Stephen Ajagbe, Ilorin
Fun pe wọn tapa sofin to de ṣiṣi ile-ijo lasiko ajakalẹ arun Korona, aadọta eeyan lọwọ tẹ ni idaji ọjọ Abamẹta, Satide, nile itura Kwara Hotels, niluu Ilọrin. Akọwe iroyin gomina to tun jẹ alukoro igbimọ to n gbogun ti arun yii ni Kwara, Rafiu Ajakaye, lo sọrọ naa ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sawọn oniroyin.
O ṣalaye pe Alaga igbimọ to n mojuto eto ilera, Medical Advisory Committee, Dokita Fẹmi Ọladiji, lo fi iṣẹlẹ naa to igbimọ yii leti. Dokita Ọladiji ni ni kete tọwọ tẹ wọn lawọn ko wọn si ibudo iyasọtọ to wa ni ipagọ awọn arinrinajo Hajj niluu Ilọrin. O ni igbakeji Gomina, Kayọde Alabi, to jẹ alaga igbimọ Covid-19 lo dari ikọ to lọọ fi pampẹ ọba ko awọn eeyan ọhun nibi ti wọn ti n ṣe faaji lai bikita nipa ofin to wa nita.
“Ni nnkan bii aago kan oru, niroyin tẹ wa lọwọ pe awọn kan wa nile-ijo, nibi ti wọn ti n ṣe faaji nile itura Kwara Hotel. Nigba ta a debẹ a ba awọn ọkunrin atawọn obinrin rẹpẹtẹ tọjọ ori wọn ko ju ogun si ọgbọn lọ.
“Arin oru yii kan naa, ni nnkan bii aago meji, la ko wọn de ibudo naa. A jẹ ki wọn farabalẹ sun mọju, a si gba ohun ta a le fi ṣe ayẹwo Korona lara wọn. A maa ṣe ayẹwo wọn lọkọọkan. A tun maa foju wọn bale-ẹjọ ki awọn eeyan le mọ pe ijọba ko ni i faaye gba titapa sofin.”
O nijọba yoo gbe igbesẹ to ba yẹ lati ba awọn alakooso ile-itura naa to gba iru nnkan bẹẹ laaye wi.