Ọlawale Ajao, Ibadan
Oludari ikọ eleto aabo ilẹ Yoruba, iyẹn Amọtẹkun ẹka ipinlẹ Ọyọ, Ajagunfẹyinti Ọlayinka Ọlayanju, ti sọ pe awọn ajinigbe ni ẹṣọ Amọtẹkun yinbọn pa ninu aginju igbo lagbegbe Ibarapa, ki i ṣe awọn Fulani nitori ko sija laarin ẹṣọ Amọtẹkun atawọn Fulani ọlọsin ẹran.
Ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan, Ajagun-fẹyinti Ọlayanju sọ pe loootọ lawọn Amọtẹkun lọọ kogun ja awọn agbesunmọ to n fi awọn inu igbó agbegbe naa bójú ṣiṣẹ ibi ti awọn sí yinbọn pa mẹta ninu awọn afurasi ọdaran tó dojú ija kọ àwọn ninu igbo naa, ṣugbọn awọn olori awọn Fulani naa mọ sí igbesẹ awọn ọhun.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Iṣẹlẹ ijinigbe ti di lemọlemọ lagbegbe Ìbàràpá, a sì mọ pe inu igbo lawọn afurasi ọdaran naa maa n lo lati ṣiṣẹ ibi wọn. Idi niyẹn ta a ṣe pinnu lati ṣigun wọ gbogbo inu igbó to wa lagbegbe yẹn, ka le palẹ awọn ẹni ibi naa mọ lagbegbe yẹn.
“Ẹgbẹ awọn Fulani ọlọsin maaluu naa mọ si i ko too di pe a ṣigun lọ sinu awọn igbo yẹn, nitori a sọ fun wọn ka too ṣe e. Koda, awọn Miyyeti Allah paapaa, pẹlu awọn ọdẹ ibilẹ atawọn fijilante dara pọ mọ àwọn èèyàn wa to ṣigun lọ si awọn aginju igbo to wa nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ibarapa, Aarin-Gbungbun Ibarapa, Ariwa Ibarapa atijọba ibilẹ Iwajọwa.
“Nigba ti awọn eeyan wa (Amọtẹkun), de inu aginju igbo kan lagbegbe Ayẹyẹ lawọn kan doju ija kọ wọn, ti wọn si jọ fija pẹẹta ko tóo di pe mẹta ninu awọn eeyan yẹn ku.
“Awọn to lọ si Igboọra naa koju ipenija lọdọ awọn agbesunmọmi meji kan, wọn ri awọn mejeeji mu, wọn si ko wọn lọ si tesan ọlọpaa n’Igboọra pẹlu ibọn ti wọn ka mọ ọkan ninu wọn lọwọ.
“Lẹyin ti awọn eeyan wa jade ninu awọn igbo yẹn la gbọ pe wọn ji ẹni kan gbe. Fulani lẹni tí wọn ji gbe yìí, nitori naa, bi ọrọ ijinigbe ṣe n pa Yoruba lara lo n pa awọn Fulani naa lara ”
Ajagun-fẹyinti Ọlayanju fidi ẹ mulẹ siwaju pe ninu aginju igbo kan niluu Ayegun, nijọba ibilẹ Iwajọwa, lọwọ awọn Amọtẹkun ti tẹ afurasi ajinigbe kan to n jẹ Sanni Bello, nnkan bii aago mẹsan-an aabọ aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ana.