Aderounmu Kazeem
Lọjọ Ẹti, Furaidee, to lọ yii ni wọn ba oku ọkùnrin kan ninu mọto loju ọna CMD, lagbegbe Magodo, l’Ekoo.
Ninu fidio kan to n lọ kaakiri ori ẹrọ ayelujara lawọn eeyan ti pe bo ọkunrin naa, ti wọn si n wa foonu rẹ lati le wo nọmba ti wọn le pe ti awọn mọlẹbi rẹ yoo fi mọ ohun to ṣẹlẹ si i.
ALAROYE gbọ pe gbogbo asiko ti ọkunrin yii fi ku, ina mọto ṣi wa ni titan silẹ. O jọ pe lori irin ni iṣẹlẹ ti ẹnikẹni ko mọ ti ṣẹlẹ si ọkunrin naa, ki iranlọwọ si too de, o ti ku.
Awọn kan ti wọn wa nitosi sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe niṣe ni ọkan ọkunrin ti ẹnikẹni ko mọ orukọ rẹ to wa ninu mọto Honda Accord yii daṣẹ silẹ lojiji, to si ṣe bẹẹ ku nitori irisi rẹ ko jọ ti ẹni ti aisan n ṣe rara.
Ọga agba fún iṣẹlẹ pajawiri l’Ekoo, Dokita Olufẹmi Oke-Ọ̀sanyintolu, lo sọrọ yii fawọn oniroyin nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Oke-Ọ̀sanyintolu sọ pe ni kete ti wọn ti fi iṣẹlẹ ọhun to àjọ àwọn leti lawọn ti sáré débi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn ti ẹni tawọn ba ninu ọkọ naa ti jade laye.
Ẹni tó ti doloogbe yìí nìkan ni wọn ba ninu ọkọ ọhun, orí ṣiarin to gbe ori le naa ni wọn lo dakẹ sí.
Oke-Ọ̀sanyintolu fi kun un pe nigba tí àwon ṣayẹwo fún un, ko mi mọ rara, èmi ti bọ lẹnu ẹ patapata.
O ni loju ẹsẹ lawọn èèyàn olóògbé náà ti sáré debẹ, ti wọn sì ti gbé é lọ sile igbokuu-si to sun mọ agbegbe iṣẹlẹ ọhun.