Florence Babaṣọla
Baba agbalagba kan, Rafiu Abimbọla, nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti ranṣẹ si lori ẹsun pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹẹẹdogun lo pọ titi to fi loyun.
Ilu Isundunrin, nijọba ibilẹ Ejigbo, nipinlẹ Ọṣun, niṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ. A gbọ pe baba to n gbe lagboole Ọba, yii ti ba ọmọ ọhun sun laimọye igba, to ba si ti tẹ ifẹ ọkan rẹ lọrun tan ni yoo sọ fun ọmọ naa pe ọjọkọjọ to ba sọ ohun to ṣẹlẹ fun ẹnikẹni, ṣe lo maa ya were.
Eleyii la gbọ pe o fa a ti ọmọ naa fi dakẹ, to si sọ ọrọ naa di amumọra bii iso inu ẹku. Laipẹ yii lọmọbinrin ọhun bẹrẹ si i ṣaisan, to si n lọnu mọlẹ, idi niyẹn ti awọn mọlẹbi rẹ fi mu un lọ fun ayẹwo nileewosan.
Nigba ti esi ayẹwo de, jẹbẹtẹ gbe ọmọ le wọn lọwọ nigba ti dokita sọ fun wọn pe ṣe oyun oṣu mẹrin ti wa ninu rẹ. Lẹyin ọpọlọpọ arọwa lọmọ naa to jẹwọ pe baba naa maa n ba oun lo pọ.
Awọn mọlẹbi ọmọ yii fori le agọ ọlọpaa to wa niluu Ejigbo lati fi to wọn leti, ṣugbọn wọn fẹsun kan awọn ọlọpaa pe ọjọ ti wọn ranṣẹ si baba agbalagba yii naa ni wọn fi i silẹ lati maa lọ sile.
Nigba ti ALAROYE n ba alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọrọ lori iṣẹlẹ naa, o ni loootọ lawọn ti gbọ nipa rẹ, awọn SI ranṣẹ si baba naa fun ifọrọwanilẹnuwo.
Ọpalọla ṣalaye pe iya ọmọbinrin yii lo lọọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti pe baba naa fipa ba ọmọ oun sun loṣu kẹsan-an, ọdun 2020, eleyii to yọri si oyun, bẹẹ ni awọn ara ọsibitu fidi rẹ mulẹ.
O ni iwadii n lọ lọwọ lori ẹsun naa, ati pe o di dandan kileeṣẹ ọlọpaa waṣu rẹ delẹ ikoko laipẹ rara.