tiẹ ti i loyun ẹ rara ti mama ti maa n sọ ọ pe oun fẹ ki n bi Fada.

Nigba ti mo dẹ bi abigbeyin mi yii torukọ ẹ n jẹ Fada Rapheal Abayọmi Ẹniitan, kekere lo ti maa n sọ fun mi pe Fada loun maa ṣe o, a dẹ ni a ti gbọ. Ọjọ to lọọ gba iwe agunbanirọ ni wọn pe e ni ṣọọṣi pe ko maa bọ ni sẹminari, wọn ti mu un fun Fada to fẹẹ ṣe.

Nnkan ayọ ni, mo dupẹ pe Fada wa ninu awọn ọmọ mi. Ọkọ mi gan-an fẹẹ ṣe Fada, Ọlọrun ko pe e ni.

Imọran mi fawọn ọmọ isinyii

Suuru ni ki wọn ni, ẹni to ba ni suuru lo n gbele ọkọ. Ọkunrin to ba ni suuru niyawo ki i kọ, ki wọn si maa gbadura pẹlu.

Leave a Reply