Wahala ọna Eko s’Ibadan, nibo ni Faṣọla wa o
Awọn kinni kan wa ti wọn fi n mọ awọn orilẹ-ede to dara ju lagbaaye, lara ẹ ni iye ọdun ti eeyan le lo ni iru orilẹ-ede bẹẹ ki wọn too ku, iyẹn iye ọdun ti eeyan yoo lo laye, ti yoo ku, ti awọn eeyan ko ni i sọ pe tọhun ṣanku. Ninu awọn orile-ede to lọ silẹ ju nidii eyi, ọkan ni Naijiria tiwa. Ipo keji ni Naijiria wa laye ninu awọn orilẹ-ede ti ọjọ-ori awọn eeyan wọn ki i to nnkan, nitori bi eeyan ba ku ni ọmọ ọdun mẹrinlelaaadọta, tohun ko ṣanku ni Naijiria gẹgẹ bi awọn onimọ agbaye ti wi. Bẹẹ ni Japan, eeyan yoo pe ọmọ ọdun marundinlaaadọrun-un (85) ko too ku, ọdun mọkanlelọgorin (81) ni ti United Kingdom, ọdun mọkandinlọgọrin ni ti Amẹrika, koda, ọdun metalelaaadọrin (73) ni ti Algeria, ọkan ninu awọn orilẹ-ede Afrika. Ṣugbọn ti Naijiria yii ko daa, ọdun mẹrinlelaaadọta! Ko si si ohun to n fa iru iku bayii ju wahala. Wahala kookoo jan-an jan-an, wahala ọna ti ko dara, wahala ileewosan ti ko si, ati oriṣiiriṣii awọn nnkan keekeeke ti awọn orilẹ-ede mi-in ko ka si nnkan, ṣugbọn to jẹ babara ni wọn lọdọ tiwa. Ọkan ninu ẹ ni oju ọna to dara.
Ẹyin naa ẹ fi oju inu wo iye ọdun ti ijọba Naijiria ti n ṣe ọna marosẹ Eko si Ibadan, ti wọn ṣe e titi, ti wọn ko pari ẹ. Bẹẹ, lojoojumọ leeyan n ku, lojoojumọ lẹmi n ṣofo, lojoojumọ loju ona naa n da ẹmi awọn eeyan legbodo. Tabi ni orile-ede wo ni wọn ti n fi ọdun mẹwaa ṣe ọna kan ṣoṣo bii ti Naijiria yii, to si jẹ ọdọọdun ni ọna naa yoo maa lewo si i, ti awọn ti wọn si n ṣe titi naa ro pe awọn lawọn n ṣe wa loore, ki i ṣe awa la ṣe wọn loore ti a gbe iṣẹ fun wọn. Bi mọto ko ba takiti, tanka yoo gbina; bi tanka ko si gbina, awọn ti wọn n ṣe titi yii le gbagbe mọto janwee soju ọna, ti wọn yoo si fi i silẹ nibẹ, ti wọn yoo ba tiwọn lọ. Ni wahala yoo ba de. Eyi to ṣẹlẹ ni ọjọ ọdun yii buru. Lati ọdun ku ọla ni mọto kan ti bajẹ soju ọna yii, wọn ko si gbe e titi ti fi di wahala nla titi wọ inu ọdun tuntun. Awọn mi-in sun soju ọna marosẹ yii ni, awọn mi-in pada si ọọfiisi lati lọọ sun, awọn mi-in lọọ sunle ọrẹ mọju, bẹẹ ni awọn miiran padanu ọpọ iṣẹ aje ti wọn n ṣe soju ọna yii, nitori ti wọn ko ri ọna de ibi ti wọn iba ti ri ti aje ṣe. Ki lo de ti nnkan tiwa kuku ri bayii ni Naijiria! Ki lo de ti nnkan tiwa maa n ṣe bayii bajẹ! Ṣe awa nikan la wa lorilẹ aye yii ni, abi o ṣe jẹ nnkan tiwa ni ki i nilọsiwaju kankan, ti awọn orilẹ-ede bii Ghana, Togo, Bẹnnẹ nitosi nibi yoo si maa ta wa yọ ninu ohun gbogbo. Babatunde Faṣọla tiwa ni minisita eto iṣẹ ode, sibẹ, ko ri iṣẹ oju ọna naa ṣe, afi eebo ṣaa, afi laulau ti ko debi kan bọ, ka soro loni-in, ko dọla ka ma ba a bẹẹ mọ, ka ṣaa maa wa nnkan wi fawọn araalu ṣaa, ọrọ naa yaayan lẹnu gan-an. Bẹẹ nnkan n bajẹ loju ọna yii, nitori ni gbogbo Afrika, ọna ti mọto n gba ju lọ lojoojumọ aye yii ni ọna Ibadan yii, ọna naa lo si ti waa pada di ile iku, ile ofo yii. Nibo ni Faṣọla wa paapaa? Ko waa ṣalaye ohun to n ṣẹlẹ loju ọna yii fun wa o! Abi o digba ti wọn ba pa wa tan soju titi yii ni! A ma ṣe nnkan o!
