Ẹ sọ fun Buhari ko sọrọ soke

Ẹ sọ fun Buhari ko sọrọ soke

Eyi to buru ju ninu ohun to n ba Aarẹ Muhammadu Buhari ja, to si n doju ijọba to n ṣe ru, ni pe ọpọlọpọ awọn ọrọ to maa n sọ jade lẹnu ki i ṣe ironu oun funra rẹ, awọn mi-in ni wọn maa n ronu fun un. Awọn ti wọn si n ronu fun un yii ko ni iṣẹ meji ti wọn n ṣe ju ki wọn sọ ọrọ didun lati fi tan araalu, ki wọn si kọ awọn ọrọ wọnyi sinu iwe, ki wọn ni ki Aarẹ ka a si eti gbogbo ọmọ Naijiria. Eyi lo ṣe jẹ lojoojumọ aye yii, bi Aarẹ Buhari yoo ba ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ, ohun kan naa ni yoo maa ti ẹnu rẹ jade. Bo ba ṣe pe awọn eeyan lo ku bẹẹrẹ lọ nibi kan, yoo ni ọrọ naa ba oun ninu jẹ gan-an, ati pe oun yoo wa nnkan ṣe si eto aabo Naijiria laipẹ rara. Bi wọn ba sọrọ eto ọrọ-aje pe dọla ẹyọ kan ti di ẹẹdẹgbẹta naira, Buhari yoo ka akọsilẹ awọn ọmọ rẹ jade pe awọn ti n ṣiṣẹ lori ẹ, dọla yoo ja walẹ laipẹ yii. Bo si jẹ awọn Boko Haram ni, yoo ni ọga awọn olori ologun awọn ti n ṣe bẹbẹ, wọn si maa le awọn Boko Haram lugbo laipẹ jọjọ. Ọrọ kan yii naa ni lojoojumọ, ọrọ kan yii naa ni ni gbogbo igba, ọrọ rẹ ki i yatọ nijọ kan.

