Aderounmu Kazeem
Bo tilẹ jẹ pe wọn ti sin Ọgbẹni Tunde Thomas, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Tunde Gentle, lọgbọnjọ oṣu kejila ọdun 2020, sibẹ ariwo iku to pa ọkunrin naa lo gbode kan bayii, bẹẹ ni ọrọ ọhun paapaa ti ra ileefowopamọ FCMB lẹsẹ, ti awọn naa si ti n sare kiri bayii lati fọ ara wọn mọ.
Ohun ti wọn lo fa iku ojiji to pa Tunde Gentle ni iroyin agbako kan ti iyawo ẹ, Moyọ Thomas, to wa niluu oyinbo, iyẹn orilẹ-ede Amẹrika fi ranṣẹ si i wi pe ̀ọmọ meji ti oun bi labẹ orule ẹ, ko ma fọkan si i pe oun loun ni awọn ọmọ naa o, ọga oun nibiiṣẹ, Adam Nuru, ni baba wọn n ṣe.
Ibanujẹ nla lo dori agba kodo nigba ti Tunde Gentle gbọ ohun ti iyawo ẹ sọ yii, bẹẹ lawọn to sun mọ ọn daadaa sọ pe latigba ti obinrin yii ti fi iroyin buruku yii ranṣẹ si i ni nnkan ti daru fun ọkunrin naa, to si fẹẹ para ẹ pelu, ki o too pada waa ku nigba to to n mura lati gbagbe iṣẹlẹ naa ko le ba bẹrẹ aye tuntun.
Ohun ti a gbọ ni pe gbogbo asiko ti Moyọ fi wa labẹ orule Tunde, ti wọn jọ n ṣe tọkọ-taya, ni obinrin yii ati Ọga agba fun ileeṣẹ ifowopamọ FCMB, Adam Nuru, ti jọ n ba ara wọn sun, ati pe pupọ ninu awọn oṣiṣẹ banki yii paapaa ni wọn mọ, nitori wọn ko fi aṣiri ajọṣepọ ọhun bo rara.
Wọn ni pẹlu idunnu gan-an ni Tunde fi n tọju awọn ọmọ to ro pe oun loun ni wọn yii, ti ko si kọ lati na iyekiye fun itọju wọn.
Bi Tunde ati iyawo ẹ ṣe jọ n gbe ree, to si n ba baba olowo, iyẹn ọga iyawo ẹ, ti wọn sọ pe o lowo lọwọ bii ṣẹkẹrẹ tọju ọmọ.
Bẹẹ lawọn to sunmọ mọlẹbi Tunde daadaa sọ pe lasiko isinmi ọlide, bo ti ṣe n ko wọn lọ si Dubai, bẹẹ lo n gbe wọn lọ si London pẹlu owo ẹ, laimọ pe ọmọ ọlọmọ lawọn ọmọ naa n ṣe.
Yatọ si eyi, ileewe olowo nla lawọn ọmọ ọhun n lọ pẹlu, ti ọkunrin yii si n ro pe ti oun ba tọju awọn ọmọ oun yii, ko ni i si iṣoro fun oun lọjọ alẹ, nitori wọn yoo le ṣanjọ fun oun naa.
Ṣa o, a gbọ pe nibi ti wahala ti bẹrẹ wẹrẹ ni asiko ti akọbi ọmọ ọhun pe ọmọ ọdun mẹjọ, niṣe ni Moyọ ṣadeede kọwe fipo silẹ ni banki FCMB, to si gba Amẹrika lọ. Ohun ti wọn lo sọ fun ọkọ ẹ ni pe oun fẹẹ ki wọn lọ lo olude wọn lọhun-un ni.
Ṣugbọn nigba ti awọn ọmọleewe wọle, ti Moyọ ko ko awọn ọmọ pada, nibi ti wahala ti so niyẹn, ki oloju si too ṣẹ ẹ, iroyin agbọsọgbanu lo fi ranṣẹ si ọkọ ẹ.
Nibi ti Tunde ti n bi i kin ni idi ẹ ti ko fi ko awọn ọmọ pada si Naijiria, ki wọn waa wọle pada sẹnu ẹkọ wọn pẹlu awọn ara yooku, nibẹ ni Moyọ ti sọ fun ọkọ ẹ pe ko ma ni aye oun lara o, awọn ̀ọmọ naa ki i ṣe tiẹ, ko ye beere wọn mọ.
Nibi ti wahala ti de ba Tunde Thomas niyẹn o, ẹni ti wọn sọ pe oun naa ti figba kan jẹ oṣiṣẹ banki Oceanic tẹlẹ ri, ki ileefowopamọ naa too kogba wọle.
