Florence Babaṣọla
Agbẹnusọ ẹṣọ ajọ ojupopo nipinlẹ Ọṣun, Agnes Ogungbemi, ti fidi rẹ mulẹ pe obinrin kan lo jade laye, nigba ti awọn ọmọde mẹta fara pa yanna-yanna nibi ijamba mọto to ṣẹlẹ niluu Ikire lọsan-an ọjọ kin-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun tuntun yii.
Ogungbemi ṣalaye pe ere asapajude ti mọto akoyọyọ kan ati Toyota Corolla kan sa pade ara wọn lo fa ijamba naa.
O ni ṣe lawọn ọkọ mejeeji sọ ijanu wọn nu, ti wọn si fori sọ ara wọn. Eeyan mẹrin lo fara pa; obinrin kan atawọn ọmọde mẹta.
ALAROYE gbọ pe wọn gbe obinrin naa lọ sileewosan Ọbafẹmi Awolọwọ University Teaching Hospital, Ile Ifẹ, ṣugbọn ko pẹ ti wọn gbe e debẹ lo jade laye.
Awọn ajọ O’Ambulance la gbọ pe wọn kọkọ ṣetọju awọn ọmọde keekeeke naa, ki wọn too gbe wọn lọ sileewosan fun itọju.