Bo si jẹ ọrọ kan ti ko mọ ojutuu si rara ni, yoo ni awọn ẹgbẹ oṣelu PDP lo ko ba awọn, awọn ni wọn fẹẹ da oju ijọba oun de. Ko si ohun meji to fa gbogbo ọrọ ti ẹ n gbọ yii ju pe ki i ṣe Buhari funra ẹ lo n sọ awọn ọrọ yii, awọn kan ni wọn n kọ ọ fun un, ohun ti wọn ba si kọ naa ni yoo ka, koda, ko jẹ ko mọ kinni kan nipa ohun ti wọn kọ fun un. Bo ba ṣe pe Buhari funra ẹ lo maa n kọ awọn ọrọ to maa n ka jade nigba yoowu to ba ni oun fẹẹ ba gbogbo ọmọ Naijiria sọrọ ni, ọrọ wa ko le ri bayii. Ohun to n ṣẹlẹ si wa ni pe Buhari kọ lo n ba wa sọrọ, awọn eeyan rẹ ti wọn n ba a ṣiṣẹ, ni wọn n kọ oriṣiiriṣii ọrọ fun un ni. Ẹ wo ohun to ka jade lọjọ ọdun tuntun yii, ko si iyatọ ninu ọrọ naa ati eyi to sọ lọdun to kọja, tabi ọdun to lọ lọhun-un, tabi nigbakigba to ba ti ni oun fẹẹ ba gbogbo ilu sọrọ. Nitori pe oun kọ lo n kọ ọrọ yii, ko jẹ ko mọ pe ọrọ rẹ ti su awọn ọmọ Naijiria, wọn ki i fẹẹ duro lati gbọ ohun yoowu to ba ni oun fẹẹ sọ. Idi ni pe ki i si ọrọ gidi kan ti wọn le tẹle ninu awọn ọrọ rẹ, bẹẹ ni ko si eyi to fi wọn lọkan balẹ pe aburu to n ṣẹlẹ ko ni i ṣẹlẹ mọ, tabi pe wọn yoo ri ojutuu si iṣoro gbogbo to n koju wa. Ohun to n ṣẹlẹ ko yipada, ọrọ ti Buhari n sọ ko yipada, bẹẹ ni ohun to n ṣe Naijiria n buru si i lojoojumọ. Ayipada gbọdọ ba iru nnkan bayii o! Ki Buhari ṣejọba, ko si jẹ ki awọn ọmọ Naijiria mọ pe oun loun n ṣejọba le wa lori. Ọrọ to ba fẹẹ sọ, ko beere awọn ohun ti ko ba ye e nipa ẹ, ko si ronu lori ohun ti oun fẹẹ ṣe lẹsẹkẹsẹ lati mu iṣoro naa kuro ko too di pe o ba ilu sọrọ nipa rẹ, ki i ṣe ko jẹ awọn kan ni yoo maa kọ ikọkukọ fun un, ti oun naa yoo si maa ka ikakuka, ti yoo maa sọ awọn ohun to ba ṣaa ti wa sẹnu rẹ ṣaa. A ki i wi sibẹ ka ku sibẹ, ki i ṣe bi wọn ti n ṣejọba niyi, bi Buhari si ti n ṣejọba Naijiria yii ko daa. Bo ba ṣe ara rẹ ni ko ya loootọ, ko si ohun to buru to ba mi sẹyin, ki igbakeji rẹ mojuto ijọba naa, nigba to jẹ wọn jọ dibo fun awọn mejeeji ni. Ṣugbọn lati jokoo kan maa fiya jẹ gbogbo ilu yii ko daa, ko daa rara tiẹ ni. Bi wọn si ti n kọ ikọkukọ yii naa ko daa bi wọn ko ba fẹ ki Ọlọrun mu awọn, ki wọn jawọ ninu palapala ti wọn n ṣe. Ijọba Naijiria ko lori, ko nidii, nitori olori ijọba ko mọ ohun to fẹẹ ṣe tabi ohun to n ṣe. Ọrọ ti Buhari ka lọjọ ọdun tuntun yii, ko si nnkan kan nibẹ, awọn alagabagebe ati alabosi kan lo kọ kinni naa, ti Buhari paapaa ka a. Ẹ kilọ fun wọn ki wọn ma ṣe bẹẹ mọ, ohun ti ko daa ko daa!

Lọjọ wo ni pipa ti wọn n paayan kiri yii yoo dinku

Ipade kan waye lọsẹ to kọja yii, nibi ti ọpọ awọn agbaagba ilu ti pe jọ lori ọrọ aabo orilẹ-ede yii, ati pipa ti awọn janduku n paayan kiri. Lọjọ wo ni pipa ti wọn n paayan kiri yii yoo dinku, Boko Haram, Fulani onimaaluu n fojoojumọ pa awọn eeyan kiri. Ohun kan ti awọn agba ti wọn wa nibẹ fẹnu ko le lori ni pe bi Aarẹ Buhari ba kọ ti ko yọ awọn olori ologun ilẹ wa yii kuro lẹnu iṣẹ wọn, nigba ti gbogbo ilu ti mọ bayii pe wọn ko kun oju oṣuwọn mọ, iṣẹ naa ti tobi ju wọn lọ, ki awọn olori ologun naa fi ipo naa silẹ funra wọn, ki wọn kọwe fipo silẹ nigba ti kinni naa ṣi niyi, ko ma di pe wọn yoo tẹ patapata, ti iṣẹ ti wọn si ti ṣe daadaa tẹlẹ yoo pada waa bajẹ. Buhari nikan lo le sọ idi to fi fi awọn ti wọn n ṣe olori awọn jagunjagun yii silẹ nipo wọn, nigba ti wọn fi wọn jẹ oye awodi, ti wọn ko le gbe adiẹ. Ohun ti awọn kan si ṣe n tẹnu mọ ọn ree pe Buhari ko raaye ijọba Naijiria yii, tabi ko jẹ ko mọ ohun to n lọ loootọ rara. Bo ba mọ ohun to lọ ni, ọpọ ohun to n ṣẹlẹ lasiko yii, awọn ti ko to bẹẹ ti ṣẹlẹ lawọn igba mi-in to jẹ lẹsẹkẹsẹ ni olori ijọba bẹẹ yoo yọ awọn olori ologun danu, ti yoo si fi ẹlomi-in si i. Ki i ṣe pe o koriira wọn, tabi pe o kan wọn labuku, ṣugbọn ki wọn le fi awọn mi-in ti wọn yoo ṣe iṣẹ naa bii iṣẹ sibẹ ni, nigba to jẹ ọgbọn ọdun yii, were igba mi-in ni.

