Ọlawale Ajao, Ibadan
Laarin wakati mélòó kan sira wọn, èèyàn meji ni won ti pa nipakupa bayii laduugbo Leventis, lagbegbe Ajibade, n’Ibadan. Eyi lo si sọ awọn olugbe agbegbe naa sinu ibẹru bojo nitori wọn ko mọ igba ti awọn ẹruuku naa tun le dé torótoró lati pada waa pitu ọwọ wọn.
L’Ọjọbọ, Tọsidee to kọja, ni wahala ọhun bẹrẹ, nigba ti awọn ọdọ àdúgbò náà dana sun ọkunrin kan laaye.
Ẹsun ole ni wọn fi kan ọkunrin ti a ko mọ orúkọ rẹ yii ti wọn fi da sẹria iku fun un funra wọn.
Laaarọ ọjọ keji, iyẹn ọjọ Ẹtì, Furaidee, lawọn eruuku kan ya wọ adugbo naa tibọntibọn pẹlu awọn ohun ija oloro mi-in, ti wọn si pa ẹnikan lai ṣẹ lai ro.
Bakan naa la gbọ pe wọn ba ọpọlọpọ dukia jẹ kí wọn too fi adugbo naa silẹ.
Èyí ló mú kí ọpọlọpọ awọn to n taja nibẹ tilẹkun ṣọọbu wọn, ti wọn sì wá ibi fara pamọ́ si.
Nigba to n ba akọroyin wa sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CSP Olugbenga Fadeyi, fidi ẹ mulẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lo jọ pe wọn lọọ kọ lu awọn olugbe adugbo Leventis, nitori pipa ti awọn araadugbo naa pa afurasi ole ti wọn mu nibẹ lọjọ Tọsidee.
Ọpọlọpọ igba, nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti kilọ fawon ọdọ ipinlẹ yii, paapaa, awọn tigboro Ibadan, lati yee maa fiya jẹ afurasi ọdaran funra wọn, awọn ọdọ agbegbe Leventis, nigboro Ibadan, ti tun dana sun ọmọkunrin kan laaye.
Laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, niṣẹlẹ ọhun waye lagbegbe Leventis, ni Dugbẹ, n’Ibadan.