Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin ti eeyan mẹta ti ku ni ìfọnná-fọnṣu, ọkẹ aimọye eeyan ti ibọn tun ba ni wọn n japoro lọwọ bayii latari laasigbo to waye laarin awọn ọmọ igboro niluu Tápà, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ.
Ni nnkan bii aago mẹwaa kọja alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, niṣẹlẹ ọhun waye, nibi ti awọn ikọ eleto aabo ilẹ Yoruba, Amọtẹkun, ẹka ipinlẹ Ọyọ, ti n gbiyanju lati da ajọdun adugbo (kańnífà) ti wọn n ṣe nigboro ilu naa duro.
A oo ranti pe latọdun to kọja (2020) nijọba ipinlẹ Ọyọ ti fofin de ayẹyẹ ààjìn tabi arijàṣemọ́jú lati dena itankalẹ arun aṣekupani Kòrónà to n ja ran-in-ran-in kaakiri agbaye lọwọlọwọ bayii.
Olugbe ilu Tapa kan, ẹni ti ko darukọ ẹ f’ALAROYE ṣalaye fakọroyin wa pe “Awọn kan lo n ṣe kánífà, ṣugbọn ariya to n dun mọ wọn ko jẹ ki wọn tete pari ẹ laago mẹwaa alẹ to yẹ ki wọn pari ẹ. Iyẹn lawọn Amọtẹkun ṣe lọọ ba wọn lati jẹ ki wọn pa ofin ijọba mọ.
Awọn to jẹ abẹnugan ta a le pe ni awọn adari awọn to n ṣe kanifa yii ko ba awọn Amọtẹkun jiyan nigba ti wọn kọkọ lọọ ba wọn, wọn gba lati dawọ orin ati ijo duro. Ṣugbọn ariya yii ti wọ awọn kan lara ninu wọn, wọn si kọ lati fopin si kanifa yẹn.
Nigba ti awọn Amọtẹkun tun pada lọ lẹẹkeji, niṣe lawọn ti ko fẹ ki ariya pari sibẹ bẹrẹ si i ba wọn fa wahala, awọn kan paapaa bẹrẹ si i lẹ̀ko mọ wọn. Nibẹ lawọn Amọtẹkun naa ti yinbọn, ti eeyan mẹta si ku nibẹ loju ẹsẹ.
Ọpọ eeyan nibọn tun ba to jẹ pe wọn n fa ọta ibọn yọ lara wọn ni. Ṣugbọn ki i ṣe gbogbo awọn ti ibọn ba yẹn naa ni wọn jẹ ara awọn to n ṣe kanifa. Awọn kan wa to jẹ ile wọn ni wọn wa ti ọta ibọn fi lọọ ba wọn.”
Tẹ o ba gbagbe, kanifa ti awọn ọdọ adugbo kan n ṣe niluu Ogbomọṣọ naa lawọn agbofinro n gbiyanju lati fopin si, ti ọkan ninu awọn ikọ Amọtẹkun fi yinbọn mọ ọlọpaa lọjọ keji, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii, bo tilẹ jẹ pe agbofinro ọhun ko ku.
Ajagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju ti i ṣe oludari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ṣugbọn o ni eeyan meji pere lo padanu ẹmi wọn sinu iṣẹlẹ naa.