Ọlawale Ajao, Ibadan
Leyin ti awọn ọmọ iṣọta ti kọkọ ja ọdẹ kan lole ninu iṣẹlẹ akọkọ, o kere tan, eeyan mẹrin ni wọn yinbọn mọ, ti ọpọ dukia si bajẹ ninu ija igboro to waye laarin awọn tọọgi nigboro Ibadan lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee).
Bi iku ni yóò gbẹyin ọrọ awọn ti wọn yinbọn fún ọhun nileewosan ibilẹ ti wọn ti n gba itọju, bi iye ni, ọwọ Ọlọun nikan lo wa bayii.
Ija igboro ọhun, eyi ti a ko tii mọ ohun to sokunfa rẹ lo waye lopoopona Onidẹ-ọrẹ lagbegbe Ọranyan nIbadan, nnkan bíi aago mẹjọ alẹ ọjọ Aiku, Sannde to kọja lo si ti bẹrẹ.
Gẹgẹ bi aarẹ ẹgbẹ awọn ọdẹ ibilẹ taa mọ sí Soludẹrọ Hunters Association nilẹ yii, Ọba Wahab Ajijọla-Anabi, ṣe fidi ẹ mulẹ, “ẹgbẹ wa to lọọ koju awọn ọdọ yẹn ti wọn to ọgọrun-un kan (100) niye ti wọn dojú ìjà kọra wọn pẹlu ibọn atawọn ohun ìjà oloro mi-in lati pana ija yẹn, ṣugbọn ija yẹn gbona kọja bẹẹ, ko sí rọrun lati pari bọrọ.
“Ṣugbọn nigbẹyin, Ọlọun ran wa lọwọ lati pana ẹ nigba ti awọn Amọtẹkun waa dara pọ mọ wa nibẹ lati kun wa lọwọ.
“Ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Sannde ti wahala yen bẹrẹ lawa ẹgbẹ ọdẹ Soludẹrọ ti kọkọ tu wọn ka ki wọn tóo tun lọọ kora wọn jọ pada ko tóo waa di ohun ti apa ko fẹẹ tete ka mọ lanaa. Ohun to si fa a ni pe ọdọmọdé lawọn to n fa wahala wọnyi. Bakan naa, aarin igboro ni wọn ti n ja, eyi ko si jẹ ko ṣee ṣe fun wa lati le yinbọn”.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, nṣe lawọn ọmọ iṣọta kan lo anfaani iṣẹlẹ yii lati jalẹkun awọn ṣọọbu agbegbe naa ti wọn sì n ji awọn ẹru to wa nibẹ ko.
Ninu iṣẹlẹ min-in to fara pẹ eyi, ṣugbọn to ti waye ni nnkan bíi ọjọ mẹta ṣaaju, la ti gbọ pe awọn janduku kan lọọ da ọdun oriṣa Ògún ti awọn kan nse laduugbo Bẹyẹrunka n’Ibadan ti wọn si já foonu gba lọwọ ọkan ninu awọn ọdẹ to n ṣọdun Ogun naa.
Lẹyin naa ni wọn bẹrẹ si i jalẹkun awọn ṣọọbu to wa nibẹ ti awọn naa n ji awọn ọja ọlọja ko.
Ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin Naira (₦800,000) la gbọ pe wọn ji ko ni ṣọọbu ọkunrin kan to n jẹ Badmus Yusuf. Ọpọlọpọ ẹru ti owo wọn kò mọ ni miliọnu Naira kekere lawọn ontaja agbegbe náà sì padanu sọwọ awọn janduku naa.