Aderounmu Kazeem
Pẹlu ohun to ṣẹlẹ niluu Igangan atawọn ilu kan nipinlẹ Ọyọ lana-an, nigba ti Oloye Sunday Adeyẹmọ, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho kọlu awọn Fulani darandaran to si le wọn lugbo, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti sọ pe oun ko ni i faaye gba iru iwa bẹẹ, ati pe eni kan ko laṣe lati le ẹnikẹni nipinlẹ ọhun.
Gomina Seyi Makinde lo fidi ọrọ yii mulẹ lasiko to gbalejo kọmiṣanna ọlọpaa tuntun fun ipinlẹ Ọyọ, Arabinrin Ngozi Ọnadẹkọ.
Gomina yii sọ pe gbogbo ohun to n ṣẹlẹ l’Oke Ogun pata loun n gbọ lori bi ẹnikan ṣoṣo ṣe paṣẹ pe oun ko fẹẹ ri awọn Fulani lawọn ilu kan lagbegbe naa mọ, to si tun lọọ kogun ja wọn pẹlu.
O loun ko ni i fara mọ ki ẹnikan sọ pe oun n ja fun ẹya kan tabi ilu kan, ko si maa fi da wahala silẹ nipinlẹ Ọyọ.
Makinde ti sọ pe ẹnikẹni to ba ti n dunkoko mọ ẹya kan tabi da laasigbo silẹ ni ki awọn ọlọpaa mu bayii, ki wọn si fi ọwọ ofin jẹ iru ẹni bẹẹ niya. Gbogbo eeyan si mọ pe ko si ẹni to ni owe naa bi ki i ṣse Sunday Igboho.
O ni, “Ti a ba ri ẹnikẹni to ba n sọ pe oun n ja fun iran Yoruba, to wa n fi iwa ọwọ ẹ da rukerudo silẹ, niṣe ni ki ẹ mu iru ẹni bẹẹ ko si foju wina ofin. Emi naa ko fọwọ si iwa ijinigbe tabi idaluru, bẹẹ la wa ko doju ija kọ Hausa tabi Fulani, awọn janduku la o fẹ ri mọ nipinlẹ Ọyọ. Gbogbo ẹnikẹni to ba ti jẹ janduku la o fẹẹ ri, a o fẹẹ mọ iru ẹya to jẹ tabi ẹsin to n ṣe.
“Boya ẹyin naa ti gbọ ọ, nigba tawọn janduku kan n ko iyọnu ba awọn eeyan lagbegbe Okeeho, nijọba ibilẹ Kajọla, ọpọ eeyan ni wọn pa, nigba ti ọwọ si tẹ awọn to n hu iwa yii, njẹ ẹ jẹ mọ pe awọn Ebira ni, lati ipinlẹ Kogi lọhun-un. Fun idi eyi, awọn janduku lawa ko fẹẹ ri mọ nipinlẹ yii yala wọn jẹ Yoruba, Hausa, Fulani tabi eyikeyi ninu ẹya.”
Makinde sọ pe ogun ti awọn ẹṣọ agbofinro gbọdọ mura ẹ bayii ki i ṣe lati fi kogun ja ẹya kan bikoṣe awọn janduku adaluru laibikita ẹsin tabi ẹya iru ọdaran bẹẹ.
O ni ijọba oun ko ni i faaye gba ẹnikẹni lati di alaafia ilu lọwọ nipa ṣiṣe awọn nnkan ti ko ba ofin orilẹ-ede Naijiria mu.