Stephen Ajagbe, Ilorin
Ajiṣafẹ Tokunbọ, oṣiṣẹ ajọ to n mojuto igboke-gbodo ọkọ, FRSC, tẹlẹ, ti wa lahaamọ ọgba ẹwọn bayii fẹsun pe o lu Raji Jimọh ni jibiti ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin naira din diẹ (#673,000) niluu Omu-Aran, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, nipinlẹ Kwara.
Adajọ A.O Idiagbọn tile-ẹjọ Majisireeti kan to wa niluu Ilọrin lo paṣẹ naa lọjọ Ẹti, Furaide, nigba tileeṣẹ NSCDC wọ ọ lọ sibẹ.
Afurasi naa ni wọn lo pe ara rẹ ni ọga FRSC to n mojuto Omu-Aran ati gbogbo agbegbe rẹ, to si gba owo ọhun pẹlu ileri lati lo ipo rẹ gba Jimọh siṣẹ.
Iwadii ti ẹka to n mojuto ẹsun jibiti nileeṣẹ NSCDC ṣe fi han pe lati ọdun 2007 ni wọn ti le olujẹjọ naa lẹnu iṣẹ.
Agbẹjọro ijọba, Amofin Ajide Kẹhinde, rọ ile-ẹjọ ki wọn gbe Ajiṣafẹ sahaamọ na, nitori ẹsun ti wọn fi kan an ki i ṣe eyi ti wọn le fun un ni beeli.
Adajọ Idiagbọn to gba ẹbẹ agbefọba naa ni ki wọn gbe olujẹjọ lọ si ọgba ẹwọn, o sun ẹjọ si ogunjọ, oṣu kin-in-ni, ọdun yii.