Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Opin ọsẹ to kọja yii ni fidio kan jade sori ayelujara, ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan torukọ ẹ n jẹ Barakat Melojuẹkun Mayọwa, lo fẹsun kan Ọnarebu Abiọdun Abudu-Balogun, iyẹn Kọmiṣanna eto ayika nipinlẹ Ogun, pe ọkunrin naa fẹẹ fipa ba oun lo pọ, o si ti bẹrẹ si i tẹ oun lọmu koun too rọna sa jade nile rẹ to wa ni Ita-Otu, Waterside, nipinlẹ Ogun.
Akẹkọọ ni Barakat nileewe Girama Victory Model College, ipele aṣekagba lo wa. Alaye to ṣe ni pe ẹnikan lo ni koun waa ba kọmiṣanna yii ṣiṣẹ kọmputa, oun si lọ sile rẹ ni Ita-Otu, afi bo ṣe tilẹkun mọ oun to fi kọkọrọ pamọ, to n beere awọn ibeere ti ko lẹsẹ nilẹ lọwọ oun ko too di pe o fọwọ tẹ oun lọmu, to si tun n fọwọ pa oun lara.
Barakat sọ pe Ọnarebu yii bẹrẹ si i pogede, bẹẹ lo fẹẹ ti oun wọ inu baluwẹ rẹ, o si n gbiyanju lati gbe ọwọ le oun lori pẹlu.
Ọmọ naa sọ pe awọn ero to wa layiika ile Ọnarebu Balogun ni ko jẹ ko le fagidi mu oun mọlẹ fun ibasun, toun fi raaye jade. O ni ẹgbẹrun meji naira lo foun pe koun fi ṣowo ọkọ.
Ṣugbọn Kọmiṣanna yii ni ko sohun to jọ bẹẹ, ninu ọrọ ti Abiọdun Abudu-Balogun, ba AKEDE AGBAYE sọ lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, o ni irọ patapata lọmọbinrin yii n pa.
Kọmiṣanna yii sọ pe ibanilorukọ jẹ nidii oṣelu lawọn to wa nidii ọrọ naa n ṣe. O ni iṣẹ ni Barakat n fẹ lọdọ oun nileewe kọmputa toun da silẹ, oun to gbe e wa sile oun niyẹn, ẹgbọn rẹ kan to jẹ ọkan ninu awọn to n fẹ toun lo si mu un wa pẹlu.
O ni ki ẹnikẹni ma ṣe gba ọrọ yii gbọ, oun ti fa a le ọlọpaa atawọn lọọya lọwọ, wọn yoo wa idi otitọ jade laipẹ ti gbogbo eeyan yoo ri i.