Ọba Eko, kaabọ, ṣugbọn ẹ kilọ f’Akiolu ko fi suuru ṣe
Baba mọgba, bi wọn ba n tan ọ, ki o ma tan ara rẹ. Awọn olorin ati onilu Yoruba ni wọn maa n kọrin bẹẹ nigba ti wọn ba ri ẹni kan ti wọn n tan, ṣugbọn ti oun naa tun n tan ara rẹ, nitori wọn mọ pe fungba diẹ ni idunnu iru ẹni bẹẹ, bo ba ya, nnkan mi-in yoo tun ṣẹlẹ si i bi ko ba ṣọra ṣe. Ki owe yii jẹ ti Ọba Rilwan Ọṣuọlale Akiolu. Lọsẹ to kọja yii, Akiolu fi ilu ati orin pada sinu aafin rẹ, lẹyin to ti fi odidi oṣu meji gbako sa ninu aafin ọhun, nitori wahala to ṣẹlẹ lasiko ti wọn n ṣe iwọde SARS l’Ekoo yii. Ọjọ buruku lọjọ naa, ọjọ buruku eṣu gbomi mu ni! Awọn ọmọọta ya wọ aafin, wọn ba nnkan jẹ nibẹ, ni gbangba la si n wo ọpa-aṣẹ Akiolu, bi ọmọ elewele kan se na an soke to n sọ pe ‘Ọpa aṣẹ Akiolu ree o! Ọpa aṣẹ Akiolu ree o!’ Bi ko si awọn ṣọja ti wọn wa nitosi ti wọn dọgbọn fi ẹyin pọn kabiyesi funra ẹ jade, afaimọ ki wọn ma gbe ọba naa tọpatọpa, ki la waa fẹẹ maa sọ, pe wọn ji ọba Yoruba gbe ninu aafin. Bẹẹ ohun to le ṣẹlẹ daadaa ni. Awọn ẹlẹtan kan, awọn ti wọn ri ootọ ọrọ nilẹ ti wọn ko jẹ sọ, wọn yoo sọ pe awọn janduku, tabi ki wọn ni awọn oloṣẹlu kan, awọn ni wọn dẹ awọn eeyan si Akiolu.
