ISSA FUNTUA, ỌKAN NINU AWỌN IGI-LẸYIN-ỌGBA BUHARI, TI KU O

NInu ile ijọba Aso Rock, a-gbọ-sọgba-nu ni iroyin iku ọhun jẹ. Awọn eeyan ibẹ ko tete gbagbọ pe Mallam Ismail Issa Funtua, ọrẹ timọ, to si tun jẹ ọkan ninu awọn igi-lẹyin-ọgba-mẹta ti Aarẹ Muhammadu Buhari ni, ti dagbere faye. Alẹ ana yii lo ku, ọkan rẹ ni wọn sọ  pe o da iṣẹ silẹ lojiji.

Ọmọ ipinlẹ Katsina bii Buhari ni Funtua, ẹgbẹ si ni won, ọrẹ ni won, lati kekere ni wọn si ti n ba ara wọn bọ ki iku too mu un lọ. Ọga awọn oniroyin ni Alaaji Funtua, ooun lo n iiwe iroyin Democrat, o si ti figba kan jẹ alaga ẹgbẹ awọn onileeṣẹ iwe iroyin fun gbogbo Naijiria, bẹẹ lo ti ṣe minisita nigba kan, laye ijọba Shehu Shagari, ni 1983.

Nigba ti ijọba Buhari yii ṣẹṣẹ bẹrẹ, ti awọn eeyan n pariwo pe awọn kan ni wọn n dari Buhari, awọn ni wọn ko jẹ ko ṣejọba daadaa, ati pe awọn nikan lo n gbọrọ si lẹnu, titi ti iyawo rẹ, Aisha, naa fi sọrọ pẹlu ibinu, awọn mẹta pere naa lawọn eeyan n sọ. Eni akọkọ ni Maman Daura ti i ṣe ẹgbọn Buhari, ẹni keji ni Funtua to ku yii, ẹni kẹta wọn si ni Abba Kyari toun naa ti ku nijọsi.

Nigba ti ẹsẹ awọn mẹtẹẹta yii pe, ẹni ti wọn ba fẹ ko ri Buhari ni yoo ri i, ẹni ti wọn ba si fẹ ki Buhari fi ṣe minisita tabi ko yan sipo nla kan ni yoo fi sibẹ, bi wọn ko ba si fẹ ẹni kan, awọn naa ni yoo le e lọ. Ko si ohunn ti wọn nawọ si ti ọwọ wọn ko to, nitori ohunkohu ti wọn ba fẹ ni Buhari yoo ṣe. Funtua ki i kuro nile ijọba, ṣaṣa si ni irin-ajo ilẹ okeere ti Buhari yoo lọ ti ko ni mu Funtua dani. Bẹẹ ni won k oyan Funtua sipo, ọrẹ Buhari lasan ni.

Iku baba ọmọ odun mẹrindinlọgọrin naa dun Buhari, alukoro ile ijọba, Garba Shehu, si ti gbe iwe jade lati ṣalaye bi iku naa ṣe dun Aarẹ to. O ni Aarẹ so pe ọrẹ oun ni, alatilẹyin oun ni, lati kekere lawọn si ti jọ n ba kinni naa bọ titi di asiko yii. Ṣugbọn ọrọ iku ko ri bẹẹ, ki jẹ keeyan dagbere fẹnikeji ẹni. Mallam Issa Funtua naa ti lọ ree, o lọ sọrun aṣante.

Leave a Reply