 

Ọgbọn ti eeyan kan gbọn latijọ le ma ṣiṣẹ lasiko yii mọ, ohun to si dara ju ni lati wa ọgbọn tuntun. Ṣugbọn Buhari taku, gbogbo bi wọn ti n pariwo to yii, Buhari ko dahun, ko ri ohun to buru ninu iṣẹ ti awọn eeyan yii n ṣe, bo tilẹ jẹ gbogbo awọn agbaagba ilu, awọn ọlọgbọn ilu ati awọn ọjọgbọn nla nla ni wọn n pariwo pe ti ọrọ ba da bayii, ẹni ti olori ijọba yoo kọkọ paarọ ni awọn olori ologun wọn. Ti Naijiria nikan lo yatọ, nitori gbogbo aye lo n pariwo pe ki wọn le awọn araabi yii danu, Buhari kọ, o loun ko ṣe o. Bẹẹ awọn ti wọn n sọrọ yii, ki i ṣe pe wọn koriira awọn ti wọn n sọrọ wọn, nitori pe awọn olori ologun yii ko ṣe ohun ti wọn tori ẹ fi wọn joye ni. Iṣẹ ti wọn n ṣe ko yọ, awọn araalu si mọ pe wọn ko ṣiṣẹ lati mu awọn janduku ti wọn n dalu ru, awọn Boko Haram ko yee pa awọn eeyan, bẹẹ ni ibẹru ati ijaya wa fun ẹni gbogbo. Ki waa lawọn olori ologun wọnyi n ṣe. Ohun tawọn eeyan ṣe n pariwo ki wọn yọ wọn ree, nitori ko si anfaani kankan lara wọn mọ. Ko waa yẹ kijọba Buhari kọyin si gbogbo ohun ti araalu n wi yii, nitori nnkan naa ko daa ni. Ki Buhari yi awọn olori ologun yii pada, ka le ri ayipada tuntun ninu iṣẹ ologun, ki wahala awọn Boko Haram ati janduku le dinku, ki aye awọn ọmọ Naijiria le tun pada daa!

Ohun ti wọn n tori ẹ da Ọmọyẹle Ṣoworẹ laamu niyẹn o

Ni ọjọ ti ọdun tuntun ku ọla ni wọn mu Ọmọyẹle Ṣoworẹ, ọkan ninu awọn ajijagbara ti wọn n pariwo awọn aidaa ti ijọba Buhari n ṣe. Ṣoworẹ ati awọn eeyan rẹ n ṣeto iwọde, wọn ni ni ọjọ kin-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, awọn yoo ṣeto iwọde nla kan lati fi ta ijọba Buhari ji, ki awọn le jẹ ki wọn mọ pe iya n jẹ ọmọ Naijiria, ohun to n ṣẹlẹ si wọn labẹ ijọba yii ko dara. Bi wọn ti n mura lori bi wọn ti ṣe fẹẹ ṣẹwọde ọhun, nibẹ lawọn ọlọpaa ati DSS ti ya bo wọn ni Abuja, wọn si ko gbogbo wọn. Ki i ṣe pe wọn ti i ṣewọde, ki i ṣe pe wọn ti i jade nibi kan, wọn kan n sọ bi wọn yoo ṣe ṣeto naa lọwọ ni. N ni wọn ba ko wọn o, wọn si ti wọn mọle lati igba naa. Ohun ti wọn tori ẹ mu Ṣoworẹ ati awọn eeyan rẹ niyi o, nitori pe wọn n mura lati ṣe iwọde. Bo ba ṣe awọn opurọ kan ni wọn de ni, awọn oloṣẹlu ti wọn sanwo fun, ti wọn ba bẹrẹ iwọde, ti wọn n jo kiri ilu Abuja, ti wọn ni ko si iru ijọba bii ti Buhari yii, bo tilẹ jẹ pe ẹtan ni, awọn ọlọpaa ati awọn DSS yoo gbe oju wọn si ẹgbẹ kan, tabi ki wọn tẹle wọn ki awọn naa maa ba wọn jo kiri. Ẹnikẹni to ba ti fẹẹ sọ aṣiri to wa ninu raurau to wa ninu ijọba yii, o ti dọta ọlọpaa, o ti dọta ijọba, koda, o ti dọta awọn ṣọja. Kaka ki awọn ti wọn n ṣejọba mọ pe ẹtan lawọn to n sọ pe ijọba wọn dara n ṣe fun wọn, ki wọn si mọ pe awọn ti wọn n pariwo le wọn lori yii fẹ rere wọn ni, odi ni wọn yoo maa ronu si, ti wọn yoo si maa ṣe ohun gbogbo lodi lodi. Ko si ohun to yẹ ki wọn tori ẹ mu Ṣoworẹ rara o. Ohun ti wọn n sọ ni pe ijọba yii ko daa, loootọ si ni, ijọba naa ko daa, ko si ani-ani kan nibẹ.

