Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Latari atẹjade to ti ọfiisi Gomina Dapọ Abiọdun wa lọsẹ to kọja, pe ko gbọdọ si isin ti awọn onigbagbọ fi maa n wọ ọdun tuntun ni ṣọọṣi lasiko yii nitori Korona, ẹgbẹ Onigbagbọ ilẹ Naijiria (CAN), ti rawọ ẹbẹ si gomina lati jọwọ, gba wọn laaye lati ṣe isin naa, ko si tun fun awọn ni anfaani lati pada sile laaarọ ọjọ ọdun tuntun.
Ninu atẹjade ti Alaga CAN nipinlẹ Ogun, Biṣọọbu Ọmọwe Tunde Akin-Akinsanya, fọwọ si lorukọ ẹgbẹ Onigbagbọ ni wọn ti rawọ ẹbẹ si gomina pe ko jẹ kawọn ṣọọṣi bẹrẹ isin ti wọn yoo fi bọ sọdun tuntun laago mẹwaa aabọ alẹ ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2020.
Ki wọn si pari ẹ laago mejila kọja iṣẹju mẹẹẹdogun, lọjọ kin-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021. Wọn ni kijọba Ogun ṣe bii t’Ekoo, ti wọn ko ni ki isin ma waye, to jẹ wọn kan fi asiko ti wọn yoo fi ṣe e si i ni.
Wọn tun bẹbẹ pe kijọba jọwọ fun awọn olujọsin naa ni anfaani lati rin pada sile wọn laarin aago mejila kọja iṣẹju mẹẹẹdogun naa si aago kan oru ọjọ kin-in-ni, ninu ọdun tuntun.
CAN ni gbogbo ofin to de Koro lawọn olujọsin yoo tẹle lasiko isin ọhun, wọn ni inu awọn yoo dun bijọba ba le wo o ṣe fawọn, awọn yoo si dupẹ, nitori ki ohun gbogbo le dara si i naa ni ijọ Ọlọrun n ṣe.