Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun
Titi dasiko yii lawọn eeyan ṣi n sọrọ nipa iṣẹlẹ aburu kan to waye niluu Ṣaki, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii, nigba tawọn ọdọ ilu naa fibinu dana sun tirela kan ati maaluu mẹtadinlọgbọn to ko sinu rẹ, latari ijamba ọkọ to waye ṣaaju, wọn ni tirela naa pa ọlọkada to jẹ ọmọ ilu Ṣaki kan.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọja maaluu to wa niluu Ilesha Ibaruba, nipinlẹ Kwara, ni wọn ni tirela naa ti gbera, ibẹ lo ti lọọ ra maaluu to ko sẹyin, to si fẹẹ gba adugbo Challenge kọja niluu Ṣaki.
Ẹnikan tọrọ naa ṣoju ẹ sọ f’ALAROYE pe ere asapajude lọkunrin naa n sa bọ, bẹẹ adugbo to fẹẹ gba kọja yii, adugbo tawọn ọmọleewe Poli Ṣaki pọ si ni. Yatọ siyẹn, iṣẹ atunṣe ọna n lọ lọwọ lori titi onibeji ọhun, o si yẹ konimọto rọra ṣe lasiko naa ni pẹlu awọn ami ti wọn gbe sẹgbẹẹ ọna.
Wọn ni ọkunrin ọlọkada kan, Ayuba Raji, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, wa lori ọkada ẹ pẹlu ẹgbọn rẹ obinrin to fẹẹ gbe sọda sodikeji ọna naa.
Nigba ti Raji ti ri ere buruku ti tirela naa n sa bọ, niṣe lo yi ọkada rẹ sẹgbẹẹ kan, tori ọna ti ko yẹ ki tirela naa gba lo gba.
Wọn ni kongẹ ọlọkada yii ni tirela naa de ti taya ọkọ rẹ kan fi fo yọ, ko si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, o ti kọ lu ọlọkada to duro, ẹsẹkẹsẹ lọkunrin naa ku, bo tilẹ jẹ pe ori ko obinrin to gbe sẹyin yọ.
A gbọ pe loju-ẹsẹ ti awakọ tirela ọhun ti fura pe ọṣẹ nla ti ṣe lo ti fo bọ silẹ niwaju ọkọ, o fi maaluu ati mọto rẹ silẹ, lo ba sa lọ.
Bawọn ọdọ ṣe ri ohun to ṣẹlẹ naa ni wọn ti ya bo tirela ọhun, wọn fibinu fọ gbogbo gilaasi ọkọ naa, ni wọn ba da epo bẹntiroolu sara ẹ, wọn ṣana si i, ati maaluu, ati tirela, ni wọn sun jona rau.
Ni idaji ọjọ keji takọroyin wa ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ naa, pitimu lawọn ọdọ naa ṣi ya bo oju titi, wọn dana saarin ọna lẹyin ti wọn ti gbe’gi dina tan, wọn o jẹ ki onimọto eyikeyii kọja, wọn n fẹhonu han latari iṣẹlẹ to waye ọhun.
Deede aago mẹwaa aabọ owurọ ọjọ naa ni Ọkẹrẹ tilu Ṣaki, Ọba Khalid Ọlabisi, waa ba awọn ọdọ ilu naa sọrọ, o pẹtu si wọn ninu, eyi lo mu koju awọn ọdọ ọhun walẹ diẹ, ti wọn si gba lati gbe igi kuro lọna fawọn ọlọkọ to fẹẹ kọja.
Nigba to n ba akọroyin wa sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Alaga ẹgbẹ awọn onimọto agbegbe naa, Ọgbẹni Azeez Destiny, koro oju si bawọn onimaaluu ṣe n wa tirela wọn niwakuwa lai bikita loju ọna naa, o si parọwa fun ijọba lati wa nnkan ṣe, paapaa ti ọna marosẹ naa ba pari.