Ko si ohun to buru ninu ohun ti awọn Ṣoworẹ fẹẹ ṣe, ọkan pataki ninu ohun to n gbe eto ijọba oṣelu tiwa-n-tiwa duro ni aaye fun gbogbo ẹni to ba ni ẹhonu lati fi ẹhonu ẹ han, gbogbo ẹni to ba fẹẹ ṣe iwọde, ki wọn lanfaani lati ṣe iwọde, ki gbogbo eeyan si sọ ohun to ba n bi wọn ninu nipa ijọba to n paṣẹ le wọn lori. Ko si ijọba dẹmokiresi kan to dara ti ko si awọn alatako nibẹ, nitori iṣẹ alatako ni lati fi atako wọn ta ijọba ji, ki wọn fi tọ ijọba sọna, ki ijọba naa le mọ eto to yẹ ki wọn ṣe fun awọn araalu gbogbo. Ijọba to ba n pa awọn alatako lẹnu mọ, to n sọ pe ki awọn araalu ma ṣe iwọde, ijọba kan-an-pa niyẹn, ijọba onipakaleke, ijọba ti ko fẹ ki araalu sọrọ, koda ko jẹ ohun ti wọn n ṣe ko dara. Iru ijọba bẹẹ a maa pada waa da ogun silẹ niluu, nitori bi wọn ba mu araalu lẹru pẹ titi, bo ba di ọjọ kan, awọn araalu yoo yiju pada si wọn. Awọn Ṣoworẹ yii ko gbebọn, wọn ko paayan, ki waa ni awọn ṣọja  atọlọpaa n le wọn kiri si. Awọn janduku ti wọn n gbebọn, awọn Boko Haram ti awọn n ji awọn ọmọleewe gbe, awọn Fulani onimaaluu ti wọn n pa awọn eeyan sinu oko, awọn yii wa nibi kan ti wọn n ṣe bo ti wu wọn, ti apa awọn ṣọja wa ko ka wọn, bi ọlọpaa si gburoo wọn nibi kan, wọn yoo sa lọ ni. Ki lo waa de to jẹ awọn araalu ti ko nibọn, ti ko si ni ohun ija, ti wọn ko si ṣe ẹnikẹni leṣe lawọn ọlọpaa ati ṣọja wa n le kiri. Eleyii ko daa, ijẹni-nipa ni, ifiyajẹni ni, Ọlọrun paapaa ko si fẹ ẹ.

Ta ni yoo san gbese yii?