Ọrọ rirun ni o, bi Kabiyesi ba si n gba iru katikati bẹẹ gbọ, a ṣe pe ọba naa n tan ara rẹ jẹ ni. Ọba le wa lati ibikibi, awọn ọmọọta le wa, awọn oloṣẹlu le wa, ṣugbọn aafin ọba alaye ki i ṣe ibi ti awọn ipanle kan n wọ lati ṣe aburu bi ọba naa ba jẹ eyi ti awọn eeyan rẹ fẹran, ti ọba naa ba jẹ eyi ti awọn araadugbo ibi ti aafin rẹ wa nifẹẹ si daadaa. Akiolu ṣẹ awọn eeyan, oun naa si mọ. Akiolu fẹran oṣẹlu ju ipo ọba lọ, bẹẹ lawọn mi-in si fẹsun aibikita ati igberaga pọnnbele kan an. Eleyii ko jẹ ki awọn eeyan fẹran rẹ laduugbo, ohun ti wọn si ṣe n wo o nigba ti nnkan rẹ n bajẹ lọ niyi, koda, bi wọn ji i gbe lọjọ naa, awọn araadugbo yii yoo maa sọ pe Ọlọrun lo mu un ni. Nigba ti awọn araadugbo ẹni ko ba fẹ tẹni, tabi nigba ti ọpọ awọn ti eeyan jọba le lori ko ba fẹran eeyan, ninu ewu ni iru ọba bẹẹ wa. Nitori ẹ, ki Akiolu ma wo ti awọn oloṣelu ati awọn ẹlẹtan ti wọn waa jo pade ẹ, kaka bẹẹ, ko wo ẹyin, ko si wo awọn ohun ti oun naa ṣe ti ko dara. Bo ba ti ri awọn nnkan wọnyi, ko sare ko yaa tun ibẹ ṣe. Nigba ti ọrọ yii kọkọ ṣẹlẹ, kia lawọn kan ti fẹẹ yi i le awọn Ibo lori, ọpẹlọpẹ ẹni to ji ọpa aṣẹ gbe to n pariwo lede Yoruba lori tẹlifiṣan ati ori ẹrọ ayelujara, ti gbogbo eeyan si ri i pe awọn ọmọ Yoruba, awọn ọmọ Eko nibẹ, ni wọn ṣiṣẹ naa fun ọba wọn. Nidii eyi, ki i ṣe awọn araata ni ko fẹran Akiolu, awọn araale ti ọba naa n ṣejọba rẹ le lori ni. Ẹni to ba ba wa ri Akiolu, ko ṣadura fun un o, pe a ko ni i ri iru eleyii mọ, ewu to ti re kọja lọ ko tun ni i pada wa si aafin. Ṣugbọn koun naa maa ranti owe awọn agba, pe bi koko ba n fẹ ni lẹfẹẹ, a ki i jẹ ori imado; bi a ba si jẹ ori imado, awujọ kumọ ni a ko gbọdọ lọ; a tun waa le ṣeeṣi de awujọ kumọ, iwọnba ara ẹni la a mọ, eeyan ko gbọdọ debẹ ko maa bu iya ẹgbẹ wọn. Ki Akiolu ṣe pẹlẹ, ki oun paapaa le fi agbalagba ara gbadun nipo ọba.
Baba mọgba, bi wọn ba n tan ọ, ki o ma tan ara rẹ. Awọn olorin ati onilu Yoruba ni wọn maa n kọrin bẹẹ nigba ti wọn ba ri ẹni kan ti wọn n tan, ṣugbọn ti oun naa tun n tan ara rẹ, nitori wọn mọ pe fungba diẹ ni idunnu iru ẹni bẹẹ, bo ba ya, nnkan mi-in yoo tun ṣẹlẹ si i bi ko ba ṣọra ṣe. Ki owe yii jẹ ti Ọba Rilwan Ọṣuọlale Akiolu. Lọsẹ to kọja yii, Akiolu fi ilu ati orin pada sinu aafin rẹ, lẹyin to ti fi odidi oṣu meji gbako sa ninu aafin ọhun, nitori wahala to ṣẹlẹ lasiko ti wọn n ṣe iwọde SARS l’Ekoo yii. Ọjọ buruku lọjọ naa, ọjọ buruku eṣu gbomi mu ni! Awọn ọmọọta ya wọ aafin, wọn ba nnkan jẹ nibẹ, ni gbangba la si n wo ọpa-aṣẹ Akiolu, bi ọmọ elewele kan se na an soke to n sọ pe ‘Ọpa aṣẹ Akiolu ree o! Ọpa aṣẹ Akiolu ree o!’ Bi ko si awọn ṣọja ti wọn wa nitosi ti wọn dọgbọn fi ẹyin pọn kabiyesi funra ẹ jade, afaimọ ki wọn ma gbe ọba naa tọpatọpa, ki la waa fẹẹ maa sọ, pe wọn ji ọba Yoruba gbe ninu aafin. Bẹẹ ohun to le ṣẹlẹ daadaa ni. Awọn ẹlẹtan kan, awọn ti wọn ri ootọ ọrọ nilẹ ti wọn ko jẹ sọ, wọn yoo sọ pe awọn janduku, tabi ki wọn ni awọn oloṣẹlu kan, awọn ni wọn dẹ awọn eeyan si Akiolu. Ọrọ rirun ni o, bi Kabiyesi ba si n gba iru katikati bẹẹ gbọ, a ṣe pe ọba naa n tan ara rẹ jẹ ni. Ọba le wa lati ibikibi, awọn ọmọọta le wa, awọn oloṣẹlu le wa, ṣugbọn aafin ọba alaye ki i ṣe ibi ti awọn ipanle kan n wọ lati ṣe aburu bi ọba naa ba jẹ eyi ti awọn eeyan rẹ fẹran, ti ọba naa ba jẹ eyi ti awọn araadugbo ibi ti aafin rẹ wa nifẹẹ si daadaa. Akiolu ṣẹ awọn eeyan, oun naa si mọ. Akiolu fẹran oṣẹlu ju ipo ọba lọ, bẹẹ lawọn mi-in si fẹsun aibikita ati igberaga pọnnbele kan an. Eleyii ko jẹ ki awọn eeyan fẹran rẹ laduugbo, ohun ti wọn si ṣe n wo o nigba ti nnkan rẹ n bajẹ lọ niyi, koda, bi wọn ji i gbe lọjọ naa, awọn araadugbo yii yoo maa sọ pe Ọlọrun lo mu un ni. Nigba ti awọn araadugbo ẹni ko ba fẹ tẹni, tabi nigba ti ọpọ awọn ti eeyan jọba le lori ko ba fẹran eeyan, ninu ewu ni iru ọba bẹẹ wa. Nitori ẹ, ki Akiolu ma wo ti awọn oloṣelu ati awọn ẹlẹtan ti wọn waa jo pade ẹ, kaka bẹẹ, ko wo ẹyin, ko si wo awọn ohun ti oun naa ṣe ti ko dara. Bo ba ti ri awọn nnkan wọnyi, ko sare ko yaa tun ibẹ ṣe. Nigba ti ọrọ yii kọkọ ṣẹlẹ, kia lawọn kan ti fẹẹ yi i le awọn Ibo lori, ọpẹlọpẹ ẹni to ji ọpa aṣẹ gbe to n pariwo lede Yoruba lori tẹlifiṣan ati ori ẹrọ ayelujara, ti gbogbo eeyan si ri i pe awọn ọmọ Yoruba, awọn ọmọ Eko nibẹ, ni wọn ṣiṣẹ naa fun ọba wọn. Nidii eyi, ki i ṣe awọn araata ni ko fẹran Akiolu, awọn araale ti ọba naa n ṣejọba rẹ le lori ni. Ẹni to ba ba wa ri Akiolu, ko ṣadura fun un o, pe a ko ni i ri iru eleyii mọ, ewu to ti re kọja lọ ko tun ni i pada wa si aafin. Ṣugbọn koun naa maa ranti owe awọn agba, pe bi koko ba n fẹ ni lẹfẹẹ, a ki i jẹ ori imado; bi a ba si jẹ ori imado, awujọ kumọ ni a ko gbọdọ lọ; a tun waa le ṣeeṣi de awujọ kumọ, iwọnba ara ẹni la a mọ, eeyan ko gbọdọ debẹ ko maa bu iya ẹgbẹ wọn. Ki Akiolu ṣe pẹlẹ, ki oun paapaa le fi agbalagba ara gbadun nipo ọba.
