Florence BabaṣọlaObinrin kan ti ko ti i le ju ẹni ọdun marunlelogoji lọ la gbọ pe mọto kan to n sare asapajude da ẹmi rẹ legbodo laago mẹsan-an alẹ ana, Tọsidee niluu Oṣogbo.
Obinrin yii, ẹni ti wọn n pe ni Arabinrin Agboọla ni wọn lo ti kọkọ de inu ṣọọsi wọn, Cherubim and Seraphim, Ayọ ni o, to wa nikọja odo Gbodofọn loju-ọna Ogo-Oluwa niluu Oṣogbo, ko si sẹni to mọ nnkan to fẹẹ mu nita to fi jade.
Bo ṣe bọ sojuu titi ni mọto naa gba a gidigidi, dẹrẹba yẹn ko si duro, bẹẹ ni ko sẹni to roju-raaye le mọto rẹ lasiko ti wọn n ṣaajo oloogbe naa.
Gẹgẹ bi ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣe sọ, oju-ẹsẹ lobinrin naa ku, awọn ajọ ẹṣọ ojuupopo atawọn ọlọpaa ni wọn wa sibẹ lati palẹ oku rẹ mọ lọ sile igbokupamọsi.