Lojoojumọ ni ijọba yii n yawo, lojoojumọ ni wọn n raja lawin, lojoojumọ ni wọn n jẹ gbese kun gbese si i. Ibeere akọkọ ti eeyan yoo beere ni pe ta ni yoo san gbese yii o. Bi nnkan ti wa, ko si kinni kan ti iijọba yii n ṣe bayii mọ ti ki i ṣe pe gbese ni wọn fi n ṣe e. Lọdun to kọja yii, laarin oṣu mẹṣan-an pere, ninu tiriliọnu mẹwaa owo ti ijọba Naijiria na lọdun naa, ijọba Buhari ti na tiriliọnu meji lati fi san ele to wa lori gbese ti wọn jẹ. Iyẹn ni pe ọrọ ti doju ẹ debii pe ti Naijiria ba fẹẹ na naira mẹwaa lọdun kan, naira meji ni wọn yoo fi san ele lori gbese, bẹẹ ni eyi ko ti i mọ owo ti wọn jẹ gbese ẹ gan-an. Ele nikan ni wọn n san, sibẹ, wọn ko yee yawo si i.

Bi ijọba kan ba n ṣe bayii yawo, ti wọn n fi gbogbo owo ti wọn ba ri san gbese, wọn yoo sọ orile-ede naa di ẹdun arinlẹ pata ni. Ka si sọ tootọ, ijọba yii ti sọ Naijiria di ẹdun-arinlẹ, wọn ti sọ wọn di onigbese loju aye gbogbo. Boya ni orilẹ-ede kan wa bayii ti Naijiria ko ti yawo, bẹẹ ni wọn o si ti i sinmi, wọn n yawo ọhun lọ ṣaa ni. Nibi ti wọn ti waa yawo yii de yii, ele ori gbese ti wọn n san ti n ko pupọ ninu owo ti ijọba ni lati na lọdun kan lọ. To ba jẹ wọn duro ni, ti wọn ko ba ya owo mọ, tabi to ba jẹ awọn owo ti wọn n ya yii, iṣẹ ni wọn fi n da silẹ ti awọn araalu n ri iṣẹ naa ṣe, ti wọn si n pa owo lori rẹ, gbese naa ko le le to bayii. Gbogbo awọn owo ti wọn n ya wọnyi, awọn ohun ti ko ṣee gbọ seti ni wọn fi pupọ ṣe ninu wọn. Bi wọn ba si ti jẹ gbese nla bẹẹ tan, ti wọn ṣe owo naa mọkumọku, awọn ọmọ Naijiria yoo bẹrẹ si i san ele lori gbese ti wọn ko mọ igba ti wọn jẹ, ti wọn ko si mọ bi wọn ti ṣe owo naa gan-an. Ijọba yii ti yawo rẹpẹtẹ lọwọ awọn ara Ṣaina, wọn ya lọdọ Amẹrika, wọn ya ni Britain, wọn yaa ni Yuroopu, wọn ya lọwọ awọn ara India, koda, wọn ti yawo wọ awọn orilẹ-ede Afrika, bi a si ti n wi yii, wọn tun n wa ibi ti wọn yoo ti yawo mi-in ni. Ijọba Naijiria gbọdọ ṣisẹ ju ki wọn kan maa wa ibi ti wọn yoo ti yawo kiri lọ, bẹẹ nijọba Naijiria gbọdọ jẹ ki awọn ọmọ orileede yii mọ bi wọn ti n nawo ti wọn ba ya, ko dara lati maa ti ọrun ilu bọ gbese nigba ti araalu ko ba mọ ohun ti wọn fowo ti wọn ya ṣe. O ti doju ẹ bayii o. Owo ti ijọba n ya yii ti pọ ju, wọn ti ya owo naa debii pe apa ko fẹẹ ka a lati san mọ. Ko tilẹ sẹni to sọro ja gbese ti wọn jẹ yii rara, ele ori ẹ nikan ni wọn n san. Ta lo waa fẹẹ san gbese yii? Ṣe ijọba Buhari fẹẹ ta Naijiria fawọn oyinbo ni? Tabi kin ni yoo ṣẹlẹ ti wọn ba jẹ gbese ti wọn ko rowo naa san! Bẹẹ ki i ṣe epe lo n ja wa ni Naijiria yii, abi awọn olori ijọba wa lo kuku nika ninu to bayii, tabi loootọ loootọ ni laakaye wọn ko gbe iṣẹ ijọba ni. Eleyii ga o, afi ka bẹ Ọba Eledumare, ko ko gba wa lọwọ ijọba Buhari o.

Leave a Reply