Stephen Ajagbe, Ilorin
Afurasi kan, Kẹhinde Kesari, to n gbe lagbegbe Ita-Amọ, niluu Ilọrin, ti di ẹni tawọn ọlọpaa n wa bayii nitori bi wọn lo ṣe gun ọmọ ọdun mejilelogun kan, Jamiu Abdulqọdir, ni daga nitori biyẹn ṣe n yin banga lọjọ aisun ọdun Keresimesi.
Iṣẹlẹ ọhun to waye lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, la gbọ pe o mu ki gbogbo adugbo kan gogo.
ALAROYE gbọ pe lasiko ti oloogbe naa pẹlu awọn ọrẹ rẹ n yin banga ṣere nitosi ile wọn ni Kẹhinde atawọn ọrẹ rẹ waa ba wọn lati kilọ fun wọn ki wọn jawọ.
Ikilọ yii ni wọn lo fa ede-aiyede laarin Jamiu ati Kẹhinde, ti wọn si bẹrẹ si i leri sira.
Ẹni tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ ṣalaye pe lẹyin iṣẹju diẹ ti awọn mejeeji tahun sira wọn ni Kẹhinde pẹlu awọn meji kan pada wa lati kọju ija si Jamiu. Ṣugbọn ṣe ni oloogbe naa bẹrẹ si i bẹ wọn.
Ohun tawọn yẹn ro ni pe Kẹhinde ti gbọ ẹbẹ, ṣugbọn boun atawọn ọrẹ rẹ mejeeji ṣe fẹẹ maa lọ ni afurasi naa tun yiju pada, to si ṣa Jamiu lagbari pẹlu daga to mu lọwọ, loju-ẹsẹ ni ẹjẹ bo o.
Wọn ni mọlẹbi oloogbe naa gbiyanju lati doola ẹmi rẹ, wọn gbe e lọ silewosan aladaani kan to wa ni Aromaradu, ṣugbọn awọn yẹn kọ ọ nitori to kọja agbara wọn. Ilewosan ijọba ti wọn pada gbe e de lo ti dagbere faye lasiko ti wọn n tọju rẹ.
ALAROYE gbọ pe lẹyin iṣẹlẹ naa, Kẹhinde ti sa kuro laduugbo, titi di asiko yii, ko sẹni to mọ ibi to wa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti waa bẹrẹ iwadii, wọn nireti ṣi wa pe ọwọ yoo tẹ afurasi naa laipẹ.