Seriki awon Fulani lo maa n ba wa fun awon ajinigbe lowo -Awon ara Igangan

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Pẹlu bi inu wọn ṣe n dun ṣinkin fún bí ọba awọn Fulani ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Saliu Abdul-Kadiri, atawọn Fulani ilu Igangan ṣe sa fi ilu naa silẹ, awọn araalu naa ti royin idaamu ti awọn ọdaju àjèjì náà n mú ba awọn.

Wọn ni yatọ si bi awọn Fulani ṣe maa n pa awọn nipakupa, aadọta miliọnu naira (#50m) lawọn maa n san fawọn ọdaju àjèjì náà kí wọn tóo lè yọnda eeyan awọn ti wọn ba ji gbe fawon.

Lọjọ Aiku, Sannde, ìjẹta, ni wọn sọrọ yii nigba ti wọn gbalejo aṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ ati oga agba ọlọpaa ipinlẹ naa, Abilekọ Ngozi Onadeko, fun ìpàdé alaafia ati abẹwo sí awọn nnkan to bajẹ lasiko rogbodiyan to waye lọjọ Ẹtì, Furaidee, to kọja.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, lajafẹtọọ ọmọ Yorùbá nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Ìgbòho ya wọlu Igangan pẹlu awọn ajijagbara ẹgbẹ ẹ bíi OPC atawọn ọmọ ẹgbẹ Agbẹkọya lati sọ fún àwọn ọdaran Fulani to wa niluu naa ati agbegbe Ibarapa lapapọ, pé àsìkò ti to fún wọn láti fi ipinlẹ Ọyọ silẹ patapata.

Lọsan-an ọjọ Sannde to kọja laṣoju Gomina Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ, CP Fatai Owoṣeni ti i ṣe oludamọran pataki fún gomina lori ọrọ eto aabo, pẹlu ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Ngozi Onadeko. ṣabẹwo siluu Igangan lati wo awọn nnkan to bajẹ lasiko laasigbo naa. ki wọn si ba awọn agbaagba agbegbe Ibarapa sọrọ.

Ninu Ipade ọhun lawọn ara Igangan ti lahùn pe awọn Fulani lo wa nidii awọn iṣẹlẹ ọdaran bíi ipaniyan, ijinigbe, idigunjale ati ifipabanilopọ to n waye gbọnmọgbọnmọ lagbagbe awọn lẹnu lọọlọọ yìí.

Wọn ni oun to ṣe ni ni kayeefi ni pe ọba awọn Fúlàní to sá fi ilu Igangan silẹ yii mọ nipa ọran naa nitori oun lo maa mọ bi owo ti awọn ba san lati yọ awọn eeyan awọn kuro nigbekun awọn ajinigbe yóò ṣe tẹ awọn agbesunmọmi ẹda naa lọwọ.

Nigba to n sọrọ lorukọ Gomina Makinde, CP Owoṣeni sọ pe ìgbàgbọ ọpọ eeyan ni pe ijọba ko gbe igbesẹ kankan lati dẹkun eto aabo to mẹhẹ, bẹẹ ọrọ ko ri bẹẹ, eeyan mokanlelaaadọta nijọba ti mu fún onírúurú iwa ọdaran nipinlẹ naa to jẹ pe wọn ti fa wọn le awọn ọlọpaa lọwọ, ti wọn sì ti fi oju ọpọ nínú wọn ba ile-ẹjọ.

Ninu ọrọ tiẹ, CP Onadeko rọ awọn olugbe agbegbe naa lati gba alaafia laaye, ki wọn si yee máa fọwọ ara wọn jẹ arufin níyà. Dipo bẹẹ, ki wọn maa fa wọn lè awọn agbofinro lọwọ fún ijiya to ba tọ labẹ ofin.

 

Leave a Reply