Florence Babaṣọla
Awọn alaṣẹ ileewe Obafemi Awolowo University, Ileefe, ti kede pe ọjọ keje, oṣu keji, ọdun yii, lawọn akẹkọọ kan yoo pada sileewe.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe ileewe naa, Arabinrin Omosule, fi sita lo ti ṣalaye pe ki i ṣe gbogbo akẹkọọ ni yoo pada sinu ọgba, ori ẹrọ-ayelujara lawọn yooku yoo ti maa kẹkọọ wọn.
Awọn ti yoo pada sinu ọgba ileewe naa ni awọn akẹkọọ ti wọn wa nipele aṣekagba ni Faculty of Pharmacy, Clinical Student, ti wọn wa ni College of Health Sciences, atawọn Faculty of Agriculture.
Ọmọṣule fi kun un pe awọn alaṣẹ ti fagi le saa ikẹkọọ 2020/2021, o si pọn dandan fun awọn akẹkọọ ati olukọ lati tẹle gbogbo ilana idena ajakalẹ arun Koronafairọọsi.
O ni ibomu lilo ṣe pataki, bẹẹ ni ko gbọdọ si ifarakanra nibikibi. Wọn gbọdọ maa fọ ọwọ wọn pẹlu ọṣẹ loorekoore, ki wọn si maa fi sanitaisa sọwọ.