Awọn Fulani ko ti i rin jinna, ẹ ma sun asunpara o
Nigba ti iroyin jade pe awọn ẹṣọ Amọtẹkun ti gba awọn inu igbo kan lọwọ awọn Fulani oniwahala ni Oke-Ogun, idunnu lọrọ naa mu wa fawọn eeyan, nitori iṣẹ ti wọn fẹ ki Amọtẹkun waa ṣe gan-an niyẹn. Iṣẹ ẹyọ kan yii lawọn Yoruba gbe fun awọn Amọtẹkun, iṣẹ naa si ni lati gba wọn kalẹ lọwọ awọn Fulani onimaaluu, awọn Fulani darandaran. Wọn ni bi wọn ti gburoo wọn si inu igbo lagbegbe naa ni wọn ti ṣa ara jọ, wọn si wọ igbo naa titi ti wọn fi ri awọn Fulani yii mu laarin oru, ti wọn si le wọn jade ni agbegbe wọn. Ko si ohun to dun to eyi, iroyin amaraya gaga ni. Ko si aburu tabi ipaya kankan to wa fun gbogbo Yoruba lasiko yii ju ti wahala awọn Fulani yii lọ. Nigba to jẹ lojoojumọ iku ni bayii nkọ, ki wọn jiiyan gbe loni-in, ki wọn jiiyan gbe lọla, ti igbiyanju awọn ọlọpaa lori ọrọ naa ko si muna doko.
Bi Amọtẹkun ba waa dide, ti wọn kun awọn agbofinro lọwọ, ko si ohun to buru nibẹ rara, nitori awọn Amọtẹkun yii mọ ọna adugbo wọn ju awọn ọdaran yii paapaa lọ. Bi Amọtẹkun ba mu Fulani, ti wọn ko pa a, ti wọn kan le e jade kuro niluu wọn ati ni agbegbe wọn, ko si ohun to buru nibẹ, nitori ohun ti eeyan ko ba fẹ ni agbegbe rẹ, ko fẹ ẹ naa ni, agaga ohun to ba n di alaafia ilu lọwọ. Ko si si ofin kan to lodi si iru ẹ, nitori ohun gbogbo ti ko ba ti ba alaafia mu, gbogbo ọna leeyan le fi kọ ọ, lati mu alaafia pada wa si awujọ. Awọn Amọtẹkun yii ko gbọdọ duro ṣaa o, bẹẹ ni wọn o gbọdọ tura silẹ, nitori nibi gbogbo ti wọn ba ti le Fulani onimaaluu, wọn a tun maa pada wa si agbegbe naa lati ṣe awọn eeyan ibẹ leṣe, ti wọn yoo ni awọn ni wọn lọọ sọrọ awọn fun awọn ẹṣọ. Ki gbogbo awọn ọmọ Yoruba ti wọn wa ni agbegbe yii maa fura si alejo yoowu ti wọn ba ti ri, ti wọn ba si ti mọ pe Fulani ni, ki wọn tete fi ọrọ rẹ to awọn ẹṣọ wọnyi leti, awọn ni wọn yoo mọ ohun ti wọn yoo ṣe. Ki awọn olori Amọtẹkun Ọyọ mojuto awọn ẹṣọ naa, ki wọn wo awọn ti wọn ba fẹẹ maa fi kinni naa ṣe janduku, ki wọn si ri i pe wọn yọ iru ẹni bẹẹ danu lawujọ wọn. Lojoojumọ ni ki wọn tubọ maa kọ awọn ẹṣọ yii ni ẹkọ loriṣiiriṣii, ẹkọ igbaradi, ilo ibọn ati awọn nnkan mi-in ti ko ni i jẹ ki apa awọn Fulani ka wọn lojiji ninu igbo, ki wọn si kọ wọn ni iwa ọmọluabi ti wọn yoo maa lo lawujọ. Iṣẹ ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, ẹyin Amọtẹkun gbogbo nilẹ Yoruba, awọn Fulani ko ti i rin jinna, ẹ ma sun asunpara o.
