Minisita fun eto iṣuna nigba kan, Sẹnetọ Jubril Martins-Kuyẹ ti jade laye lẹni ọdun mejidinlọgọrin (78).
Ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe ọhun, Abọlaji ti sọ pe loootọ niṣẹlẹ ọhun waye, ati pe ile baba naa ni Victoria Garden City, niluu Eko, lo ku si ni deede aago mẹwaa aarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Akọṣẹmọṣẹ ni Sẹnetọ Jubril Kuyẹ ninu iṣẹ iṣiro-owo, bẹẹ ipinlẹ Eko ni wọn sọ pe o ti ṣiṣẹ daadaa ko too darapọ mọ oṣelu, ninu eyi to ti dije dupo aṣofin agba, to si ṣe bẹẹ di Sẹnetọ lasiko ijọba alagbada ẹlẹẹkẹta ni Naijiria.
Ọdun 1999, gan-an ni wọn lo tun gbiyanju lati dupo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ṣugbọn ti Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba fẹyin ẹ gbolẹ ninu idije ọhun nipinlẹ Ogun.
Bo tilẹ jẹ pe o kuna lati jawe olubori ninu ibo gomina, sibẹ Aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ fun un nipo minisita kekere fun eto iṣuna. Ori ipo ọhun naa lo si wa titi di ọdun 2003.
Nigba to tun di ọdun 2010 si 2011, Aarẹ Goodluck Jonathan naa tun fun un nipo minisita okoowo ati ileeṣẹ.
Aago mẹrin ọjọ Aiku to jade laye yii naa ni wọn yoo sin in nilana ẹsin Islam sile ẹ to wa niluu Ago-Iwoye, ipinlẹ Ogun.