Bo tilẹ jẹ pe ko si eeyan kankan to ku nibẹ, sibẹ, dukia to ṣegbe nibi ijamba ina kan to tun ṣẹlẹ nisọ pako to wa ni Demurin, ni Ketu, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ko ṣee fẹnu sọ.
Lojiji ni wọn ni ina ọhun sọ ni apa ibi kan ninu ọja naa, ti ko si sẹni to ti i le sọ ohun to fa a.
Ọga agba to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, Dokita Olufẹmi Oke Osanyintolu, sọ pe loootọ ni ijamba ina naa ṣẹlẹ, to si fi ọpọ dukia ṣofo, o ni o ṣee ṣe ko jẹ oyẹ to wa nita lo ran iṣẹlẹ ina ti ẹnikẹni ko ti mọ ohun to fa a naa lọwọ.
O fi kun un pe ọkẹ aimọye dukia lo ba iṣẹlẹ ina naa lọ.