Ni ti kọmiṣanna oni-kinni ko-m’ọmọde
Iṣẹ ijọba ki i ṣe iṣẹ ti eeyan i ṣe ti i fi igba kan bọkan ninu. Iṣẹ ti eeyan i ṣe, ti i ko gbogbo aniyan ati bi ọrọ ba ti ri siwaju awọn araalu ni. Bi aburu ba ṣẹlẹ lati ọwọ ẹni yoowu to ba wa ninu iṣẹ ijọba, ko gbọdọ gba awọn ọga rẹ ni wakati pipẹ ti wọn yoo fi yọ ẹni naa jade kuro lara wọn, iyẹn ni yoo jẹ ki inu awọn araalu dun, ti yoo si jẹ ki gbogbo aye le ridii okodoro. Gomina Dapọ Abiọdun ti yọ komiṣanna kan ti wọn fẹsun pe o fẹẹ fi tipa tipa ba ọmọde kan sun, Abiọdun Abudu-Balogun, kuro lẹnu iṣẹ rẹ, o ni ko lọọ da awọn ọlọpaa ati awọn oluwadii lohun ẹsun ti ọmọde naa fi kan an, ki oun naa le ri aaye fi han gbogbo aye bi nnkan ti ṣe ṣẹlẹ gan-an. Ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan, Barakat Melojuẹkun, lo ya ara rẹ sinu fidio, to si ju kinni naa sori ẹrọ ayelujara. Ohun to ṣalaye sibẹ ni bi Abudu-Balogun ṣe fẹẹ mu oun nipa, to fẹẹ fipa ba oun sun.
Ọrọ naa run si ni, koda, ko ṣee gbọ seti. Kọmiṣanna n wa mọto lọ, o ri ọmọleewe to duro lati wọkọ, o loun yoo gbe e, iyẹn ni oun ko ṣe, komiṣanna naa si bẹrẹ si i wa awọn eeyan ti wọn yoo ba oun mu ọmọ naa wa sile, wọn mu ọmọ dele tan, kọmiṣanna ni ki wọn mu un wọ yara, o tilẹkun mọ ọn, o bẹrẹ si i fọwọ tẹ ẹ lọmu, o fẹẹ ti i lu bẹẹdi ki iyẹn too fi ariwo ta. Bẹẹ lo n pọfọ bii ẹgbẹji, boya ọfọ oogun amudo ni tabi ti eyi ti wọn fi n fi ọmọ ṣowo, ko sẹni to le sọ. Ṣugbọn ọmọ naa ati awọn obi rẹ huwa ọlọgbọn pupọ, wọn ko jẹ ki ọrọ naa tutu ti wọn fi gbe e lọ si tọlọpaa, ti wọn si tun ju u sori ẹrọ ayelujara, nitori bi wọn ko ba ṣe bẹẹ ni, ọrọ naa yoo wọlẹ lasan, Ọlọrun nikan lo ṣaa mọ iye ẹni ti Abudu-Balogun ti ṣe bayii fun ninu awọn ọmọde adugbo, ti yoo fi owo tan wọn, ti yoo si maa fi ọfọ halẹ mọ wọn. Bawo ni agbalagba yoo ṣe ki iru ọmọde bẹẹ mọlẹ ti yoo si fẹẹ ba a laye jẹ. Abudu-Balogun n wayawo ni abi o kan n wa ẹni ti yoo ba sun lasan. Iru eeyan wo ni wọn fi ṣe kọmiṣanna bayii, ẹni to ro pe ti oun ba ti wa nipo kan, oun le fi ipo naa yan awọn eeyan jẹ. Ọlọrun lo mu un, Oun naa ni yoo si tubọ tu aṣiri rẹ si i. Dajudaju, ipo kọmiṣanna ti bọ na, iṣẹ mi-in lo ku ti yoo wa ṣe. Iyẹn ni oriyin ṣe tọ si Dapọ Abiọdun ti i ṣe gomina, ẹni ti ko jẹ ki wọn fi rẹdẹrẹdẹ rẹ ijọba oun lara. Ẹni ba ṣe e yoo fi oju ara rẹ ri i, ohun ti komiṣanna onikinni **yọkiyọkiyoki naa ba ri nidii iṣẹlẹ yii, ko mọ pe oun funra oun loun fọwọ ara oun wa a.