Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Ni nnkan bii aago mẹjọ ku ogun iṣẹju, aarọ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejila, oṣu kin-in-ni, ọdun 2020 yii, ni iku ojiji pa tọkọ-taya kan loju ọna Ṣagamu-Ogijo, nipinlẹ Ogun. Ọlọkada to gbe wọn lo fi tiẹ ko ba wọn nigba to fẹẹ ya ọkọ Camry kan silẹ, bo ṣe takiti, ti tirela to n bọ lẹyin tẹ wọn pa niyẹn.
Nigba to n ṣalaye bi ijamba naa ṣe ṣẹlẹ gan-an, Alukoro TRACE, Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi, sọ pe Ogijo ni ọlọkada to da wahala silẹ naa ti n bọ, Ṣagamu lo si n lọ.
O ni mọto bii mẹta ni ọkada ti ko ni nọmba naa ti ya silẹ, nibi to ti n sare buruku loju popo.
Igba to fẹẹ ya mọto ayọkẹlẹ Camry ti nọmba ẹ jẹ FKY 733GF silẹ lo lọọ kọ lu mọto naa lẹyin, bii igba ti ẹyin fori sọ apata lo ri, nitori niṣe lọkada ṣubu yakata si titi, ti awọn tọkọ-tiyawo to gbe naa ṣubu pẹlu, ki wọn too dide ni tirela to n bọ lẹyin, ti nọmba ẹ jẹ AGL 505 WX ti ba wọn nibẹ, to si tẹ wọn pa.
Ọlọkada yii ko ku ni tiẹ, o kan ṣeṣe ni. Akinbiyi sọ pe ile igbokuu-si to wa nileewosan Ọlabisi Ọnabanjọ, ni Ṣagamu, lawọn gbe oku awọn tọkọ-taya naa lọ. O ni ileewosan Idẹra lawọn gbe ọlọkada to ṣeṣe lọ.