Aderounmu Kazeem
Bi iku ojiji to pa gbajumo oṣere tiata nni, Fọlakẹ Arẹmu, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Oriṣabunmi, ṣi ṣe n ya awọn eeyan lẹnu, awọn ẹbi ẹ ti sọ pe aisan ranpẹ lo ṣe e, ati pe ẹni ọgọta ọdun ni, ko too jade laye.
Pupọ ninu awọn oṣere ni wọn bara jẹ nigba ti kaluku n ṣi foonu wọn wo lowuurọ kutu oni, Ọjọruu, Wẹsidee, ti wọn si n ba ikede iku ẹ pade lori ikanni ayelujara wọn. Lori ayelujara yii naa ni wọn ti n bara jẹ, bẹẹ lo fi han wi pe iku obinrin naa dun wọn gidigidi.
Ariwo to gba igboro kan naa ni pe obinrin oṣere tiata to ti figba kan jẹ iyawo nile Oloogbe Jimọh Aliu, iyẹn Baba Aworo, ti ku. Bẹẹ lọpọ wọn n sọ pe awọn naa ko ti i mọ ohun to ṣokunfa iku obinrin naa gan-an nitori awọn ṣi jọ pade ni lokeṣan ere kan niluu Ibadan ni nnkan bii ọjọ meloo kan sẹyin.
Mọlẹbi ni Oriṣabunmi to jade laye yii pẹlu iyawo gbajumọ sọrọsọrọ to fi ilu Ilọrin ṣe ibugbe, iyẹn Dan Kazeem. Ẹgbọn iyawo ẹ gan-an ni Oriṣabunmi jẹ, ọkunrin sọrọsọrọ yii si ti ba ALAROYE sọrọ.
Alaye to ṣe ni pe aisan ọjọ mẹta pere lo ṣe Oriṣabunmi. Oun naa lo fidi ẹ mulẹ wi pe ẹni ọgọta ọdun, bẹẹ ilu kan ti wọn n pe ni Ọla, nijọba ibilẹ Isin ni Oriṣabunmi ti wa. O fi kun un pe wọn ti gbe oku Oriṣabunmi pamọ titi di igba ti ẹbi yoo sọ igbesẹ ti yoo kan lori bi wọn yoo ti ṣe sin in.
Ọkunrin onitiata kan, Quadri ọmọ Oyiboyi, ti oun naa ba wa sọrọ salaye pe, “Ko sẹni kan bayii to lero wi pe iru iṣẹlẹ buruku yii le ṣẹlẹ si wọn. Laipẹ yii la jọ wa ni lokeṣan kan niluu Ibadan, ọmọ wọn gan-an ni mo ṣe ninu ere naa, ko si si apẹẹrẹ aarẹ tabi aisan kankan lara wọn. Nigba ti mo gbọ pe wọn ku, ti mo beere lọwọ awọn eeyan ohun to fa a, alaye ti wọn ṣe fun mi ni pe o rẹ wọn diẹ ni ọjọ kọkanlelọgbọn osu kejila to pari ọdun 2020, nigba to si di ọjọ ọdun gan-an ni dokita sọ pe ki wọn maa lọ sile, afi bi iroyin iku wọn ṣe gba igboro kan lowurọ kutu oni. Ki Ọlọrun foriji wọn.
Ninu ọrọ Ọmọoba Jide Kosọkọ, o ṣapejuwe obinrin naa gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ to kopa manigbagbe ta a ba n sọ nipa fiimu Yoruba.
Ọgbẹni Abọlaji Amusan, ẹni ti ṣe Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere tiata Yoruba, naa ti fidi ẹ mulẹ wi pe aṣalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ana yii, lobinrin naa jade laye.
Lara awọn oṣere tiata tawọn naa tun ṣedaro gbajumọ oṣere yii ni Toyọsi Adesanya, Ayọka Ọlọgede, Kunle Afod, Ọmọtunde Ogundimu, atawọn mi-in lori ikanni ayelujara wọn.
Ọkan pataki ninu awọn oṣere to kopa ninu ere ọlọsẹ mẹtala ti Oloogbe Jimọh Aliu, ṣe to pe akọle ẹ ni Arelu ni Oriṣabunmi, n ṣe. Ere naa lo fun un lokiki, paapaa ni nnkan bii ọgbọn ọdun o le diẹ sẹyin.
Ki Ọlọrun foriji i, ko ṣe iku nisinimi fun un.