Awọn to sunmọ tọkọ-tiyawo yii sọ pe lara igbesẹ ti obinrin naa gbe ni bo ti ṣe n wa oriṣiriiṣi ọna ti ijọba ilẹ Amẹrika yoo fi fun un ni iwe igbeluu.
Wọn ni lara awọn ete to n lo ni irọ buruku to pa mọ Tunde pe niṣe lo n ṣe oun niṣekuṣe, to n fi iya nla jẹ oun. Ati pe iyẹn gan-an lo mu oun sa wa si Amẹrika, ki wọn dakun jọwọ fun oun ni iwe igbeluu.
Ọdun 2017 ni wọn sọ pe iṣẹlẹ buruku yii waye si Ọgbẹni Tunde Gentle, bẹẹ ni wọn sọ pe iroyin buruku to gbọ yii paapaa lo sọ ọ dẹni to ni arun rọpa-rọsẹ lojuẹsẹ.
Pẹlu itọju lọtun-un-losi ni wọn lo mu ara Tunde pada ya, bẹẹ lo ti n bọ sipo pada, ṣugbọn ni gbogbo igba to ba ti ranti ohun ti iyawo ẹ yii ṣe fun un, ẹkun ni wọn sọ pe ọkunrin yii maa n sun.
Lara igbesẹ ẹ lati tẹ siwaju pẹlu aye ẹ naa lo mu bẹrẹ si ni ṣe wọle-wọde pẹlu obinrin lọọya kan, ti ireti si ti wa wi pe wọn yoo fẹra sile.
Wọn ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kejila ọdun 2020 yii ni Tunde ti n mura lati lọọ yọju nile awọn amofin to fẹẹ fẹ niyawo yii, bẹẹ lo ti sọ fawọn mọlẹbi tiẹ paapaa, ti wọn si ti n reti ki ọjọ ko, ki awọn ba a lọ ṣeyawo tuntun.
Ṣugbọn lọjọ kẹẹdogun, oṣu kejila ọdun to kọja yii, nigba to ku ọjọ mọkanla pere ko lọọ dana ni Tunde subu lulẹ nile ẹ, to si ku lojuẹsẹ.
Awọn to sunmọ ọn sọ pe ninu iwadii ti wọn ṣe nipa oku ẹ lo ti foju han wi pe ironu lo pa a, wọn ni niṣe ni ọkan ẹ daṣẹ silẹ lojiji, ti iku si mu un lọ.
̀Ọjọru, Wẹsidee, iyẹn ọgbọnjọ, oṣu kejila ọdun 2020, ni wọn si in. Ṣugbọn Tunde lo ku o, sababi ohun to pa a, ati gbogbo bi ọrọ ọhun ṣe jẹ gan-an lo ti wa nita bayii, ti awọn eeyan si n sọ pe ọga banki to n ba iyawo oniyawo sun, tiyẹn fi bimọ meji labẹ ọkọ ẹ, ko gbọdọ lọ laijiya.
Ni kete ti iroyin agbọsọgbanu yii ti bọ sigboro lawọn eeyan ti n kọ oriṣiriiṣi nnkan sori ikanni ayelujara wọn, bẹẹ ni wọn n ba awọn eeyan sọrọ wi pe ti banki naa ko ba yọ Adam Nuru niṣẹ, lojuẹsẹ ni ki awọn eeyan lọọ ti akaunti wọn pa, ki wọn ma kowo wọn si ileepamọ naa mọ.
Eyi ni wọn lo mu ileefowopamọ ọhun tete bọ sita lati sọrọ wi pe iwadii yoo waye, awọn si ti ṣetan lati ṣe ohun to tọ. Ni bayii, ileefowopamọ FCMB naa ti bọ si gbangba bayii lati ṣalaye igbesẹ wọn lori ọrọ naa.
Banki naa ni awọn ti gbọ ọrọ ọhun, paapaa bi awọn eniyan ti ṣe n gbe e kiri lori oriṣiiriṣi ẹrọ ayelujara. Wọn ni bo tilẹ jẹ ọrọ ọhun ni i ṣe pẹlu oṣiṣẹ banki ọhun, sibẹ iwadii to peye yoo waye lati tuṣu desalẹ ikoko lori ohun to ṣẹlẹ gan-an.
Siwaju si i, ileefowopamọ yii ti sọ pe ninu iwadii ọhun lawọn yoo ti wo o boya ọga ti wọn fẹsun kan yii lu ofin ileeṣẹ naa, ati pe iwadii ọhun ki i ṣe ohun tawọn yoo fi falẹ rara.
Bakan naa ni wọn ti rọ awọn eeyan lati ṣe ọpọ suuru bi iwadii ọhun ba ṣe n lọ, ki wọn si lo iwa ọmọluabi lati fi bọwọ fun awọn mọlebi tọrọ ọhun kan gbọngbọn.