Stephen Ajagbe, Ilorin
Eeyan mẹta lo jẹ Ọlọrun nipe lọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ to lọ yii, nibi ija to bẹ silẹ laarin awọn onifayawọ atawọn ẹṣọ aṣọbode nijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara.
Alukoro ileeṣẹ aṣọbode ẹka tipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Chado Zakari ni awọn ti ko oku awọn eeyan naa lọ si mọṣuari ilewosan Baptist, to wa niluu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ.
Zakari ni awọn onifayawọ irẹsi lọpọlọpọ ninu awọn to kọju ija si awọn oṣiṣẹ aṣọbode lọjọ naa, o ni gbogbo akitiyan ọba ilu yii lati pẹtu si wọn ninu lo ja si pabo, koda, wọn tun gbiyanju lati kọ lu Emir naa, ṣugbọn awọn ẹṣọ rẹ sare gbe e kuro nibi to ti lọọ pẹtu si aawọ.
Nigba to n ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, Zakari ni awọn oṣiṣẹ awọn to wa lọna Ṣaki da ọkọ Volkswagen alawọ pupa kan ti nọmba rẹ jẹ; BDG 453 BH duro, ṣugbọn awakọ naa kọ lati duro, idi niyẹn tawọn yẹn ṣe le e mu.
Ọkunrin yii ni bi dẹrẹba naa ṣe ri i pe ilẹ ti mọ ba oun lo yọnda ọkọ naa pẹlu ẹru irẹsi to ko, to si sa wọnu igbo lọ tefetefe.
O fi kun un pe awọn aṣọbode wọ mọto naa lọ sibudo wọn lati yẹ awọn ohun to ko wo, wọn si ba awọn apo irẹsi ilẹ okere to kun inu ẹ bamu.
Lẹyin wakati diẹ ni awakọ naa pada wa pẹlu awọn ẹgbẹ rẹ atawọn ọdọ kan ti wọn ko igi, okuta atawọn ohun ija oloro lọwọ lati kọ lu ibudo aṣọbode naa.
Awọn aṣọbode kuro nibẹ pẹlu ọkọ to ko irẹsi ti wọn gbẹsẹ le naa, lẹyin iyẹn lawọn onifayawọ naa dana sun ibudo wọn, ti gbogbo ohun to wa nibẹ si jona guruguru.
Zakari ni lasiko akọlu naa, ọlọpaa kan fara pa, ṣugbọn o ti n gbadun nileewosan ti wọn gbe e lọ lati tọju ẹ.
Alukoro yii ni lẹyin ti wọn dana sun ibudo naa ni wọn tun gba ibudo tawọn n ko awọn ohun ija oloro atawọn mọto tawọn fi n ṣiṣẹ, to fi mọ awọn ẹru tawọn gba lọwọ awọn onifayawọ si. Asiko yii gan-an lawọn koju ija si wọn.
ALAROYE gbọ pe ọkọ kan tawọn to waa kọ lu ibudo naa gbe wa ni awọn aṣọbode yinbọn mọ, to si gbokiti, oju ẹsẹ lawọn mẹta dagbere faye.
O ṣalaye pe ipade alaafia waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹsan, nibi ti Emir, awọn adari ilu, atawọn ọdọ ti peju, ireti si wa pe awọn to da rogbodiyan naa silẹ ko ni i lọ lai jiya to ba tọ si wọn.